Nigeria housing: Ilé orí omi ni mo n gbé ní Eko

Aerial shot of homes

Lẹyin ti iwaadi ajọ isọkan agbaye kan jade eyi to bẹnu atẹ lu ipo to buru ti ipese ile igbe wa ni Naijiria, akọroyin wa ni BBC Mayeni Jones ṣe abẹwo si adugbo kan tawọn eeyan ti n gbe ninu ilé ìgbé ti kò bojúmu ni Eko akete.

Bi eeyan ba n wo Oko-Agbon to wa ni Makoko latI okeere, niṣe ni yoo dabi ẹni pe wọn ya aworan rẹ ni.

Ninu aworan ti a o ri yi, awọn to kọ ile sibẹ fi igi tẹlẹ ile onipakó si ori omi to dudu birikiti.

Bẹẹ leeyan o si ri awọn aradugbo ti wọn kesi ara wọn lati inu ọkọ oju omi.

Awọn ajoji to ri iru nkan bayi ni ilu Venice tawọn eeyan ti n fi ọkọ oju omi rin laarin ile, a ma ṣapejuwe Makoko gẹgẹ bi Venice tilu Afrika.

Amọ ṣaa, bi eeyan ba sunmọ daada, yoo ri pe ọrọ ko ribẹ tanyanyan.

Orisirisi pantiri lo kun ori omi yi, idọti to fi mọ ẹgbin. Oorun ẹja to ti baje ko ni jẹ ki eeyan rimu mi rara nibẹ.

Oorun naa kọja afẹnusọ.

Àkọlé àwòrán,

Dosu Francis ń gbe ni Oko Agbon pẹlu ọmọ àti ìyàwó rẹ̀

Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn eniyan lo n gbe papọ nibi ti ko si sí ààye la'ti ṣe ǹkan láàye ara ẹni.

Síbẹ, ibi jẹ ibi ààbò fun ọpọlọpọ̀. Dosu to jẹ́ pẹjapẹja kode Makoko ni nkan bi ọdun mẹta ṣẹyin lẹ́yin ti wọn le kúro ni ilé rẹ lẹba omi bakan náà ni àdúgbò Otodo Gbame.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aladugbo ibí tí ìjọba Èkó tí n wole sọ èrò ọkàn wọn

Oun, ìyàwó àti ọmọ ni wọ́n jọ n gbe inú yàrá kótópó, ti wọn n l'ò fún ẹja yíyàn.

Igba diẹ lo yẹ ki o fi gbe ile kolobo yi to jẹ ti ọkan lara awọn ọmọ iya rẹ sùgbọ́n ọdun kẹ́ẹ́ta rèé to ti n gbe ibẹ nigba ti ko riibo miran lati gbe.

Mo fi awọn ọmọ mi ranṣẹ si aburo mi

Pẹlu ohun irẹlẹ Francis sọ fun wa pe ''lati igba ti wọn ti lewa kuro,igbe aye ko dẹrun rara''

''Mo ni awọn ọmọ mẹta to to lọ ileewe ṣugbọn mi o le san owo ileewe wọn. A ti fun wọn lounjẹ jẹ iṣoro tori naa mo ti ni ki meji ninu wọn ma lọ si ọdọ akọbi mi obinrin to wa nile ọkọ ''

O ni ''ọkan ṣoṣo ninu awọn ọmọ mi ọkunrin lo n gbe lọdọ mi bayi''

Àkọlé àwòrán,

Ibi ti Dosu Francis n gbe tẹlẹ ni Otodo Gbame ti wọn wo ni nkan bi ọdun mẹta sẹyin

Ogbẹni Francis sọ pe típatikuuku ni wọn fi le àwọn jáde ni Otodo Gbame ni ọdun 2017, nigba ti àwọn ilú to súnmọ wọ́n fẹ́ gba ilẹ wọ́n, ni wọn rán àwọn ọlọpàá láti le àwọn dànù.

" Wọn bẹ̀rẹ̀ si ni le wa díẹ̀ díẹ.A léro pe àwa ati ọlọpàá yoo le dúna dura ni, súgbọ̀n ọjọ kan ni wọ́n kan wá le gbogbo wa dànù"

Mo beere lọwọ rẹ boya ijọba san owo gbaa ma binu fun.

''Ko si ẹni to fun wa ni nkankan,wọn ofun wa ni ile, wọn o fun wa ni owo.Wọn o fun wa ni nkankan, wn kan ni ka kẹru wa ki a ma lọ''

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awon Olugbe Tarkwa Bay lo si ile ẹjo ninu osu keji lati lo pe ijoba lẹjo idi ti wan fi le wan kuro ni ibugbe wọ́n

Kò si ǹkan to jẹ tuntun nínú ọ̀rọ̀ ti ọgbẹ́ni Francis sọ.

Idi ni pé ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn ni wọn maa n le kúro nilé ni orile-ède Naijiria láisi owo gba mabinu kankan fún wọ́n ti wọ́n ko si ni fi to wọ́n leti tẹ́lẹ̀ tabi fi wọ́n si ile míràn.

Gẹ́gẹ́ bi Amnesty International se sọ pe láàrin 2000 àti 2009 ijọba Naijiria ti le èèyàn miíọnu méji kuro ni ibugbe wọ́n.

Ní ìpínlẹ̀ Eko nikan àimọye àwọn ènìyàn ni wan ti fi tipa le kúro ni ibugbe wọ́n

Ninú osu keji ọdun 2013, o le ni ẹgbẹ̀run mẹsan eniyan ti wọ́n le ni Badia ni ilu Eko, lati mu ki ijọba kọ àwọn ile kan ,nínú osu kẹsan ọdun 2015, ẹniyan ẹgbẹ̀run mẹwàá ni wọ́n le kuro ni àdugbo náà.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdun yìí 2020, o to èèyàn ẹgbẹ̀run mẹwàá ti wọ́n fun ni wákàti kan pere láti ko ẹru wọ́n kúro ni Tarkwa Bay, nibi ti ọpọ àwọn ènìyàn ti ma n gbafẹ́ lopin oṣẹ nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bí àwọn eniyan ṣe kígbe to lori ayelujara, síbẹ ìjọba pada wó ilé wọ́n dànu.

Abẹwo BBC si Tarkwa Bay lati wa idi ti wọ́n fi le àwọn eniyan náà, awon ọmọ ologun ni ki àkoroyin wá kuro ni ẹsẹkẹsẹ,

Wọn ni ko si ǹkan ti àwọn n gbe pamọ súgbọ̀n ki wọ́n lọ gba ọ̀na to tọ láti pada wá