Coronavirus in Nigeria: Ọmọ Nàìjíríà kan ṣàlàyé pé nǹkan ò dẹ̀rùn láyé coronavirus yí ní orílẹ̀èdè Italy

Lati igba ti arun Coronavirus ti bs sigboro agbaye, ko si eniyan ti arun naa ko tii mu ayipada ba igbe aye rẹ.

Pataki laarin awọn eeyan ti arun yii ti da bira ninu igbe aye wọn ati ọna ajọṣepọ wọn ni awọn eeyan orilẹede Italy.

Lootọ, ilu Wuhan lorilẹede China ni wọn ti kọkọ kẹẹfin arun yii eleyi to ti wa gbẹrẹgẹjigẹ di igi nla laarin awọn ipenija agbaye lasiko yii bayii.

Ni bayii orilẹede kan ti ọwọja arun yii ti mulẹ bi ọwara ojo ni orilẹede Italy nibi ti omilẹgbẹ awọn eeyan ti ko arun yii ti ọpọ si ti ku nipasẹ awọn ohun to jẹyọ lẹyin arun naa.

Nibẹ bayii, labẹ igbele ni olukuluku wa, lara awọn to s wa labẹ igbele yii ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria wa pẹlu.

Tolulọpẹ niyi, to n sọ ọrọ funwa lori ohun ti oju oju n ri nibẹ latigbati iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.