Elebuibon: Àwọn asòfin Ogun yóò ṣe àkóbá fún ilẹ̀ Yoruba pẹ̀lú òfín tó fágilé àsà

Awọn ọba nipinlẹ Eko pẹlu igbakeji gomina nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, @followlasg

Onimọ nipa eto ati asa ilẹ Yoruba, Baba Fayemi Elebuibon ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn asofin ipinlẹ Ogun, ti wọn pe fun ọna igbalode nipa yiyan ọba ati ṣise isinku ọba ni ilẹ Yoruba.

Elebuibon lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ ni, awọn asofin naa fẹ pa asa ati iṣe ilẹ Yoruba run ni.

O ni ko tilẹ yẹ ko jẹ bi wọn ṣe n yan ọba ni awọn asofin naa yoo jiroro le lori, nitori ki ilu lee tuba, ko tuṣẹ ni wọn se ma n ṣe etutu fun ọba, ni ilẹ Yoruba.

"Awọn asofin yii fẹ ba asa Ẹgba jẹ, ti yoo si se akoba fun gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba nitori ọba ti ko ba ṣe etutu, kii ṣe ọba. Ẹ ko le yan ọba ilẹ Yoruba bii ti ilẹ Gẹẹsi, bẹẹ naa ni wọn ko le yan ọba ilẹ Gẹẹsi bii ọba ilẹ Yoruba, nitori ọtọọtọ ni Ọlọrun da wa."

"Aṣiṣe ti ko dara gba a ni yoo jẹ ti ọba ko ba ṣe etutu ki o to jọba, abi ki wọn ma bọwọ fun asa ti wọn ba fẹ sin ọba"

Oríṣun àwòrán, @ObatAkinruntan

Onimọ nipa eto ati asa ilẹ Yoruba naa ni oro ati etutu ti wọn n ṣe fun awọn ọba lo ya ọba sọtọ, nitori ẹlomiran ni owo amọ wọn ko le e pe e ni ọba, nitori ko le e ṣe oun ti ọba n ṣe.

Elebuibon sọ wi pe o ti pe ti wọn ti yii pada ti ọba kii jẹ ọkan ọba mọ ati wi pe wn ti fi ọkan ẹran rọpọ rẹ.

Bakan naa ni o sọ wi pe eto isinku ọba ilẹ Yoruba ti yipada nitori wọn kii sin ẹnikẹni mọ ọba mọ, bẹẹ ni wọn kii yọ ẹya ara kankan lara ọba mọ to ba waja, nitori wọn ti fi ẹran rọpo awọn etutu ti wọn ma n ṣe.

O ni lara asa Yoruba ni ki awọn oni ifa ati awọn agba ṣe irubọ, ki wọn wo ikọṣẹ-jaye ọba ti o fẹ jẹ, kikọ ọba ni bi wọn ṣe n sọrọ lawujọ ati bi ihuwasi to mu ọba yatọ si awọn ẹlomiran, eyi to mu ki wọn ma a pe e ni alaṣẹ ekeji orisa.

Oríṣun àwòrán, Olubadan

Amọ, Elebuibọn faramọ ki wọn mase kọla fun awọn obinrin ni oju ara, amọ ila oju wa fun ẹwa obinrin ati ọkunrin ati lati mọ ibi ti eniyan ti ṣẹ wa.

Onimọ nipa eto ati asa ilẹ Yoruba, naa wa ni ila kikọ tun n pa owe fun awọn ọmọ ilẹ Yoruba pe ki eniyan to le jọrọ, yi o ṣiṣẹ takuntakun.

Àwọn àṣà tó ń jẹ́ kí Yorùbá hùwà bíi ẹranko àti ajẹ̀nìyàn, ẹ pa wọ́n run - Oluwo

Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Telu Kinni, ti kede pe o yẹ kawa ọmọ Yoruba se ipade apero lori ọna ta gba pa awọn asa ati ise awujọ wa kan rẹ, ti ko ba igba mu mọ.

Oríṣun àwòrán, emperortelu1

Ọba Akanbi fesi bẹẹ loju opo Instagram rẹ eyi to fi n sọ ero rẹ nipa bi Awujalẹ ilẹ Ijẹbu ati Ọṣilẹ Oke ọna se n beere pe ki wọn se atunse si awọn asa ati ise wa kan to ti di ogbo.

Awọn ọba meejeji naa lo mẹnuba baa pe ilana ibilẹ ti wọn n gba sinku ọba ni ko ba igba mu mọ, o si yẹ ki ayipada de baa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oluwo, lero tiẹ ni bi o tilẹ jẹ pe asa wa nilẹ Kaarọ oojire yaayi pupọ amọ awọn abala kan wa ninu rẹ to yẹ ka parẹ, nitori pe wọn ko ba saa taa wa yi mu mọ.

Oríṣun àwòrán, Samuel Ladoke Akintola

"Ẹ ko loye lori ohun to n lọ, nitori ẹ kii se ara rẹ. A n gba Oromọdiẹ lọwọ iku, o ni wọn ko jẹ ki oun re akita lọ jẹun ni. Awọn iyipada ta fẹ ninu asa wa ni awọn asa ati ise to n jẹ ka maa huwa bii ẹranko ati ajẹniyan, awọn abala asa wa ti ẹ ko mọ niyi."

Oluwo ni "Awa ti a ni ẹri ọkan yoo wa awọn asa yii jade nitori a ko lee pẹlu ọbọ jẹ oko, lara awọn asa kan gboogi ti ọjọ ti lọ lori wọn ni ila kikọ, asa Yoruba si gbọdọ maa ba igba mu."

Oríṣun àwòrán, emperortelu1

Oluwo tun tẹsiwaju pe asa Yoruba yaayi lootọ, ko si si ohunkohun taa fẹ gba ninu ka ba asa wa jẹ, amọ ta ba ba aye yi nidi awọn asa to ti di ogbo, a ti kuna niyẹn, iyipada maa n duro titi lae ni.

Oluwo wa pari ọrọ rẹ pẹlu ibeere pe "Ta lo fẹ wọ gọmbọ fun ọmọ rẹ lode oni? amọ eyi wa lọwọ ọmọ naa boya o wuu lati kọ ila to ba dagba."