Human Calculator: N kò lo idán àbí àlùpàyídà fún ìṣirò ọpọlọ tí mò ń ṣe

Human Calculator: N kò lo idán àbí àlùpàyídà fún ìṣirò ọpọlọ tí mò ń ṣe

Imọ isiro jẹ ohun ti ko wọpọ, o si maa n le fun ọpọ akẹkọ lati mọ, eyi to n mu ki wọn maa gbe ẹrọ isiro, taa mọ si Calculator kiri.

Amọ eyi ko ri bẹẹ fun akanda ẹda kan, Jolaade Tella, tii se ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti ọba oke fi imọ isiro da lọla.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Jolaade ni kakuletọ to jẹ eeyan (Human Calculator) ni wọn maa n pe oun, oun lee pin, yọ kuro tabi sọ di pupọ nisẹju aaya.

Jolaade ni oun kii lo idan abi alupayide amọ erongba oun ni lati di onimọ ẹrọ ayarabiasa lagbaye, to maa idasilẹ oniruuru akanse isẹ lori ayelujara.