Michael Oluronbi: Pásítọ̀ r'ẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n he lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀

Tọkọ taya Oluronbi

Oríṣun àwòrán, WEST MIDLANDS POLICE

Pasitọ kan, Michael Oluronbi ti rẹwọn ọdun mẹrinlelọgbọn he lẹyin to jẹbi ẹsun ifipa ba awọn ọmọde lo pọ nilẹ Gẹẹsi.

Ẹni ọgọta ọgun ọhun ni wọn fẹsun kan pe o ba awọn ọmọdebinrin mẹfa ati ọmọdekunri kan lo pọ fun ọpọ ọdun labẹ asia pe o un ṣe iwẹ mimọ fun wọn lati lee bawọn le ẹmi ẹsu jinna.

Iyawo rẹ, Juliana Oluronbi naa rẹwọn ọdun mọkanla he lẹyin to jẹbi ṣiṣẹ oyun fun mérin lara awọn ọmọdebinrin mẹrin naa.

Pasitọ ọhun, to jẹ ọmọ Naijiria ṣugbọn to n fi Birmingham ṣebugbẹ nilẹ Gẹẹsi ni wọn sọ pe, o ma n sọ fun awọn to ba ko si lọwọ wa ni ihoho niwaju rẹ, fun iwe mimọ.

Agbẹjọro ijọba sọ fun ile ẹjọ ni Birmingham pe o ma n ṣe eyii lati tan awọn awọn ọmọde naa, lọna ati le ba wọn ni ibalopọ.

Ọwọ palaba pasitọ naa segi loṣu karun un ọdun 2019 nigba to n gbiyanju ati sa kuro nilẹ Gẹẹsi lọ Naijiria, awijare rẹ ni pe iṣe eṣu lo mu oun ṣe aṣemaṣe.

Adajọ to n gbọ ẹsun naa, Sarah Buckingham ni iwa pasitọ yii wa lara awọn iwa ọdaran to buru ju ti wọn tii gbe wa siwaju oun.

Nigba ti wọn sọ iriri wọn fun ile ẹjọ, awọn obinrin ti ọrọ ọhun ṣẹ si so pe, iwa pasitọ naa jẹ eyii ti wọn ko lee gbagbe ni kiakia, koda, ọkan lara ni oun ti dẹkun ati ma lọ ile ijọsin.

O ni "Mi o lero mo le fi igabgbọ mi sinu ẹsin kankan mọ. Mo fọkan tan pasitọ yii nitori mo n wo bi Ọlọrunn lorilẹ alaye, ṣugbọn o jami kulẹ."

Pasitọ Oluronbi to jẹ ọmọ ijọ Kerubi ati Serafu jẹbi ẹsun ifipabanilopọ marundinlogun ti wọn fi kan an atawọn ẹsun mii, lẹyin naa ni adajọ ni ko lọ fi aṣo pempe roko ọba.

Àkọlé fídíò,

Obasanjo: Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ogun ní iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún Ọbasanjọ láti ṣe fún mẹ̀kúnù Nàìjírìà