Coronavirus: Àjọ bọ́ọ̀lù ní France sún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ PSG àti Strasbourg síwájú nítorí Coronavirus

Awọn ololufẹ ẹgbẹ agbagblọọlu PSG

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibanujẹ ba awọn ololufẹ ere bọọlu ni liigi orilẹede France, atawọn ololufẹ Ligue 1 pẹlu bi awọn alaṣẹ

Ere bọọlu lorilẹede naa ṣe sun ifẹsẹwọnsẹ laarin ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Paris Saint Germain, PSG ati Strasbourg siwaju nitori ọwọja arun Coronavirus nibẹ.

Eyi ni ifẹsẹwọnsẹ bọọlu akọkọ laarin awọn ikọ odu ẹgbẹ agbabọọlu lorilẹede naa ti wọn yoo maa wọgile nitori arun naa.

Orilẹede France wa laarin awọn orilẹede to n moke lagbo awọn orilẹede ti arun Coronavirus ti n ṣọṣẹ julọ pẹlu bi o ti ṣe jẹ pe ẹgbẹta o le mẹtala eeyan lo ti ko sọwọ arun naa ti eeyan mẹsan ti jade laye nitori rẹ.

Titi di bi a ṣe n kọ iroyin yii wọn ko tii sọ igba ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo wa pada waye.

Orilẹede France kọ ni akọkọ orilẹede tawọn alaṣẹ ere bọọlu yoo ti wọgile ifẹsẹwọnsẹ bọọlu nitori arun Coronavirus.

Orilẹede Italy wọgile ifẹsẹwọnsẹ marun lopin ọsẹ to kọja nitori arun naa ninu eyi ti ifẹsẹwọnsẹ Juventus ati Intermilan wa.