Chineme Martins: NFF ní àyẹ̀wò gbogbo irinṣẹ́ ètò ìlera ti di dandan báyìí ṣáájú eré bọ́ọ̀lù kankan

Ambulansi

Ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiriia, NFF ti sọ pe dandan ni ṣiṣayẹwo gbogbo irinṣẹ eto ilera awọn ẹgbẹ agbabọọlu bayi ki ifẹsẹwọnsẹ kankan to le bẹrẹ.

Eyi waye lẹyin iku agbabọọlu Nasarawa United, Chineme Martins to di oloogbe nigba ti ifẹsẹwọnsẹ NPFL n lọ lọwọ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Katsina United lọjọ Aiku.

Ikọ agbabọọlu Nasarawa ko tii sọrọ lori iku ojiji adilemu wọn to ti ṣoju ikọ agbabọọlu naa nigba mẹrin ọtọtọ ni saa bọọlu yii.

Minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ, Sunday Dare fi aidunnnu rẹ han loju opo Twitter rẹ nibi to ti sọ pe o ṣeeṣe ki Martins maa ku tawọn irinṣẹ eto ilera gidi ba wa ni papa iṣere ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Minisita ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi agbabọọlu Martins to di oloogbe.

Igba keji ree ti agbabọọlu yoo gbẹmi mi ni papa isẹre Nasarawa United niluu Lafia.

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

NFF, LMC Kwara United bá Nasarawa United kẹdun ikú Martins

Agbabọọlu Kano Pillars, Dominic Dukudod subu ni papa isere kan naa ninu osu kejila odun 2018.

Àwọn ọmọ Naijiria to ti kú lóri pápá lásìkò ìfẹsẹwọ́nsẹ

Kòsi àniàni, eré ìdáraya bọọlù jẹ́ èyi tó gbàjúmọ jùlọ ni orílẹ-èdè Naijiria àti ní gbogbo àgbàyé, ọ̀pọ́ àwọn ènìyàn lo si máa n lọ wòràn.

Sùgbọ́n o, bi àwọn ènìyàn ṣe n lọ wo bọọlu yìí ọjọ miran wà ti wọ́n maa n ri ohun ti kò dùn mọni nínú.

Ìrú ìṣẹ̀lẹ̀ abaní nínú jẹ yìí lo wáye lána nígbà ti ọmọ agbábọọlu pẹlu Nasarawa United dédé súbú lulẹ to si gba ibẹ lọ si ọrun alákeji.

Èyí ju ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria , àjọ NFF, LMC, ẹbi, ọ̀rẹ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ àgbá bọọlu jákejádo Naijira sínú ọ̀fọ̀.

Ẹ̀wẹ̀, èyí kìí ṣe ìgbà àkọkọ láàrin àwọn agbábọọlu Nàìjíríà ti agbá bọọlu yóò dédé kú lóri pápá.

Àwọn agbábọ́ọ̀lù Naijiria to ti kú sórí pápá

Samuel Okwaraji: Samuel Okwaraji kú lórí pápá lásìkò to n gbá bọọlu láti fun pegede ife àgbáye pẹlu Angola.

Okwaraji kú ni ọjọ́ kejila, oṣù kẹjọ ọ́dun 1989.

Ọ̀pọ̀ lo si n dáro Okwaraji titi di àsìkò yìí nítori o jẹ olókìkí to si mọ ere orí pápá náà gbá dáadaa.

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọmọ Naijiria to ti kú lóri pápá lásìkò ìfẹsẹwọ́nsẹ

Michael Umanika: Agbábọọlu Naijiria fún Zagatala PFK lo dójubolẹ lori pápá lásìkò ti wọ́n ṣe ìgbáradi láti lọ fun idíje.

Wọ́n fún ra pe àìsàn ọkan lo pàá, òun náà kú ni ọjọ kẹẹdogun ọdun 2016

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọmọ Naijiria to ti kú lóri pápá lásìkò ìfẹsẹwọ́nsẹ

Amir Angwe: Agbábọọlu Julus Berger náà kú lóri pápa lọ́dun 1995.

Iròyìn ni pé, àisan ọkàn náà lo pa òun náà.

Orí pápá ló ti subu ti oun náà si gba ibẹ̀ lọ, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọ̀n ni lásìkò náà.

Orobosan Adun: Kí wọ́n to lọ fún ìfẹsẹwọ́nsẹ pẹlú Enugu Ranger, àwọn ọmọta kan ti wọ́n fúra si pe o jẹ oloufẹ àwọn ẹgbẹ́ agbábọọlu ti wọ́n fẹ́ lọ bá gbá ti kọkọ ṣe ìkọlu si asọle ẹgbẹ́ agbábọọlu Warri Wolves (Adun).

Asikò ìgbáradi lóri pápá ni Adun kú lẹ́yin ọjọ mẹta ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

O kú ni ẹni ọdun méjidinlọgbọ̀n, lọdun 2009.

Azeez Saka: Lọ́dun 2017, okiki irú èyi náà tún kan nígbà ti ọmọ akọnimọọgba bọọlu ori tabili Kasali Lasisi ku.

Saka jẹ ọmọ ẹgbẹ́ agbábọọlu Kwara United, o kú ni ori papa lásìkò ìgbáradi pẹlu àwọn akẹgbẹ́ rẹ ní ilú ìlọrin tii ṣe oluulu ipinlẹ Kwara.

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọmọ Naijiria to ti kú lóri pápá lásìkò ìfẹsẹwọ́nsẹ

Emmanuel Ogoli: Ọmọ ẹgbẹ́ agbábọọlu Ocean Boys kan náà kú lori pápá, lásiko idije league, o si pada jẹ di oloogbe ni ilé iwosan.

O ku ni ọjọ kejila osu kejila ọdub 2010

NFF, LMC Kwara United bá Nasarawa United kẹ́dùn ikú Martins

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

NFF, LMC Kwara United bá Nasarawa United kẹdun ikú Martins

Àjọ NFF àti LMC ṣì n sọ̀fá ìkú adilé mú ọmọ ẹgbẹ́ agbabọolu Nasarawa United Chineme Martins.

Alaga àjọ LMC, Shehu Dikko, nínú àtẹjáde kan to fi ba Nasarawa United àti ẹbi olóògbé náà kẹ́dun.

Ọgá àgbà èré bọọlu òun ni àwọn yóò ṣe àyẹwò okú náà láti mọ irú ikú to pa Martins ni pàtó.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

NFF, LMC Kwara United bá Nasarawa United kẹdun ikú Martins

"A ní ìgbàgbọ́ pé tí a ba mọ irú ikú to pa a, ni yóòjẹ ki a lé mọ irú igbésẹ̀ ti a o gbé láti dẹkun irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀."

Ẹ̀wẹ̀, àjọ LMC ń wá ọ̀nà láti ni ìbáṣepọ ẹgbẹ́ agbábọọlù olóògbé àti àwọn ẹbi rẹ̀, láti le mọ ọ̀nà ti wọ́n yóò gbà ṣe ìrànwọ́ níru àsìkò aburu yìí

Bákan náà ni àjọ NFF fi ẹdun ọkan rẹ̀ han fún ọmọ agbabọọlu ọ̀un lóri àtẹjiṣẹ́ twitter rẹ.

Bakan náà ni àwọn ẹgbẹ́ agbábọọlu Kwara United náà ti kẹdun pẹlú Nasarawa United lori ikú Martins.