coronavirus: Ìdí tí obìnrin fi leè rù ú là ju ọkùnrin lọ

Obinrin kan n se ayewo ilera

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O n dabi ẹni pe o ṣeeṣe fun ọkunrin lati ku lọwọ arun Coronavirus to n ja nilẹ bayii ju awọn ọkunrin lọ.

Bakan naa si ni ko ṣeeṣe fawọn ọmọde lati ku nipasẹ arun naa to bi awọn agba lọ.

Ọpọlọpọ awọn eeyan lo jẹ wi pe arun yii yoo kan ṣi ni fila lọ ni, ṣugbọn awọn miran a maa tipasẹ arun yii dero ọrun.

Ti o ba ri bẹẹ, ki wa gan an lo n fa iyatọ laarin bi ọṣẹ arun yii ṣe le si laarin ẹya akọ atabo tabi ara awọn ọmọ wẹwẹ ati agbalagba?

Gbogbo awọn iroyin ti a ri kojọ lori eyi wa latawọn iwadii gbankọ gbi tawọn ibudo amojuto ajakalẹ arun lorilẹede China ṣe, Chinese Centers of Disease Control.

ẹgbẹrun mẹrinlelogoji (44,000) ni iwadii naa gbe yẹwo ninu eyi to ti fihan pe ida mẹta din diẹ ninu ọgọrun (2.8%) awọn ọkunrin to ko arun Coronavirus yii lo jade laye; bẹẹni ida meji o din diẹ ninu ọgọrun (1.7%) awọn obirin to ko arun naa lo jade laye.

Bẹẹni ko tilẹ sun mọ ida kan ninu ọgọrun (0.2%) awọn ọmọde ati ọṣọrọ ọdọ to ko arun yii to jade laye; nigba ti ida marundinlogun (15%) awọn agbalagba ti ọjọ ori wọn ti ju ọgọrin ọdun lọ laisan Coronavirus ti ran lọ sọrun.

Ṣe arun yii kii mu obirn ati ọmọde ni pupọ ni?

Ọna meji ni a le gba ṣalaye abajade iwadii naa lori eyii.

Yala ko jẹ wi pe awọn obirin atọmọde ko lee saba ko arun yii tabi ko jẹ wi pe awọn ẹya ara wọn lagbara lati koju kokoro arun coronavirus ọhun.

'Koko pataki kan ni wi pe, kokoro arun tuntun yii n tan kalẹ, gbogbo eeyan lo si lee ko o." Eyi jẹ ọrọ Dokita Bharat Pankhania lati fasiti Exeter sọ.

Idi eyi ni pe ko si ajẹsara kankan ninu agọ ara to lee dena arun yii nitori ko si ẹnu to lugbadi rẹ ṣaaju asiko yii ri.

Lootọ o, lasiko ti arun naa ṣẹṣẹ bẹẹ, o ṣoro diẹ fun awọn ọmọde lati ko kokoro arun naa.

Ki lo n doola ẹmi awọn obinrin lọwọ arun Coronavirus?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoo ya ọ lẹnu pe iyatọ gedegbe wa laarin iye awọn ọkunrin ati obinrin to n ku nipasẹ arun yii?

Ṣugbọn eyi ko ya awọn onimọ sayẹnsi lẹnu o.

Bi a ko ba ni jayopa, bakan naa lọrọ ṣe rilawọn aisan miran bii otutu.

Lara idahun si eyi naa ni pe, igbe aye awọn ọkunrin buru jai ju tawọn obirin lọ lawọn nnkan ti wọn n ṣe bii siga mimu.

"Siga n ba ẹdọ jẹ. Iru ẹni bẹẹ ko lee yee rara." Gẹgẹ bi Dokita Nathalie MacDermott lati ile ẹkọ giga Kings College ni ilu London ṣe sọ.

Eyi ṣeeṣe ko fa wahala nla lorilẹede China nibi ti iwadii ti fihan pe nnkan bi ida mejilelaadọta ninu ọgọrun awọn ọkunrin wọn lo n ṣana si siga ti o si jẹ pe iwọn perete ida mẹta nini ọgọrun awọn obinrin lo n mu siga nibẹ.

Bakan naa ni iwadii fihan pe iyatọ wa laarin eroja ajẹsara abawaye awọn obinrin ati ti ọkunrin ati ọna ti awọn eroja ajẹsara yii maa fi n gbera sọ nigbakugba ti aisan tabi arun kan ba fẹ dide.

Ṣe ọmọ inu alaboyun lee ko arun coronavirus yii?

Idahun awọn ọjọgbọn ni pe 'rara'ṣugbọn awọn akọṣẹmọṣẹ kan ti n sọ ọ wi pe o ṣeeṣe o ki ọrọ maa ri bẹẹ

Oriṣiriṣi nnkan ni oyun nini maa n ṣe fun ara, lara rẹ si ni dindin agbara awọn eroja ajẹsara ara ku. Eyi si maa n mu ki wọn wa larọwọto ọpọlọpọ kokoro arun lasiko oyun yii.

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ni 'ko si ami kan gboogi' to fihan pe awọn obirin to ba loyun lee fara kaasa arun coronavirus ju awọn ti ko loyun lọ.

Bawo ni Coronavirus ṣe kan awọn ọmọde?

Àkọlé fídíò,

Omidan jáde láyé lẹ́yìn tí ìlú lù ú, jáa sí ìhòhò lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀

Awọn ọmọde lee ko arun Coronavirus. Iroyin tilẹ ti fi idi rẹ mulẹ pe ninu awọn to ti ni arun Ccoronavirus lagbaye bayii, ọmọ kekere jojolo ti wọn ṣẹṣẹ bi wa lara wọn.

Iyatọ nla wa laarin ilana eroja ajẹsara amuwaye (immune system) ọmọde ati ti agbalagba.

Awọn eroja yii lara awọn ọmọde maa n ṣiṣẹ ni kiakia ni; wọn a si maa jẹ iṣẹ kọja ibi ti wọn ba ran wọn de nigba miran. Eleyii lo maa n faa tawọn ọmọde maa fi n saba n ni aisan iba.

Bi awọn eroja yii ba n jẹ iṣẹ kọja ala, wọn le ṣe akoba fun awọn eroja ara yoku, ara idi si niyi ti awọn arun coronavirus lee mu iku dani.

Amọṣa gẹgẹ bi Dokita MacDermott ṣe sọ, eyi kii waye pẹlu arun Coronavirus lara awọn ọmọde o, ko si si ẹni to mọ ohun ti arun naa n ṣe lara awọn ọmọde ti eyi fi ri bẹẹ.