Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Arsenal, Mikel Arteta náà ti fara káásá àrùn Coronavirus

Mikel Arteta Image copyright @Sporf

Awọn alakoso idije Premier League ti wọgile ifẹsẹwọnsẹ to yẹ ko waye laarin ikọ naa ati Brighton lọjọ Abamẹta lẹyin ti akọnimọgba ikọ Arsenal, Mikel Arteta lugbadi arun Coronavirus,

Iṣẹlẹ yi ti mu ki ikọ ọhun gbe kọkọrọ ṣẹnu ilẹkun papa iṣere ti wọn ti n ṣe igbaradi, lẹyin naa ni wọn ya awọn eeyan to ṣalabapade akọnimọgba naa sọtọ fun ayẹwo ati itọju.

Ni bayii, awọn alakoso idije Premier League yoo ṣepade pajawiri lọjọ Ẹti lati jiroro lori ọjọ iwaju idije naa ni saa yi.

Nigba ti esi ayẹwo rẹ fihan pe o ti Lugbadi arun ọhun, ẹni ọdunn ọdun mẹtadinlọgbọn naa ni "O ṣeni laanu."

Arteta sọ pe oun lọ ṣayẹwo lẹyin ara oun rẹwẹsi, leyi to fi han pe Coronavirus lo n ba finra.

Ṣugbọn o ti wa ni oun yoo fẹ lati pada sẹnu iṣe laipe ni kete ti awọn dokita ba ti fun ni aye ati ṣe bẹ.

Image copyright @BleacherReport

Ọkan lara awọn adari ikọ Arsenal, Vinai Venkatesham sọ fun awọn akọroyin pe ilera awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa ati awọn ololufẹ wọn lo jẹ ikọ naa logun.

Ikọ ọhun ti wa ni pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu naa ni wọn yoo fi si apapmọ fun ayẹwo.