Coronavirus: Togo di orílẹ̀èdè kẹsàn án tí àrùn Coronavirus dé ní Afíríkà

awọn oṣiṣẹ alaisan ni ileewosan kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi aarun Coronavirus ṣe n ran kaakiri bii ina inu ẹrun lagbaye bayii, Orilẹede Togo naa ti darapọ mọ awọn orilẹede ti arun naa ti tan de lagbaye.

Ijọba orilẹede naa ti kede pe awọn ti ri eeyan kan to ni arun naa bayii nibẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti ijọba orilẹede naa sọ, arabin ọmọ ọdun mejilelogoji kan to jẹ olugbe ilu Lome tti ṣe olu ilu orilẹede naa lo ko arun naa.

Wọn ni Orilẹede Benin, Germany, France ati Turkey lawọn orilẹede ti arabin naa bẹ wo loṣu keji ati ikẹta ọdun yii.

Ijsba orilẹede Togo ṣalaye pe awọn ti fi arabinrin naa si abẹ ayẹwo fun itọju to peye; atipe ara rẹ n balẹ.

Orilẹede Togo ni orilẹede kẹsan ti arun Coronavirus yoo ti suyọ lẹyin Algeria to jẹ orilẹede akọkọ l'Afirika ti yoo kede arun ọhun lọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ọdun 2020; Egypt, Morocco, Nigeria, Senegal, South africa, Tunisia ati Cameroun.

O ti le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan bayii to ti ko aarun yii lagbaye, gẹgẹ bii fasiti John Hopkins University ṣe fidi rẹ mulẹ ninu iwadii kan.

Ninu awọn wọnyi, o le ni ẹgbẹrun mẹta ti arun yii ti ran lọ sọrun lorilẹede China nikan.

Awọn orilẹede miran ti arun yii ti n ṣọṣẹ ni Japan, South Korea, France, Ilẹ Gẹẹsi, ati Amẹrika wa lara awọn orilẹede ti arun naa ti n ṣọṣẹ.