Social Media Bill: Sowore fàáké kọ́rí, ó ní àbádòfin láti ṣàmójútó ayélujára kò lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ láéláé

Omoyele Sowore nibi ijiroro itagbangba ile aṣofin l'Abuja

Ajafẹtọ ọmjọniyan, Omoyele Sowore to kuro lahamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS laipẹ yii, ti faake kọri lori abadofin to yoo maa ṣamojuto ayelujara ni Naijiria to wa niwaju nile aṣofin agba niluu Abuja.

Sowore to ṣagbatẹru iwode ''Revolation Now'' sọrọ yii nibi ijiroro itagbangba lori abadofin naa lọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu kẹta ọdun 2020.

Sowore ni ko si anfaani kankan ti abadofin naa le ṣe fun araalu bi ko ṣe pe ko daabo bo awọn to wa ni ijọba.

Sowore fikun ọrọ rẹ pe abadofin naa ko nibii re, koda o ni abadofin naa ti ku patapata.

Oniruuru ajafẹtọ ọmọniyan, awọn onimọ nipa oju opo ayelujara ati ọpọ eeyan lo peju pesẹ sile aṣofin lọjọ Aje nibi ijiroro itagbangba naa niluu Abuja.

Ẹwẹ, ile aṣofin agba naa fidi rẹ mulẹ pe awọn ṣetan lati ṣe agbeyẹwo ero awọn ọmọ Naijiria lori abadofin ọhun.

Ile ni awọn aṣofin ko ni gbe igbesẹ ti yoo ṣe ipalara fun awọn ọmọ Naijiria lẹyin tawọn ba ṣe agbeyẹwo erongba wọn tan.

Ọpọ awọn ọdọ lo gbe kaadi ilewọ dani nibi ti wọn kọ oriṣiiriṣii nnkan to nii ṣe pẹlu ẹtọ ọmọniyan si.

Sẹnẹtọ Muhammed Sani Musa lati ipinlẹ Niger lo ṣagbatẹru abadofin naa.