Odion Ighalo: Ole Gunnar Solskjaer gbóṣùbà káre fún Ighalo lẹ́yìn tó sọ góòlò méjì sáwọ̀n Derby County

Odion Ighalo

Oríṣun àwòrán, @AfricaFactsZone

Àkọlé àwòrán,

Ohun ti ẹnikẹni ba sọ ko kan oun, bi ko ṣe ki oun gbaju mọ iṣẹ

Atamatase ikọ Manchester United, Odion Ighalo ti ni, ọrọ ti awọn kan n sọ kiri lori igbeṣẹ oun lati darapọ mọ Manchester United ko tu irun kankan lara oun.

Ighalo sọ pe ohun to ṣe pataki ni ki awọn ojugba oun gbagbọ ninu oun, gẹgẹ bi agbabọọlu to pegede.

O ni "Niwọn igba ti awọn akẹgbẹ mi, akọnimọọgba mi ati awọn ololufẹ mi ba lee gbagbọ ninu ipa ti mo le ko lori papa, temi ni lati maa ṣe ohun ti mo mọọ ṣe."

Ighalo tẹsiwaju pe "Ohun ti ẹnikẹni ba sọ ko kan mi, afojusun wa ni Man United ni lati tẹsiwaju ninu saa bọọlu yii."

Ami ayo mẹta si odo ni Manchester United fi ṣeya fun Derby County ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn to waye lọjọ Ọjọbọ, leyii ti Ighalo ti sọ bọọlu meji wọle ninu rẹ.

Ọpọ awọn ololufẹ Manchester United kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n jẹ ọrọ Ighalo lẹnu bi ẹni jẹ iṣu lẹyin aṣeyọri Manchester United ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, papa julọ fun ipa to ko.

Oríṣun àwòrán, @AfricaFactsZone

Ighalo ni aṣẹyọri oun ni Manchester United ti fi han pe, oun kun oju oṣuwọn lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ni bayii, Ighalo ti sọ goolu mẹta sinu awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ meji to ti kopa ninu rẹ lati igba to ti darapọ mọ ikọ ọhun ni Oṣu Kini, ọdun 2020.

Ẹwẹ, akọnimọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer ti gboṣuba kare fun Odion Ighalo fun iṣe akin to ṣe lati sọ bọọlu sinu awọn Derby County nigba meji ọtọtọ ninu ifẹsẹwọnsẹ FA Cup ọhun.

Àkọlé fídíò,

Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo