Ìròyìn Yàjóyàjó - Nàìjíríà kéde èèyàn míràn pẹ̀lúu àrùn Coronavirus

Awọn oṣiṣẹ ilera

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede eeyan keji to to ko aarun Corona virus lorilẹ̀ede Naijiria.

Minisita feto ilera lo kede eyi

Gẹgẹ bi atẹjade kan lori oju opo twitter ajọ to n gbogunti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ṣe sọ, onitọhun wa lara awọn to ni nnkan pọ pẹlu ọmọ orilẹede Italy ti wọn kọkọ kede pẹlu aarun naa ni ọsẹ meji sẹyin.

Ẹni ti wọn ṣẹṣẹ kede naa wa lara awọn ti wọn fi sabẹ ahamọ ayẹwo ni ipinlẹ Ogun.

Ajọ naa ni gbogbo awọn eeyan to ni ajọṣepọ kan abi omiran pẹlu arakunrin ọmọ orilẹede Italy naa ni ipinlẹ Eko ati Ogun ni yoo ṣi wa labẹ ahamọ ayẹwo ajọ naa ati ileeṣẹ eto ilera pajawiri lawọn ipinlẹ mejeeji.

Bakan naa ni minisita feto ilera tun kede rẹ pe awọn onimọ ijinlẹ nipa kokoro aifojuri latawọn ileewosan nla LUTH, ibudo iwadi ajakalẹ arun ni fasiti Redeemers ni Ede ati ibudo iwadi nipa iṣegun oyinbo, NIMR to wa nilu Eko ni wọn pawọ pọ lati ṣawari ilana kan fun itọpinpin arun Coronavirus eyi ti oyinbo n pe ni 'genome sequencing'

O ni nipasẹiwadii tuntun yii, wọn ti fi idi rẹ mulẹ pe irufẹ kokoro arun Coronavirus to n ja kalẹ ni orilẹede Italy ati ilu Wuhan lorilẹede China.

Àkọlé fídíò,

Obasanjọ: Ọbasanjọ ní òhun yóò fi ìyókù ayé òun san oore Ọlọrun ni

Minisita feto ilera ṣalaye ninu ọrọ rẹ fawọn oniroyin pe ogoji eeyan ni wọn ti fi sahamọ ayẹwo lori arun yii nipinlẹ Ogun; ogun miran pẹlu ṣi wa labẹ ayẹwo nipinlẹ Eko.

Eto iwadii ilana fun itọpinpin arun coronavirus tuntun ọhun ni akọkọ nilẹ Afririka, eleyi si fi ẹri si ohun ti ajọ ilera agbaye, WHO sọ pe igbaradi orilẹede Naijiria yanranti ju bo ṣe n lọ lọpọ awọn orilẹede lagbaye.