International Women's day 2020: Àwọn obìnrin tọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn

International Women's day 2020: Àwọn obìnrin tọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn

Ọjọ kẹjọ ọdọọdun ni ayajọ awọn obinrin lagbaye nibi ti gbogbo agbaye ti n kọju si awọn obirin lati yombo awọn iṣẹ takuntakun ti wọn gbe ṣe lai nọọni oniruuru ipenija, ẹdun ọkan ati ilakaka wọn fun aṣeyọri gbogbo laarin kaakiri agbaye.

Ẹtọ awọn obinrin pẹlu idọgba pẹlawọn ọkunrin lo gbode gẹgẹ bii ohun ojutaye lasiko ajọyọ ayajọ obinrin lagbaye ti ọdun yii.

Akọmọna ayajọ naa fun ọdun yii ni "ajafẹtọ ibaradọgba ni mi: mimu ẹtọ awọn obinrin ṣẹ."

Ninu ọrọ tiwọn, ajọ iṣọkan agbaye rọ awọn eeyan gbogbo lati ji giri gbogun ti awọn ipenija aidọgba laarin ẹya ẹda gbogbo.

Ninu fidio BBC News Yoruba fun ayajọ yii, awọn obinrin ni oriṣiriṣi ilana iṣẹ aje gbogbo sọrọ lori ipenija ti wọn n dojukọ; paap julọ laarin awọn ọkunrin lẹnu iṣẹ aje gbogbo.