Efunsetan Aniwura: Àwọn fíìmù òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú

Efunsetan Aniwura: Àwọn fíìmù òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú

Ajihinrere Felicia Iyabode Ogunsola ti gbogbo eeyan mọ si Efunsetan Aniwura, Iyalode ilu Ibadan ti kilọ fawọn oṣere tiata lati dẹkun aṣa ṣiṣira silẹ ninu fiimu.

Efunsetan ni aṣa buruku gbaa ni, o ṣalaye pe kiii ṣe ohun to dara ki aṣiri ọyan maa han sita, iṣẹ Eṣu ni.

O fikun ọrọ rẹ pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara nigba ti oun fi n ṣere labẹ ogbontarigi oṣere, oloogbe Iṣhola Ogunsola ti ọpọ mọ si Isho Pepper.

Iyabode Ogunsola ni aṣa ailojuti, aṣa awọn oyinbo ni awọn oṣere ode oni ti gbe wọ ere tiata Yoruba.

O ni aṣa ki a maa yinbọn popopo ninu fiimu lo kọ awọn ọmọ lole laye ode oni, dipo kiawọn ọmọde maa ri ẹkọ kọ nibẹ.

O rọ ọpọ oṣere ti wọn ko tii lọ kẹkọọ ere tiata ṣiṣe nibi kankan pe ki wọn yara tete lọ kẹkọọ nitori ko si oṣere kan ti ko kẹkọọ labẹ ẹnikan nigba tawọn naa.