Coronavirus symptoms: Ó ti di Ọgbọ̀n èeyàn báyìí tó ti ní àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà

Oja Ipinle Eko Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ẹlòmíràn tún ti lùgbàdì àrùn Corona Virus nílùú Abuja àti Eko

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC tun ti kede pé ènìyàn mẹta miran tun ti ko arun coronavirus niluu Eko

O ti di eeyan ọgbọn bayii to ti lugbadi arun naa lorilẹede Naijiria.

Ajọ NCDC ṣalaye pe eeyan meji ninu wọn lo ti kuro ni ile iwosan lẹyin ti wọn gba itọju tan.

O ti di eeyan mẹrin to ti lugbadi arun coronavirus bayii, nigba ti ipinlẹ Eko ko mọkandinlogun ninu rẹ, eeyan meji lo karun naa nipinlẹ Ogun, eeyan kọọkan larun naa nipinlẹ Oyo ati Ekiti.

Àrùn coronavirus wọ ìpínlẹ̀ Oyo

Ajọ NCDC ti kede tẹlẹ pe eeyan miran to ni aarun coronavirus lorilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti ajọ naa fi soju opo twitter rẹ lowurọ ọjọ Aiku, eeyan kan naa sọ iye awọn ti wọn kede pe wọn ni arun naa ni ọjọ Aiku nikan di mẹrun bayii.

Coronavirus symptoms: Èèyàn mẹ́ta míràn ti ní àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà

Image copyright Seyi makinde

Eeyan mẹta miran tun ti ko arun Coronavirus lorilẹede Naijiria bayii.

Ajọ to n gbogunti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ṣalaye pe o ti di eeyan marundinlọgbọn to ti ni arun naa bayii.

Iroyin naa fi idi rẹ mulẹ pe ipinlẹ Eko ni awọn mẹta tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣawari naa ti wa.

Image copyright Getty Images

Bakan naa ni wọn tun fi kun un pe, awọn mẹtẹẹta lo ti rinrinajo lọ sawọn orilẹede ti arun yii ti wọpọ lagbaye laarin ọjọ meje sẹyin.

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun lorilẹede Naijiria, NCDC ko ṣai fi da awọn eeyan loju pe akitiyan n lọ bayii lati ṣawari gbogbo awọn eeyan ti wsn ti ni ajọṣepọ pẹlu awọn eeyan mẹta yii.

Ajọ naa wa n rọ awọn ọmọ Naijiria to rinrinajo pada wa sorilẹede Naijiria laarin ọjọ mẹrinla sẹyin si asiko yii lati fi ara wọn sabẹ igbele fun ọjọ mẹrinla lati mọ boya wọn ni arun naa tabi ara wọn da ṣaka.