Coronavirus in Nigeria: Àwọn awakọ̀èrò, ọlọ́kadà arìnrìnàjò faragbá nínú ìpa Coronavirus

Gomina ipinlẹEkiti, Kayọde Fayẹmi Image copyright Ekiti state government

Gẹgẹ bii ara igbesẹ lati dena arun Coronavirus ni ipinlẹ Ekiti, ijsba ipinlẹ naa ti ti gbogbo ileewe to wa nibẹ pa.

Ninu iwe aṣẹ mawobẹ (Executive order) kan to fi sita ni ọjọ Ẹti, gomina Kayọde Fayẹmi ni gbogbo ipesjọpọ to ba ti n ni ọpọ ero to ju ogun eeyan lọ, yala ni ile ijọsin, ile igbafẹ, awujọ oṣelu, ile ijo ati ile ọti ko gbọdọ waye mọ titi di igba ti nnkan ba fi rọgbọ lori arun naa.

Ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọ lori ẹrọ maohunmaworan lori iṣẹlẹ arun naa eyi to ti mu eeyan kan bayii ni ipinlẹ ọhun, gomina Kayọde Fayẹmi fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ Ekiti balẹ pe wọn ti kapa arun naa nipinlẹ ọhun ṣugbọn sibẹ oju lalakan fii ṣọri.

Image copyright Ekiti state government

Bakan naa lo paṣẹ pe awọn onimọto nibẹ ko gbọdọ gbe ju eeyan kan ni iwaju ati ero mẹta-mẹta ni ila aga kọọkan ninu ọkọ wọn.

Awọn aṣẹ miran ti ijọba ipinlẹ Ekiti pa lori kikapa arun yii niwọnyii:

Àṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti lórí àrùn Coronavirus
Àṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti Bí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ rẹ̀ yóò ṣe wáyé
Lori Ẹka eto ẹkọ Gbogbo ileewe, yala ti ijọ̀ba tabi aladani yoo wa ni titi pa bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta, ọdun 2020.
Lori ipejọpọ itagbangba Ko ni si aye fun ipejọpọ ọpọ ero to ba ti ju ogun eeyan lọ.Aṣẹ yii kan awọn:Ipejọpọ ẹsin.Inawo owanbẹ.Ipade oṣelu.Ile ijoIle imuti ati igbafẹIpade eto idagbasoke agbegbe fun awọn agunbanirọ, CDS ati bẹẹbẹẹ lọ
Lori iṣẹ ilu ati aladani Gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ati a;ladani ni yoo maa ṣiṣẹ wọn ni ile bẹrẹ lati ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ọdun 2020.Eyi kan awọn oṣiṣẹ ijọba gbogbo bẹrẹ lati akasọ kejila si isalẹ.Amọṣa, aṣẹ yi yọ awọn oṣiṣẹ ẹka pataki bii ilera, panapana, iṣẹlẹ pajawiri, oniroyin ati awọn aṣode ati oniṣe abo gbogbo silẹ.
Awọn oṣiṣẹ ijọba Gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ni wọn fun ni aṣẹ lati rii pe ẹrọ ibanisọrọ wọn n wa larọwọto wọn nigba gbogbo nitori ipe lee wa fun wọn lati farahan ni ibi iṣẹ lasikokasiko.
Lori lilọ bibọ ọkọ laarin ipinlẹ Ekiti ati lati awọn ipinlẹ miran wọ Ekiti. Ko gbọdọ si akoluyapọ ero bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, ogunjọ oṣu kẹta lọ.Awọn ọkọ akero gbọdọ rii daju pe eeyan kan ṣoṣo ni wọn n gbe si iwaju ọkọ pẹlu awakọ.Ko si gbọdọ ju ero mẹta-mẹta lọ ni ila ijoko kọọkan to tẹlee.Awọn ọlọkada ko gbọdọ gbe ju ero kan lọ lati din ifarakanra ku bi o ti wulẹ o mọ.Awọn ohun elo ifọwọ gbọdọ wa lawọn ibudokọ ero gbogbo.
Fun awọn olugbe ipinlẹ Ekiti ati iṣẹ ilu gbogbo Awọn olugbe ipinlẹ Ekiti gbọdọ maa wẹ ọwọ wọn mọ tonitoni lojoojumọ lati dena itankalẹarun yii.Gbogbo awọn ibudo ita gbangba ati ileeṣẹ gbogbo lo gbọdọ pese ohun elo ifọwọ si ẹnu abawọle ati abajade ileeṣẹ wọn ni kiakia.Oju omi ẹrọ pẹlu ohun elo agbemidani pẹlu ọṣẹ ifọwọ ati ọṣẹ apakokoro ọwọ, (hand sanitizer) gbọdọ wa lawọn ibudokọ ero, ile ounjẹ, ṣọọbu itaja, ọfiisi gbogbo, atawọn agbegbe miran ti ọpọ ero n wa lati ṣe koriya fun ọwọ fifọ loorekoore.
Lori awọn ọja gbogbo ati Karakata ọja Awọn iyalọja ati babalọja gbọdọ maa ṣeto ifọwọ wọn mọ ni tonitoni pẹlu ọṣẹ ati omi to mọ gaara, o kere julọ nigba mẹfa lojumọ.Awọn eeyan to n lọ si ọja pẹlu gbọdọ maa rii daju pe wọn n fọ ọwọ wọn pẹlu ọṣẹ ati omi nio kete ti wọn ba ti kuro ni ọja ki wọn to de ile. Eyi ni lati dena itankalẹ arun Coronavirus eleyi ti wọn ba fara ko lẹnu karakata.
Lori igbokegbodo ọkọ ati irinajo Ko gbọdọ si irinajo wọle tabi jade ni ipinlẹ Ekiti ayafi ti o ba di kanrangida lasiko yii.Bi o tilẹ jẹ pe a ko lee ti gbogbo ipinlẹ yii pa bayii, sibẹ a gbọdọ rii daju pe gbogbo awọn irinajo wọ ipinlẹ Ekiti lati awọn ipinlẹ miran dinku daada ki a lee daabo bo awọn olugbe ipinlẹ yii lọwọ kiko arun yii wọle lati ibomiran.

Àrùn Coronavirus ti tàn dé orílẹ̀èdè Eritrea

Orilẹede Eritrea ti fi lede wi pe awọn ti ni ẹni akọkọ to ni Coronavirus lorilẹede naa.

Ẹni ọdun mọ̀kandinlogoji ni ara ilẹ Eritrean to n gbe ni Norway.

Ọjọ Satide ni arakunrin naa de papkọ ilẹ wọ ni Asmara International Airport, ti wọn si ya a sọtọ fun ayẹwo to fihan pe arakunrin naa ti ni arun Coronavirus.

Bakan naa ni orilẹede Uganda ti paṣẹ ki ọkọ ofurufu kankan maṣe wọle si orilẹede naa lati dẹkun itankalẹ arun naa.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ni gbogbo igbesẹ ni ijọba ipinlẹ naa n gbe lati rii pe ọṣẹ arun Coronavirus nipinlẹ naa mọ leeyan kan to wa lọwọlọwọ.

Amọ orilẹede Democratic Republic of Congo, Gabon, SUDAN ati Burkina Faso ti darapọ awọn orilẹede ni ilẹ Afirika ti awọn to lugbadi arun Coronavirus ti gbẹ ẹmi mi.

Iwe iroyin ilẹ naa fi lede wi pe dokita to n ṣiṣẹ ni ileeṣẹ ijba ni ẹni to ku naa lẹyin to pada si orilẹede DRC lati ilẹ Faranse.

Ọjọ Eti lo gbe ẹmi mi lẹyin aisan ọna ọfun rẹ ko ṣiṣẹ daradara mọ.