Coronavirus: Báwo ni o ṣe le mọ̀ pé o ní àrùn Coronavirus?

Eeyan kan to bomu Image copyright Getty Images

Awọn eeyan ti o n ni awọn apẹrẹ kan ni wọn n gba ikils bayii lati fi ara wọn si isele fun ọjọ mẹrinla gbako lati fi mọ boya arun yii lo n jẹys lara wọn abi oun kọ.

Amọṣa, ṣe gbogbo ailera ni Coronavirsu bayii ni abi bawo?

Bawo ni o ṣe lee mọ boya ailera lasan lo ni tabi boya awọn ifarahan arun coronavirus lo n jẹyọ lara rẹ?

Bawo ni awọn ifarahan arun coronavirus ṣe maa n ri gan an?

Ohun ifarahan meji ti o maa n jẹyọ bi eyan ba ni arun corona virus ni ikọ ahugbẹ ni lemọlemọ ati iba. Bi o ba n ṣe ọfinkin tabi ti o ba ni iba. O ṣeeṣe ko jẹ aarẹ lasan ni, o le maa jẹ arun Coronavirus.

Amọṣa, irufẹ iba wo; tabi bawo ni iba rẹ ṣe lee lagbara to ti a fi lee funra pe boya coronavrus ti rapala wọle;

Atipe, ki gan an ni a lee mu gẹgẹ bii ikọ ahugbẹ ni lemọlemọ?

Eyi ni ki eeyan wukọ ṣugbọn ki o ma ba omi tabi kẹlẹbẹ jade. Eyii kii ṣe irufẹ ikọ ti eeyan n wu lẹẹkọọkan o, bikoṣe eyi ti yoo maa waye ni lemọlemọ laisi idi kan gbogbogi.

O daa o, iru iba wo ni iba to n ṣafihan coronavirus?

Hmmm...bi o ba ni irufẹ iba coronavirus, iwọ naa yoo mọ.

Lọrọ awọn akọṣẹmọṣẹ, bi ara rẹ ba ti gbona ju iwọn onka igbona ara to to metadinlogun celcius tabi ọgọrun Farenheit lọ?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLàá hàn mí: Ètò yìí ló ń kìlọ̀ fún wa láti mú ìmọ́tótó ní pàtàkì láti dènà Coronavirus

Amọṣa bi o ko ba ni ohun elo tamomita ti wọn fi n wọn bi nnkan ṣe gbona si, oo ṣakiyesi pe ara rẹ n gbona,bi eeyan ba si fi ọwọ kan ẹ, aya rẹ ati ẹyin rẹ yoo gbona wa.

Bi o ba wa kẹẹfin pe o ni eyikeyi ninu ifarahan wọnyii, maa jayo pa o, to ba jẹ wi pe iwọ nikan lo n gbe ile, yara duro sile fun ọjọ meje lọ.

Amọṣa to ba jẹ pe o n ba awọn eeyan miran gbe, gbogbo wọn gbọdọ wa ni igbele fun ọjọ mẹrinla

Bi o ba wa di wi pe aisan naa n tubọ burẹkẹ sii lara rẹ, tabi ko tete lọ bọrọ, a dara ki o kan si awọn ileewosan to ba wa nitosi rẹ ki o si ṣalaye fun wọn ni kikun.