Nollywood: Ìdá 90% nínú àwọn olówó Naijiria lo n lọ ilé babaláwo

Mr Latin

Oríṣun àwòrán, Bolaji Amusan

Àkọlé àwòrán,

Ìdá 90% nínú àwọn olówó Naijiria lo n lọ ilé babaláwo- Mr Latin

Àgbà òṣèré to tún jẹ́ gbájúgba nínú eré tíátà àti alaga ẹgbẹ́ òṣèré ẹ̀ka ti Tanpan ní Nàìjíría, ọ̀gbẹ́ni Bolaji Amusan, ti gbogbo ènìyàn mọ sí "Mr Latin" sọ ìhà tirẹ̀ lórí ẹsùn ti mínísita Raji Fasola fi kan Nollywood

Mr Latin to jẹ́ alejo pataki lóri ètò àkànṣẹ́ ìfọ̀rọ̀wérọ ti ilé iṣẹ́ BBC lọ́sàn òni ọjọbọ to si fẹsì sí ọ̀rọ̀ kan ti o tẹnu mínísita orilẹ̀-èdè Naijira jáde wípe, àwọn òṣèré tíata ló kọ ara ilú bi wọ́n ṣe n ṣe òògùn owó kiri.

Ọgbẹ́ni Bolaji Amusan ní ọ̀rọ̀ náà ko ribẹ̀ rara, nítori gbogbo orilẹ̀-ède aye ní ènìyàn máa ń mọ iṣe àti àsà wọn láti ara awọn òṣèré wọ́n, Amusan sàlaye àwọn àmúyẹ to wà lára àwọn orilẹ̀-èdè àti àwọn eré ti wọ́n máa ń ṣe bi àpẹrẹ Amẹrika fiimu, India fíimu, to fi mọ fíìmù àwọn korea .

O ní ìdá àadọrùn nínú àwọn olówó orilẹ̀-èdè Naijiria lo máa nlọ si ilé Baba Alawo, nítori pe àrà àṣà abíni bi ni lórilẹ̀-èdè Naijiria àti pe tí ọ̀pọ̀ bá bẹ̀rẹ̀ si ni wo fíímu, wọ́n kii biki ta láti wòó pari ti wọ́n maa sọ pe àwọn ti mọ ibi ti yóò pari si èyi si maa n mú wọ̀n pàdánù láti mọ ẹkọ ti o wà níbẹ̀, ni ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn fíímu náà maa n naka àbùkù si àwọn to hu irú ìwà síse oògun owo ni.

Oríṣun àwòrán, Bolaji Amusan

Àkọlé àwòrán,

Ìdá 90% nínú àwọn olówó Naijiria lo n lọ ilé babaláwo- Mr Latin

O ní lẹ́yìn iṣẹ́ soja, iṣẹ́ ere ori ìtàgé tún ni o ni àṣà ìbáwi jùlọ, nítori náà gbogbo ǹkan ti àwọn ń ṣe, ìdánilẹkọ̀ọ́ lo wà fún.

Lóri ọ̀rọ̀ àwọn àgbà nínú òṣèrè ti wọ́n ku ti ọ̀pọ̀ wọ́n si n ṣe àìsàn, Mr Latin ní, ẹgbẹ́ ń ṣe ìwọ̀n to lè ṣe, sùgbọ́n ìhà ti ẹgbẹ́ yóò ko si irú ẹni bẹẹ ti wà lori irú ìhà ti ẹni náà kọ si ẹgbẹ́ nígbà ti ara rẹ̀ ji pépé.

to ba jẹ́ pe ẹni ti kìí peju dédé lásiko ipade ẹgbẹ́ ni, o ṣeeṣe ki ẹgbẹ́ náà ma kọ ibi ara sii

Ní ti Kayode Odumosu ti gbogbo ènìyàn mọ si "Pa Kasumu" Alaga Tanpan ni ẹgbẹ́ ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹfa lati ìgbà to ti bẹ̀rẹ̀ si n ṣe àisan, eyi si de ọ̀dọ̀ gómìnà àná ní ìpinlẹ̀ Ogun Ibikunle Amosun, owo to to mílíọnu meji ni gomina fún láti fi wo ara rẹ.

O ní nítori àwọn ìṣèlẹ̀ yìí ni ẹgbẹ́ ṣe fi orúkọ silẹ̀ ni àwọn ilé iṣẹ́ adójutofò kan láti le jẹ ki àwọn òsèré le maa fi tọ́rọ́kọ́bọ̀ wọ́n síbẹ̀ titi di ọjọ́ ogbó ti wọn kò ni le ṣe iṣẹ́ mọ.

Eyi o sàlàye pe yóò ma ràn wan lọ́wọ́ láti moju to ọjọ iwáju wọ́n, ti a ba si ri ẹni to ṣe àisan, o le gba nínú owó náà láti toju ara rẹ.