Coronavirus: Ẹ wo àwọn ìròyìn èké tó gbòde ní Áfíríkà torí àjàkálẹ̀ àrùn

Awọn eeyan to n yẹ ara wọn wo ni papakọ ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoruba ni ọrọ okeere, bi ko ba le kan, yoo din kan, bẹẹ si lo ri fun arun Coronavirus, nitori oniruuru awọn ayederu iroyin lo n lọ kiri nipa arun naa, tawọn eeyan ko lee fidi rẹ mulẹ nilẹ adulawọ.

Bi o tilẹ jẹ pe Coronavirus ti na ọwọja rẹ de awọn orilẹede kan nilẹ Afrika, sibẹ awọn alasẹ lawọn orilẹede nilẹ adulawọ lo n tiraka lati pana ọpọ ayederu iroyin to rọ mọ Coronavirus.

Awọn ayederu iroyin nipa Coronavirus:

Eyi ni awọn ọpọ ayederu iroyin tawọn araalu n pin kiri nipa arun Coronavirus to n waye nilẹ Afirika.

Ge irugbọn rẹ ko ma baa ko arun Coronavirus:

Awọn eeyan Afrika lo ti n lo aworan kan lo, eyi ti awọn alasẹ eto ilera nilẹ Amẹrika fisita lori irun to maa n hu loju bii irungbọn, irun imu, irun ẹba eti ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn eeyan kan ti wa n gbe iborun kiri pe o yẹ kawọn ọkunrin maa ge irugbọn wọn lati dena arun Coronavirus, eyi ti ko ri bẹẹ rara.

Fun apẹẹrẹ, akọle kan loju ewe iwe iroyin Punch nilẹ Naijiria lo kede pe "To ba fẹ bọ lọwọ arun Coronavirus, ge irungbọn rẹ, CDC sekilọ" Irọ ni.

Bakan naa ni ọpọ akọle ti n wa lawọn iwe iroyin miran lawọn orilẹede miran eyi tawọn eeyan bẹrẹ si pin kiri. Fun apẹẹrẹ, Iwe iroyin kan nilẹ Australia kọ soju opo Twitter rẹ pe "Bi irungbọn rẹ se lee jẹ ko wa ninu ewu Coronavirus laimọ."

Oniwaasu kan nilẹ Naijiria n wo arun Coronavirus san:

Oniwaasu kan to ni oun lee wo arun Coronavirus san naa tun ara awọn iroyin ti ko fidi mulẹ.

Iroyin nipa Davies Kingleo Elijah, ti ijọ Glorious Mount of Possibility lo bẹrẹ si tan kalẹ lori afẹfẹ lẹyin fidio kan to ni oun yoo lọ tẹdo si Ghana lati pa arun Coronavirus run, eyi to gba oju opo YouTube atawọn oju opo ikansira ẹni miran kan.

"Maa fi asọtẹlẹ ba arun Coronavirus jẹ. Mo n lọ si China, mo fẹ lọ pa Coronavirus run."

Lẹyin ọjọ diẹ ni iroyin naa wa lawọn opo ayelujara kan pe ojisẹ Ọlọrun naa ti gba china lọ amọ o wa nile iwosan nibẹ to n gba itọju lẹyin tọwọ arun arun Coronavirus gba mu.

Amọ orukọ miran, Elija Emeka Chibuke ni wọn fi kọ iroyin naa nipa oniwaasu ọhun.

Koda, aworan ti wsn lo jẹ aworan osere tiata kan ti ara rẹ ko ya, amọ to ti jalaisi bayii, Adeshina Adesanya, ti ọpọ eeyan mọ si Pasitọ Ajidara.

Iroyin eke nipa awakọ taxi kan:

Iroyin kan nipa awakọ tasi kan ni Naijiria ti wọn lo ko arun Coronavirus lo wa loju opo ayelujara amọ ẹbu ni iroyin naa.

Iroyin naa ni awakọ ọhun ni wọn lo gbe ọkunrin alawọ funfun kan to ni arun Coronavirus, ti wọn si ti yaa sọtọ tori pe o ni arun ọhun.

Wọn ni awakọ naa papa sa kuro nile iwosan ti wọn yaa sọtọ si, to si n dunkoko lati tan arun naa kalẹ ayafi ti awọn mọlẹbi ọkunrin naa ba san milinu lọna ọgọrun naira.

Amọ awọn alasẹ ti sẹ pe irọ ni ọrọ naa, tijọba Ogun si fi ọrọ lede lori Twitter rẹ pe irọ̀ọ ni ọrọ naa.

Ipaya wa lori fọnran ohun kan nilẹ Kenya:

Lorilẹede Kenya, ijọba fi ikede sita pe pe irọ ni fọnran ohun ti wọn n pin kiri pe arun Coronavirus ti wọ orilẹede naa, eyi to ni awọn eeyan to ni arun naa to mẹtalelọgọta niye.

Ileesẹ eto ilera ni fọnran naa jẹ ohun ti wsn jiroro nibi idanilẹks kan amọ ti ko ye wọn bi fọnran naa se lu sita.

Labẹ ofin ilẹ Kenya, ẹnikẹni to ba pin iroyin eke yoo san ẹgbẹrun lọna aadọta dọla abi ko fi ẹwọn ọdun meji jura.

Iwosan:

Nilẹ Naijiria, oniwaasu kan fi fidio ati iwe ikede kan sita, eyi ti wọn n pin loju opo Whatsapp pe, omi ọbẹ alata, taa mọ si Pepper Soup, lee wo arun Coronaviruas san.

Ko tii si iwosan tabi itọju fun arun naa, bẹẹ si ni ẹbu iroyin naa lo n salaye nipa bi omi ọbẹ alata naa se lee se iwosan Coronavirus.

Bakan naa, ileesẹ eto ilera ni Cape Verde ti kilọ fawọn araalu lati mase se alabapin iroyin to n fọnrere pe ewe kan ti wọn fi n se ọbẹ lee wo Coronavirus san.

Ohun kansoso ti ajọ eleto ilera lagbaye kede pe o lee wo Coronavirus san ni ka maa fọ ọwọ wa deede, nitori eyi se pataki lati dena kokoro arun naa.