Obasanjo: Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ogun ní iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún Ọbasanjọ láti ṣe fún mẹ̀kúnù Nàìjírìà

Obasanjo: Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ogun ní iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún Ọbasanjọ láti ṣe fún mẹ̀kúnù Nàìjírìà

Ọjọ karun oṣu kẹta ọdun 1937 ni a bi oloye Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ. Eyi to mu ki ọjọ karun oṣu kẹta ọdun 2020 jẹ ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹtalelaadọrin fun aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ naa.

Ikọ iroyin BBC News Yoruba wọ igboro Abẹokuta tii ṣe ilu Oloye Ọbasanjọ lọ lati mọ ohun ti awọn eeyan ibẹ nii sọ nipa agba oṣelu naa.

Abọ wa ni wi pe, bi awọn kan ṣe rii gẹgẹ bi eeyan to buru, awọn kan rii gẹgẹ bii ọmọ Naijiria rere ti ko yan ẹya, ede, tabi igun kan ni pọsin.

Apapọ ọrọ wọn ni pe irin ṣi pọ lẹsẹ alajọ Ẹbọra Owu lati ninu ilakaka rẹ fun igbe aye idẹrun fun mutumuwa lorilẹede Naijiria.

Abọ ree...