Coronavirus in Nigeria: Esì àyẹwò ọmọ ati ìyáwọ ọmọ Atiku ti jáde

Bauch state Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Mò n lọ fun ìgbélé nítori mo ṣe alábapàdé ọmọ Atiku- Gomina Bauchi

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Bauchi fi sita ni a ti rii pe oun nikan ni aarun naa mu laarin awọn mẹfa ti wọn jọ kọwọrin.

Wọn ṣalaye pe iwadii ti fidiẹmulẹ pe awọn ọmọ ati ẹbi rẹ wa ni alaafia lai ni aarun coronavirus.

Ajọ NCDC si ti gbe igbesẹ to yẹ lati ya gomina Bala muhammed sọtọ bayii ki o ma baa le tan aarun naa kalẹ.

corona Image copyright Bauchi
Àkọlé àwòrán Wọn ṣalaye pe iwadii ti fidiẹmulẹ pe awọn ọmọ ati ẹbi rẹ wa ni alaafia lai ni aarun coronavirus.

Gomina Bala Muhammad yii lo ti figa kan jẹ minista fun olu ilu Naijiria, Abuja ki o= to dije dupo gomina ipinlẹ Bauchi.

Ẹ wo ǹkan to sẹlẹ̀ sí ọmọ àti ìyàwó ọmọ Atikú tó lùgbàdì ààrun Coronavirus

aTIKU aBUBAKR Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹ wo ǹkan to sẹlẹ̀ sí ọmọ àti ìyàwó ọmọ Atikú ti lùgbàdì ààrun Coronavirus

Ìdúnú subú láyọ fún ẹbi àtikù nígbà ti èsì ayẹwò Coronavirus ìyáwó ọmọ Atiku àti ti àwọn ọmọ jáde ti wan ko si ni ààrun náà.

Ọmọ Atiku Mohammed ti wọ́n fi si ipamọ ni ilé ikwosan ikọni to wà ni Gwagwalad nilú Abuja nítori pé àyẹwo fi han pé o ni ààrun Coronavirus lọ́jọ́ Aiku.

Mohammed fẹ Badriyya to jẹ ọmọ gomina Bauchi Ahmed Muazu to tun jẹ alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tẹ́lẹ ri.

Lásìkò to n ba àwọn onírolyin sọ̀rọ̀ ọgbẹni Zakari Aliyu to jẹ igbakeji alaga ilé igbé rẹ sàlàyé pé ko si ibẹru bojo nítori pe ẹbi ẹni ti wọ́n n sọrọ gan ko ni ààrun náà.

Aliyu ni " ọkunrin ti wan gbé lọ ni dédé àgo kan oru yẹn ni à[run Coronavirus, sùgbọ́n ìyáwó àwti àwọn ọmọ rẹ ko ni, sùgbọ́n o àwọn náà yóò wà ni igbélé fún ọjọ mẹrinla, mo si dúpẹ lọ́wọ́ ìyàwó rẹ pe o fọwọsowọpọ pẹlu wá".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn fíìmì òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú

Ọmọ Atiku ni ìròyìn sọ pé o de láti orilẹ̀-ède Switzerland si orill-èdè naijiria ti o si jẹ ọkàn lára àwọn orilẹ̀-è[de ti o n bààrun Coronavirus fira

Mò n lọ fun ìgbélé nítori mo ṣe alábapàdé ọmọ Atiku- Gomina Bauchi

Gomina ìpínlẹ̀ Bauchi, Bala Muhammed ti kéde pé òun náà yóò lọ fi ara òun si ìgbélé, lẹ́yìn ti ìgbákeji ààrẹ àná lórilẹ̀-èdè Naijiria fi léde pé pé ọmọ oun ti lugbàdi ààrun Coronavirus.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Bauchi sàlàyépé òun àti ọmọ Atiku 'sun pàde àra àwọn nínú ọkọ bàlú láti ilú Eko lọ si ilú Abuja ti àwọn si bọ ara àwọn lọ́wọ́

Oludári ilé iṣẹ́ radio naijiria nígbà kan ri Ladan Salihu fi idí èyí mull lori àtẹjiṣẹ́ twitter rẹ̀ pé gbogbo àwọn ti àwọn ba ọmọ náà rin irin ajò ni àwọn ti lọ fi ara àwọn pamọ.

O ní àwọn ti fi ara àwọnnkalẹ fun àyẹwò báyìí ti àwọn si ni ìgbàgbọ́ pé akan ni èsì rẹ yóò jásí.

Nínú àtẹjjáde kan ti Gomina Bauchi fi sita láti ọwọ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ lórí iròyìn Mukhtar Gidado, sàlàye pé àwọn jọ wó ọkọ ofurufu Aero Contractor ní to sì jẹ́ri si pé wọ́n jọ bọ́wọ lọ́ja náa.

Gómina ko fi àmì kankan hàn báyìí, bákan náà losi ti wọ́gile gbogbo àwọn ìpáde to yẹ ki o ní.

Coronaviris in Nigeria: Ọmọ Nàìjíríà kan ẹni ọdún 67 tó kó àrùn COVID-19 ti di olóògbé

Image copyright Twitter/Federal Ministry of Health

Ọmọ Naijiria kan ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ti jẹ Ọlọrun ni pe lẹyin to lugbadi arun corona virus.

A gbọ wi pe ọkunrin naa ṣẹṣẹ rinrin ajo de lati ilẹ Gẹẹsi ni ki o to tẹri gbaṣọ ni Naijiria.

Ajọ NCDC ṣalaye loju opo Twitter rẹ pe ọkunrin naa ti ni awọn aisan kan lara tẹlẹ bi arun itọ ṣuga ati arun ti oloyinbo n pe ni Myeloma.

O jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlaadọrin.

Atẹjade ajọ WHO sọ pe O ṣẹṣẹ de pada lati ilẹ Gẹẹsi laipẹ yii nibi to ti lọ ṣe itọju aisan ara rẹ.

Wọn ni ko pẹ to gba itọju "Chemoteraphy" tan nile iwosan nilẹ Gẹẹsi to fi pada wa sile.

Wọn ni o ti n gba itọju lori awọn aisan naa ki arun COVID-19 to mu lọ.

Ajọ NCDC kẹdun pẹlu idile oloogbe naa.

O ti di eeyan mẹrindinlogoji to ni ni arun naa ni Naijiria bayii ninu eyi ti awọn meji ti jade nile iwosan.

Ọmọkùnrin mi ti kó coronavirus, ẹ bá mi fi sínú àdúrà yín- Atiku

Ẹ fi adura ranmi lọwọ nitori ọmọkunrin mi ti lugbadi arun coronavirus to n tan kalẹ kaakiri agbaaye bi ina inu ọyẹ.

Image copyright Facebook/Atiku Abubakar

Oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abuabakar lo fọrọ yii lede loju opo Twitter rẹ lalẹ ọjọ Aiku.

Atiku ṣalaye pe oun ti sọ fun ajọ to n gbogun ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC, ati pe ọmọ naa ti n gba itọju nile iwosan olukọni fasiti Abuja to wa ni Gwagwalada.

''Inu mii yoo dun ti ẹ ba le fi ọmọ mi sinu adura yin, ki onikaluku rọra maa ṣe nitori otitọ ni pe arun coronavirus wa nita,'' Atiku lo sọ bẹẹ.

Atiku tun gboriyin fawọn oṣiṣẹ ile iwosan kaakiri orilẹede Naijiria fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lasiko ajakẹlẹ arun covid-19 yii.

''Mo rọ gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn maa mi kan ti a o fi ṣẹgun arun coronavirus ni Naijiria,'' Atiku lo woye bẹẹ.

Ọgbọn eeyan lajọ NCDC ti kede pe wọn ti ni arun coronavirus ni Naijiria, ninu eyi ti awọn meji ti ri iwosan.