Collapsed building: Ilé tó jẹ́ ti báǹkì wó pa arákùnrin alágbàṣe ọmọ ọdún márùndínlógójì nílùú Èkó

Ile ifowopamọ to dawo

Oríṣun àwòrán, Google Maps

Eeyan kan ti kagbako iku lasiko ti ile kan ti wọn n ṣatunṣe rẹ dawo ladugbo Palmgroove nilu Eko lọjọ Abameta.

Awọn alaṣẹ nilu Eko ajọ iṣẹlẹ pajawiri LASEMA ni arakunrin kan to ba ba iṣẹlẹ naa lọ jẹ ẹni ọdun marundinlogoji.

Alagbaṣe ni arakunrin naa.

Gẹgẹ bi ohun ti ọga LASEMA, Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu ti ṣe sọ,Ezekiel Ajibola lorukọ rẹ ati pe ifọwọsowọpọ pẹlu awọn oṣiṣẹ panapana ti mu ki awọn ri oku rẹ yọ tawọn si ti gbe le ọlọpaa lọwọ.

O fikun ọrọ rẹ pe ile to dawo naa jẹ ti ile ifowopamọ Keystone Bank .

Laipẹ yi lọjọ kẹfa oṣu yi ni awọn alẹnulọrọ lara awọn ileeṣẹ ijọba to n f'awọn eeyan ni iwe aṣẹ ki wọn to kọ ile ṣe ipade lori bawọn eeyan ti ṣe n kọ ile lọna ti ko tọ.

Ajọ to n dena didawo ile ni Naijiria ni o kere tan ile to to ẹgbẹrun mẹrindinlọgọta lo wa ninu ewu didawo.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aladugbo ibí tí ìjọba Èkó tí n wole sọ èrò ọkàn wọn

Àkọlé fídíò,

Lagosollapsedbuilding: Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Eko ní ìjọba, aráàlú lọ́wọ́ nínú bí ilé ṣe ń wó

Aarẹ ajọ naa Akinola George sọ fun BBC pe idi ti iru nkan bayi fi n ṣẹlẹ ni pe awọn ti ko mọ nipa ile kikọ ni wọn ma n kọ awọn ile ni Eko.

Lọdun 2029 bakanna ajọ LASEMA naa sọ kin ọrọ yi lẹyin pe lilo ayederu eronja ikọle ati gbigbe iṣẹ fawọn alagbaṣe ti ko dantọ lo mu ki ile kan wo ladugbo Ikoyi ni Eko.