Chris Oyakhilome: Wọn tí fòfin de iléeṣẹ́ ìròyìn Chris Oyakhilome lẹ́yìn tó sọ pé 5G lọ ṣokùnfà Coronavirus

Chris Oyakhilome

Oríṣun àwòrán, @lwsat

Ijọba ilẹ gẹẹsi ti fofin de ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ oluṣoagutan ijọ Christ Embassy, pasitọ Chris Oyakhilome lẹyin ti wọn fẹsun kan pasitọ naa pe o n waasu tako ilana ofin wọn.

Igbeṣẹ yii lo waye lẹyin ti pasitọ ọhun sọ pe nẹtiwọọki 5G lo ṣokunfa ajakalẹ arun Coronavirus.

Ileeṣẹ to n mojuto igbohunsafẹfẹ nilẹ naa, Ofcom ni iwaasu naa ti awọn eeyan orilẹede Gẹẹsi ni anfani lati tẹti si lee ṣe ijamba fun wọn, nitori naa, o lodi si ofin igbohunsafẹfẹ ilẹ wọn.

Bakan naa, wọn fẹsun kan ileeṣẹ amohunmaworan Loveworld to jẹ ti pasitọ naa pe o sọ pe ogun Hydroxychloroquine lagbara lati ṣegun arun Covid-19 to n ba gbogbo aye finra.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ Ofcom fi lede, wọn ni ileeṣẹ amohunmaworan Loveworld ti gba pe wọn ko ni ṣe bẹ mọ.

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ni ijiya ileeṣẹ tẹlifiṣọn Loveworld ni pe yoo maa sọ ninu igbohunsafẹfẹ rẹ pe oun kede ọrọ ti ko ni otitọ ninu nipa arun Cpvid-19.

Àkọlé fídíò,

Ṣé òótọ ni pé èèyàn leè kó Coronavirus láti ara aṣọ tàbí bàtà?

Ileeṣẹ naa si ti fesi pe oun yoo ṣe gẹgẹ bi ijọba ti pa laṣẹ fun un.

Ẹwẹ, ijọba UK atawọn onimọ ijinlẹ ti ni ko si ootọ ninu ọrọ ti awọn kan sọ kiri pe nẹtiwọọki 5G naa lee ṣokunfa arun Coronavirus.

Àkọlé fídíò,

Akure okada attack: Ọlọ́kadà tí àwọn afunrasí darandaran ṣá ní

Oyedepo: Òfin kẹ́lẹ́nu-ó-ṣọ́nu lórí ayélujára tíjọba ń gbèrò kò tọ̀nà fún Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, David Oyedepo Ministries International

Biṣọọbu David Oyedepo ti ṣe apejuwe ijọba to wa lorilẹede Naijiria bayii gẹgẹbi egun fun orilẹede Naijiria.

Biṣọọbu Oyedepo sọrọ yii lasiko to fi n waasu ni ijọ rẹ.

O ni ofin tawọn aṣofin n gbero lori kẹlẹnu o ṣẹnu lori ayelujara, (social media bill) iyẹn social media bill jẹ eyi to tako ọpọlọ ati arojinlẹ.

Agba iranṣẹ ọlọrun naa wa ṣalaye pe gbogbo ọmọniyan lo lẹtọ lati sọ ọrọ ẹnu wọn lai si ẹni ti yoo dawọn lẹkun.

Oyedepo ni "ni iwoye temi eyi ni ohun to buru juls ti yoo ṣẹlẹ si orilẹede Naijiria, iyẹn ijọba yii. Ohun ni ijọba to buruju, koda bii egun lo ri."

Àkọlé fídíò,

Africa eye: Fàyàwọ̀ igi gẹdú ló ń wáyé ní Gambia àti Senegal

O ni ijọba to wa lorilẹede Naijiria bayii ko ni pato ibi to n lọ ati pe gbogbo ilana iṣejọba lo ti fẹ sọ orilẹede Naijiria da bi Ọgba ẹranko.

Eyi kọ ni igba akọkọ ti Biṣọbu oyedepo yoo ma sọko ọrọ ranṣẹ si aarẹ Muhammadu Buhari ati ijọba rẹ.