Waste to Wealth: Ẹ̀gbin tìrẹ ni èròjà táwọn èèyàn míràn fi n ṣiṣẹ́ ajé, okoòwò ńlá ni

Waste to Wealth: Ẹ̀gbin tìrẹ ni èròjà táwọn èèyàn míràn fi n ṣiṣẹ́ ajé, okoòwò ńlá ni

Ijọba Naijiria ati ajọ eleto ayika lagbaye sefilọlẹ isẹ saatan dọrọ ti owo rẹ to miliọnu mẹẹdogun dọla, ti yoo pese isẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria.

Bakan naa ni ọmọ Naijiria kan, Lolade Oresanwo ati ijọba ilẹ Gẹẹsi da ileesẹ kan silẹ, to n sọ aatan di ọrọ, towo rẹ to triliọnu mẹrin ati aabọ Pọun.

Bakan naa ni ileesẹ yii ti gba awọn eeyan to to ẹgbẹrun mẹta sẹnu isẹ, to si tun n wọ́na abayọ̀ si isoro ẹgbin ayika ati ailera to lee mu wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n ba BBC sọrọ, Oresanwo ni ẹgbin tiwa ni ohun ọ̀rọ aje fun awọn eeyan miran nitori ọpọ eroja la lee fi ẹgbin se lati pawo wọle.

O wa rọ awọn araalu lati mase ri ẹgbin ni ayika wọn mọ amọ ki wọn maa ri eroja ọrọ aje to lee mu owo ati isẹ nla wa fun wọn.