Fuel Price: Àjọ PPPRA epo bẹntiró ti di N121.50 ní Nàìjíríà báyìí

Image copyright Twitter/PPPRA

Ijọba ti kede ẹkunwo epo bẹntiro lati ọgọrun un nairia le ni naira mẹtalelogun aabọ(N123.50) si ọgọrun un nairia le ni naira mókanlelogun aabọ(N121.50).

Ajọ PPPRA to n ṣamojuto owo epo rọbi lo ṣe ikede naa ninu atẹjade kan to fi sita.

Ajọ PPPRA ṣalaye ninu atẹjade naa wi ẹdinwo epo bẹntiro naa wa ni ibamu pẹlu idasilẹ ṣiṣe ayẹwo owo epo rọbi oṣu kẹta ọdun yii.

Bi owo epo rọbi ṣe walẹ lọja agbaye lo jẹ ki adinku ba owo tawọn alagbata epo fi n gbepo wọ Naijiria lati oṣu kẹta ọdun 2020 nitori ajakalẹ aarun coronavirus.

Ijọba ti kọkọ ṣe edinwo epo bẹntiro lati naira marunlelogoje si naira marunlelọgọfa lọjọ kejilogun oṣu kẹta.

Image copyright Twitter/PPPRA

Lati oṣu kẹta naa ni ijọba ti sọ pe loṣooṣu ni ajọ PPPRA yoo maa ṣe ayẹwo owo epo bẹntiro ni Naijiria.

Ẹ̀dínwó epo bẹntíró tí NNPC kéde kò kan ará ìlú

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ti gbàlù gbájó lẹ́yìn ti wọ́n gbọ́ ìkéde pé ilé iṣẹ́ to n rí si epo rọ̀ọ̀bì ni Nàìjíríà (NNPC) tí mú àdínkù bá owó epo rọ̀ọ̀bì.

Sùgbọ́n oo àlàyé láti ẹnu olùdarí ìjáde àti ìwọlé epo nínú ẹgbẹ́ IPMAN to tún jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ náà tẹlẹ̀ Mike Osatuyi, sàlàyé pé, èdinwó náà ko tii sí fún ará ilú.

O ní gẹ́gẹ́ bi àjọ NNPC ṣe ti kéde láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ epó bẹntiro tí n já wálẹ̀ l'Ágbàyé pé oṣooṣù ni àwọn yóò ma sọ iye ti àwọn ará ilú yóò maa ra epo.

Image copyright OSatuyi
Àkọlé àwòrán Ẹ̀dínwó epo bẹntírò ti NNPC kede kò kan ará ilú

Osatuyi ni lóòyọ́ ni wọ́n kéde, sùgbọ́n lẹ́yìn ìkéde wọ́n ó yẹ ki àjọ PPMC náà fi ikéde tirẹ̀ sita láti mọ iyé ti o tọ́ fún ará ilú láti maa ràá.

Image copyright Getty Images

"Ọ̀rọ̀ epo kìí ṣe bi iṣu àti ata lọ́ja, wọ́n maa n pé olúkúlúkù láti wá gbé epo ni, iyé ti ẹni náà ba si báa ni yóò ràá, nítori náà iye ti olúkúlúkò yóò si taa yoo yàtọ̀ si ara wọ́n"

Image copyright Osatuyi
Àkọlé àwòrán Fuel Price: Ẹ̀dínwó epo bẹntírò ti NNPC kede kò kan ará ilú

Ẹkúnrẹ́rẹ́ àlàyé Mike Osatuyi rèé

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFuel Price: Ẹ̀dínwó epo bẹntírò ti NNPC kede kò kan ará ilú

Ìjọba dín owó epo bẹntiró sí N108

Fuel price: Ìjọba dín owó epo bẹntiró láwọn ibùdó ìjápo (depot) sí N108 láti N113

Image copyright AFP/Getty Images

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede adinku owo epo bẹntiro kuro ni naira mẹtalelaadọfa naira to wa tẹlẹ si naira mejidinlaadọfa naira gẹgẹ bi iye ti wọn yoo maa ta jala epo lawọn ibudo igbepo gbogbo lorilẹede Naijiria.

Atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ri si karakata owo epo lorilẹede Naijiria, PPMC fi sita ṣalaye pe igbesẹ naa wa lati tubọ mu ki ọja rẹ tubọ ta si ni ibamu pẹlu aṣẹ ajs to n ri si idiyele owo epo lorilẹede Naijiria, PPPRA gbe kalẹ lori iye ti wọn yoo maa ta epo lorilẹede Naijiria.

atejise NNPC Image copyright NNPC/Twitter
Àkọlé àwòrán Iye owo ti awọn alagbata epo n ra awọn epo ni ibudo igbepo (depot) nikan ni adinku yii ba.

Ọgbẹni Musa Lawan, oludari agba ileeṣẹ to n ri si idunadura epo lorilẹede Naijiria, PPMC, ti atẹjade naa kede o fi ọrọ naa sita nio igbesẹ adinku owo epo lawọn ibudo ijapo gbogbo naa yoo mu ki wọn lee tete ta omilẹgbẹ biliọnu jala epo ti waọn ni kaakiri aka wọn sita lowo ti ko ga ju ara rọ fawọn onibara rẹ.

O fi kun pe lẹyin ti wọn fojuwo bi oju ọjọ ṣe ri lọja epo ni wọn fi gbe ẹdinwo naa kalẹ.

Amọṣa, ẹdinwo tuntun yii ko kan epo disu.

Nigeria lockdown: Báyìí ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe dá ìrìnkèrindò ọkọ̀ dúró l'Abuja

Abuja
Àkọlé àwòrán ẸNi ti ko ba lo ibomu yoo pada sile rẹ tabi ko jẹ bulala

Iroyin lati Abuja, to jẹ Olu ilu orilẹede Naijiria ti fi han pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to waye nibẹ ko ṣẹyin iṣẹ takuntakun awọn agbofinro lati ri pe awọn eeyan tẹlẹ ilana ti ijọba gbe kalẹ lasiko yi.

Ọpọ awọn eeyan to n kọja lati ipinlẹ Nasarawa to wa lẹba ilu Abuja ni ko raye kọja, ni bi awọn agbofinro ọhun ṣe n da awọn ti ko ba wọ ibomu pada lẹnu ibode ilu naa.

Iroyin ni wamuwamu ni awọn ọmọ ologun, awọn oṣiṣẹ abo ararẹni labo ilu, NSCDC ati ajọ to n risi igboke gbodo ọkọ, FRSC ro lẹnu ibode ọhun.

Bi wọn ṣe n ṣayẹwo gbogbo awọn to ba fẹ kọja naa ni wọn n da ẹnikẹni ti ko ba wọ ibomu pada, tabi ki irufẹ ẹni bẹ jẹ bulala.

Abuja
Àkọlé àwòrán Ni kete ti ijọba apapẹ dẹwọ igbele, ile ifowopamọ lawọn eeyanb kan kọkọ fori le

Bí Eko ati Abuja ṣe rí rèé lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n dẹ ọwọ́ igbele Coronavirus

Ayẹwo ti awọn agbofinro naa n ṣe ti fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ, ti ko si dun mọ awọn eeyan naa ninu nitori wọn ni awọn mii ma n lo wakati mẹrin lojukan.

Ṣaaju ni minisita olu ilu naa ti sọ fun awọn olugbe agbegbe bi Nyanya lati joko sile wọn, ṣugbọn ọpọ ninu awọn eeyan ọhun sọ pe wọn ni lati jade si igboro nitori atijẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNiyi Akinmolayan tó ṣe fíìmu àwòrán-dèèyàn Cartoon nípa COVID-19 tó la ayé já ní N

Lara awọn eeyan ọhun to ba BBC sọrọ ni ti Coronavirus ko ba pa wọn, ebi lo ma pa wọn sile, nitrori naa ko si ohun miran ti wọn le ṣe ju ki wọn jade.

Ni kete ti ijọba apapẹ dẹwọ igbele naa lọjọ Aje, ọjọ kẹrin oṣu karun ọdun 2020, ohun akọkọ tawọn eeyan naa ṣe ni abẹwo sile ifowopamọ ti wọn n lo lati gba owo wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸsẹ̀ bàtà, èso kukumba ni wọ́n fi ń já àbálé àwọn ọmọ Nàìjíríà ní Libya

Coronavirus symptoms and treatment: Bí Eko ati Abuja ṣe rí rèé lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n dẹ ọwọ́ igbele Coronavirus

Awọn ero ni ibudokọ ero l'Eko

Ní báyìí tí ìjọba àpapọ̀ tí dẹ okun lọrun àṣẹ kònílé ó gbélé, ó dàbí ẹni pé àwọn aráàlú Èkó àti Abuja tí gbàgbé òfin títa kété síra ẹni.

Irinke-rindo ikọ BBC làwọn ojú pópó n'ilu Eko lónìí ọjọ́ Ajé, ṣàkíyèsí pé, ní agbègbè Ojodu-Berger, ṣe ni àwọn aráàlú ń du ọkọ wọ, tí wọ́n ko si bọ̀wọ̀ fún òfin ìtakété síra ẹni, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọkọ èrò ń gbé èrò

kún inú mọto wọn dẹnu.

Ṣáájú sì ni ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko ti kede pé ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún èrò táwọn ọlọkọ ń gbé sínú ọkọ wọn tẹ́lẹ̀, ní kí wọ́n máa gbé báyìí, kí àwọn èrò leè ráyè takete síra wọn.

Kódà, ní ibùdókọ̀ ọkọ èrò ìjọba, BRT to wá ní Berger, àwọn èrò tó fẹ́ wọnú àwọn ọkọ náà kò bọ̀wọ̀ fún òfin ìtakété síra ẹni lórí ila tí wọn tó sì, láti wọ ọkọ náà.

Bi o tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn yìí ló aṣọ ibomu tó jẹ́ atọwọda, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera ti kede tẹ́lẹ̀ pé èyí kò tó láti dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ Coronavirus.

Awọn ero ni ibudokọ

Ní olú ìlú ilẹ wá, Abuja, ẹwẹ, àwọn òṣìṣẹ́ nibẹ ya bo ojú pópó láti lọ síbi isẹ koowa wọn lọ́jọ́ Aje.

Ní agbègbè Nyanya-Mararaba tí ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ń gbé, ṣe ni àwọn agbofinro gbé igi dabu ọna, láti tọpinpin lílọ bibọ ọkọ sí Ìpínlẹ̀ Nasarrawa, tíì ṣe Ìpínlẹ̀ miran to mule tí Abuja, tí wọ́n si ń rí dájú pé àwọn èèyàn náà wọ aṣọ ìbòjú.

Kódà, àwọn agbófinró ń yẹ ara àwọn èrò àti ọlọkada wo pẹ̀lú ẹ̀rọ, kí wọ́n tó kọjá, tí wọn sì n da àwọn ọlọkọ tó bá lòdì sí òfin pada.

Awọn ero ni ibudokọ kan l'Eko

Wàyí o, bi aibọwọ fún òfin ìtakété síra ẹni ṣe ń wáyé n'ilu Eko, naa lo ṣe ri ni Abuja, nítorí báwọn èrò àti ọlọkada ṣe tó fún ayẹwo ọlọ́pàá, lòdì sí òfin ìtakété síra ẹni, ṣe ni wọn to si ẹyin ara wọn lai fi ààyè

kankan silẹ.

Ẹnikan nínú wọn tiẹ̀ sọ fún ikọ ìròyìn BBC pé, àǹfààní ńlá ni ìjáde wọn òní jẹ láti gba atẹgun sára.

Amin iyasọtọ kan

Coronavirus: Ijọba ìpínlẹ̀ gbé òfin jáde fún àwọn tó n padà sẹ́nú iṣẹ́ lẹ́yìn k'ónílé o gbélé

Ọja Idumọta Image copyright Getty Images

Oni ọjọ Aje ni orilẹ-ede Naijiria bẹrẹ si ni dẹ okun ofin konile-o-gbele to fi sita nitori coronavirus nilu Abuja, ipinlẹ Ogun, ati ipinlẹ Eko lati le din ipa buruku ti aarun naa le ni lara ọrọ aje ku.

Lootọ Aarẹ Buhari lo paṣẹ naa, ṣugbọn gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fi awọn ilana ti awọn eeyan gbọdọ tẹle sita.

Lara awọn ilana naa ni pe awọn oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele 'Level 15' soke nikan ni yoo pada sẹnu iṣẹ.

  • Isede yoo maa wa lati aago mẹjọ alẹ si mẹfa idaji. Awọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn ṣe koko bi i ẹka epo bẹtiro, ounjẹ, iṣẹ agbẹ ati bẹẹbẹ lọ nikan ni ofin yii ko de.
  • Awọn ọja ti wọn ti n ta ounjẹ yoo ma jẹ ṣiṣi lọjọ Iṣẹgun, Ọjọbọ ati Abamẹta laarin aago mẹsan owurọ si mẹta ọsan.
  • Awọn ọja ati ṣọọbu ti kii ṣe ti ounjẹ yoo maa ṣi ilẹkun wọn laarin aago mẹsan owurọ si mẹta ọsan ni ọjọ Aje, Ọjọru ati ọjọ Ẹti. Gbogbo awọn ontaja lo si gbọdọ lo ibomu-bẹnu, ki wọn o si tun ṣeto sanitaisa ni ọja wọn.
  • Dandan ni fun araalu lati lo ibomu-bẹnu lasiko ti wọn ba wa ni ita gbangba.
  • Awọn banki ati ileeṣẹ aladani ko gbọdọ faaye gba ju ìdá ọgọta oṣiṣẹ wọn lẹẹkan naa, wọn si gbọdọ maa ṣiṣẹ laarin aago mẹsan owurọ si mẹta ọsan.
  • Fun awọn ile ounjẹ, gomina Sanwo-Olu sọ pe wọn le maa taja laarin aago mẹsan aarọ di aago meje alẹ nitori awẹ Ramadan to n lọ lọwọ. Ṣugbọn, onibara wọn kankan ko gbọdọ joko jẹun nile ounjẹ.

Ṣugbọn ṣa, ofin ṣi de ipejọpọ ọpọ eniyan, awọn ile ijọsin ati ileewe.

Awọn to ni aarun coronavirus ni Naijiria pọ si lọsẹ to kọja, pẹlu bi eniyan 2,558 ṣe ni aarun naa bayii, mẹtadinlaadọrun si ti ku.

Amin iyasọtọ kan

Gómínà ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu ti kede pé pé kí gbogbo òṣìṣẹ́ ìjọba láti ipile kejila si isàlẹ̀ jòkó silé wọn fún ọsẹ̀ méji.

Sugbọ́n ó ni ikéde yìí yọ àwọn to ṣe àwọn osiṣẹ́ eleto ààbò, awọn panapana àti àwọn onimọ iṣegun.

Bakan náà ni Gomina ni ìjọba ti ṣe àfikún àwọn ilé iwosan ti wọ́n le ko àwọn ènìyàn si.

" a mọ bi ǹkan to wà ni ìwáju wa ṣe toni tó a si ti ṣetan láti koju rẹ, a ti n ba àwọn asoju àwọn ọlọja sọ̀rọ̀ àti àwọn olóri awakọ láti ri dáju pé wọ́n tẹle ìlàna jijina si ẹnikeji."

"Ri dájú pe o wà ni ìgbéle fun ọjọ mẹrinla ti o ba ṣẹsẹ tirin ajo dé si Naijiria. Eyi ni ǹkan to tọna láti ṣe."

" A ni láti ji giri si idojukọ wa. A o bori ti ifọwọsowọpọ ba wa láàrin àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko, a ti ri irú idojukọ bayiìí tẹlẹ".

Ẹ̀wẹ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara náà ti ni ki gbogbo oṣiṣẹ tirẹ maa siṣẹ́ láti ilé.

Nínú àtẹjade kan ti Gomina ìpínlẹ̀ Kwara Abdulrahman Abdulrazaq fọwọ́ si lo ti sàlaye pé botill jẹ́ pé ìpínlẹ̀ Kwara ko tii gba nipa ẹnikẹni to ni à[run náà sibẹ̀, iná ko se fi sori orule sùn.

Gomina fi kún pé igbẹ́sẹ̀ ti n lọ lọ́wọ́ lóri eto la'ti mu ki àwọn ilé iwosan ipinlẹ Kwara lé sàmójú to ààrun náà.

Ní báyìí eniyan ọgbsn lo ti ni ààrun náà ni orill èdè Naijira