Ado Bayero: Èyí ni àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Emir ìlú Kano tuntun

Aworan Emir ilu Kano

Oríṣun àwòrán, Aminu Ado Bayero/Instagram

Ijọba ipinlẹ Kano lọjọ Aje gbe igbesẹ meji eleyi ti ọkan ninu rẹ yẹ aga ipo Emir nidi ẹnikan ti o si gbe Emir mi si ori ipo.

Ẹni ti o di Emir ikẹẹdogun ni Kano bayi ti agbara si tiwa ni ikapa rẹ ni Aminu Ado Bayero.

Emir ni ki o to jẹ Emir Kano.Iya to bi jẹ ọmọ Emir ti aburo rẹ naa si jẹ Emir.

Kini awọn nkan miran to yẹ ni mimọ nipa Emir Ado Bayero? Ẹ jẹ ki a sé atupalẹ wọn lọọkọọkan.

Ilu Ilorin ni wọn ti bi iya to bi lọmọ

Alhaja Adeoti ti awọn eeyan a ma pe ni Iya Aminu ni Iya to bi Emir tuntun yi

Iya yi fun ara rẹ jẹ ọmọ ọba Abdulkadir Dan Bawa to jẹ Emir Kẹjọ nilu Ilorin.

Oríṣun àwòrán, Aminu Ado Bayero/Instagram

Oba Abdulkadir Baba Agba to jẹ oba Kẹẹwa ilu Ilorin si jẹ ẹgbọn Iya Aminu lọkunrin.

Wọn fi iya Aminu fun ọkọ iyẹn Emir Ado Bayero ilu Kano ti o si bi ọpọ ọmọ fun un.

Ọdun kannaa ni wọn bi EmirAminu Ado Bayero ati Lamido Sanusi

Ọdun 1961 ni wọn bi ọba Aminu Ado Bayero eleyi to se rẹgi pẹlu ti Sanusi Lamido Sanusi ti o gba ipo lọwọ rẹ yi.

Fulani to wa lati agbegbe Sullubawa ni Naijiria ni Aminu n ṣe.

O ti ati ipo Emir bọ si ipo Emir

Oríṣun àwòrán, Aminu Ado Bayero/Instagram

Ṣaaju ki wọn to fi Aminu Ado Bayero jẹ Emir ilu Kano,oun ni Emir ilu Bichi to jẹ ọkan lara awọn ilu to wa labẹ Emirate ilu Kano.

Yatọ si eleyi, o di ipo to pọ mu bi Dan Majen ilu Kano,ki o to bọ si ori apere gẹgẹ bi Emir tuntun.

O kawe gboye

Apa ariwa Naijiria ni Bayero ti ka pupọ ninuiwe to ka .sugbọn o tẹsiwaju lọ ilẹ Amẹrika nibi to ti kọ imọ nipa ọkọ ofurufu.

Imọ nipa ibaraẹnisọrọ ti a mọ si Mass Communication lo ka ni fasiti Bayero nilu Kano.

Ko pẹ lẹyin igba to kawe dari nipa imọ ofurufu ni o gba iṣẹ labẹ ile isẹ ọkọ ofurufu Kabo Air gẹgẹ bi alukoro.