NCDC: Kò dájú pé láti ilé ni ọmọ Nàìjíríà tó ní Coronavirus ní Washington ti ko

Aworan Minisista feto ilera Naijiria,Osagie Ehanire

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n dẹkun ajakalẹ arun lorileede Naijiria,NCDC, ti fidi ọrọ mulẹ pe ọmọ Naijiria ni eeyan ẹlẹkeeji to ni aisan Coronavirus ni ilu Washington lorileede Amẹrika.

Loju opo ajọ naa ni Twitter ni wọn ti fidi ọrọ yi mulẹ amọ ṣa wọn ni ko daju pe lati Naijiria ni yoo ti ko lọ si Amẹrika.

Ajọ naa tẹsiwaju pe awọn ati akẹgbẹ wọn lorileede Amẹrika jijọ n fọrọ jomitooro ọrọ nipa iṣẹlẹ yi

Gẹgẹ bi ohun ta ri ka, ọfisi alaga Washington sọ pe ile iwosan kan ni Maryland lo ti n gba itọju.

Wọn ko ti darukọ arakunrin naa ṣugbọn wọn ni awọn alaṣẹ ilera n gbiyanju lati tọ awọn ibi to ti rin de ati awọn to ti ṣalabapade.

Ẹwẹ, NCDC ti sọ pe eeyan mẹtalelogun lawọn fura si pe wọn ni aisan coronavirus ni awọn ipinlẹ marun ni Naijiria.

Ninu awọn wọn yi ti wọn wa lati ipinlẹ Edo Eko,Ogun,Abuja ati Kano, eeyan kan pere layẹwo ti fihan pe o ni aisan naa ti eeyan kankan ko si ku latara aisan ọhun.