Coronavirus in Nigeria: Ìtànkálẹ̀ coronavirus ṣe ìdíwọ́ fún ìrun Jimọ

Àkọlé àwòrán Mọṣalaaṣi An-nur nilu Abuja niyii, gbajugbaja ni, ṣugbọn itankalẹ aarun coronavirus sọ ọ di ofo. Irun Jimọ ko waye nibẹ lonii.

Itankalẹ aarun coronavirus ṣe idiwọ fun awọn mọṣalaaṣi pupọ, nitori pe ọpọ wọn ni ko lanfaani lati kirun apapọ lọjọ Jimọ.

Abẹwo akọroyin BBC si mọṣalaaṣi apapọ Naijiria nilu Abuja fihan pe, paro-paro lo da a.

Àkọlé àwòrán Titipa ni ilẹkun Mọṣalaaṣi apapọ Naijiria nilu Abuja wa. Irun Jimọ ko waye nibẹ.

Bakan naa ni nkan ri ni Mọṣalaaṣi An-nur to jẹ gbaju-gbaja nilu Abuja bakan naa.

Àkọlé àwòrán Wọn ko ṣi ilẹkun Mọṣalaaṣi An-nur rara, debi ti awọn eniyan o wa a kirun.

Ayipada yii ko yọ ilu Kaduna silẹ.

Botilẹjẹ pe ko ti i si ẹni to ni aarun naa nibẹ, ijọba ipinlẹ naa kede ofin konile-o-gbele, fun gbogbo wakati mẹrinlelogun to wa ninu ọjọ kan.

Koda, awọn aṣoju ijọba duro si oju ọna, ti wọn si n da awọn eniyan duro.

O dabi ẹni pe ofin ijọba ni awọn ibikan pe ki olukulu joko sile rẹ ti n fidimulẹ ni awọn ilu kan ni Naijiria.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kéde pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí coronavirus

Image copyright Facebook/Seyi Makinde

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ti ilẹkun ileeṣẹ ijọba pa fun ọsẹ meji gbako nitori itankalẹ aarun coronavirus nipinlẹ naa.

Gomina ipinlẹ naa, Seyi Makinde lo kede bẹ ẹ ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Twitter rẹ lọjọru.

Aṣẹ naa yoo bẹrẹ iṣẹ ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2020.

Makinde sọ pe awọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn jẹ koṣeemani nikan ni yoo ma lọ si ibi isẹ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Fífi nkan bó ìmu nìkan kò le dènà kíkó coronavirus

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ni ki gbogbo ọjà wà ni títì pa, sùgbọ́n...

Gomina ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-olu ti kede pe ki gbogbo ọja ní ìpínlẹ̀ Eko wa ni títìpa láti ọjọbọ lọ nítori pe ìbẹru bojo ti wà láàrin ilú.

Oja
Àkọlé àwòrán Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ni ki gbogbo ọjà wà ni títì pa, sùgbọ́n...

Gomina ṣe ikéde yìí lósàn oni lásìkò to n ba àwọn oniroyin sọ̀rọ̀, o ní gbogbo àwọn to ba n ta ọjà ti ko niṣe pẹlu Ounjẹ jijẹ àti àwọn to nta òògùn fun ilé ìwòsàn tàbi ọlọdani ki wọ́n jòkó silẹ̀ fun ọṣẹ kan.

O ni èyi ṣe pàtàkì gẹ́gẹ̀ bi ọ̀nà láti da ìtànkalẹ̀ àrun náà dúro nitori oun gbòrò si ni ojoojumọ ni, eyti yoo si ṣe ilu lánfani ti gbogbo ènìyàn ba fi ọwọsọwọpọ.

O ní ki olukuluku dáwọ ipejọpọ duro, yala ìkómọ ni tabi igbeyawo, eyi ni yóò ran ijọba lọ́wa láti tete de ọdọ àwọn to nilo iranlọ́wọ́.

Gmina ni àrun náà ko dá ojú ẹnikẹni mọ, yala, olwo tabi talaka, ẹni to n gbe ilé ijọba tabi ẹni to n gba Mushin, sùgbọ́n títẹle ìlàna ijọba yóò ṣe ànfani to pọ fun gbogbo èniyan.

Gomina fi èrò ìgbàgba han pé, àrun buruku ko ni ya ilé ẹnikẹni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'
Afikun nipa aarun Coronavirus

Nǹkan méje tí yóò ṣẹlẹ̀ nìyíí tí ìjọba bá kéde òfin kónílé ó gbélé nítorí coronavirus

Alufa Don Carlo Chiomento ni ṣọọṣi Image copyright Getty Images

Ofin konile o gbele jẹ ọna kan pataki ti ijọba kaakiri agbaye fi gbogun ti itankalẹ arun coronavirus to n ṣọṣẹ lọwọlọwọ.

Lati oṣu kejila ọdun 2019 ti arun naa bẹrẹ lorilẹede China, o ti ran kaakiri ọpọlọpọ orilẹede agbaye bayii.

Orilẹede Rwanda ni orilẹede ilẹ Afirika akọkọ to kede ofun gbele ẹ, ọsẹ meji ni ijọba fi kede ofin konile o gbele naa fi wa nilẹ.

Kinni ofin konile o gbele tumọ si gan an?

Ofin konile o gbele tumọ si wi pe ẹnikẹni gbọdọ joko si ile lai lọ si ibi kan.

Ibi ki bi ti nnkan meje yii ba ti ṣẹlẹ, ki ẹ mọ pe ofin konile o gbele n ṣẹlẹ nibẹ.

Ibode yoo di titi pa:

Image copyright EMMANUEL OYELEKE

Igbesẹ akọkọ tawọn ijọba orilẹede ti ofin konile o gbele wa yoo ṣe ni titi ibode ori ilẹ, ori omi ati ti ofurufu pa.

O tumọ si pe wọn ko ni jẹ ki awọn eeyan lati awọn orilẹede mii papaajulọ lati awọn orilẹede ti arun covid-19 ba n finra wọ le.

Ṣugbọn wọn le gba ki ẹru maa wọle.

Ko si irin-ajo kaakiri orilẹede:

Image copyright Getty Images

Irin-ajo lati ibi kan si ibo miiran ko si nigba ti ofin konile o gbele ba wa lode lorilẹede kan.

Awọn ti iṣẹ wọn ba ṣe pataki nikan bi awọn oṣiṣẹ eto ilera lo le lanfaani ati maa rinrin ajo lasiko ofin konile o gbele.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus in Nigeria: Ẹ wo àǹfààní tó wà nínú àrùn Coronavirus

Ẹnikẹni ko gbọdọ jade

Mo n lọ ki ẹnikan ni ibikan ko si nigba ti ofin konile o gbele ba wa nita

Ijọ ko ni fi aye gba ki awọn eeyan maa lọ ki ara wọn.

O ko gbọdọ jade kuro nilu ile ayafi ti o ba fẹ lọ ra ounjẹ tabi o fẹ lọ si ile iwosan tabi ile ifowopamọ loku.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ

O gbọdọ ṣiṣẹ lati ile

Ijọba maa n sọ fawọn oṣiṣẹ ijọba ati ti adani pe ki wọn maa ṣiṣẹ lati ile wọn lasiko ti iṣede ba wa nilẹ.

Awọn eeyan ti iṣẹ wọn ba ṣe pataki bi awọn oṣiṣẹ eleto ilera, atawọn eeyan to n ṣiṣẹ nile ifowopamọ.

Image copyright Getty Images

Ile iwe di titi pa

Gbogbo ile iwe lo gbọdọ wa ni titi pa lasiko ti ijọba ba kede ofin konile o gbele nitori ki awọn akẹkọọ maa ba lugbadi arun coronavirus to wa nita.

Ijọba maa n rọ awọn ile iwe lati fi eto wọn ranṣẹ sawọn akẹkọọ lori ayelujara.

Image copyright Getty Images

Ko si ipejọpọ lawujọ mọ

Asiko owambẹ ti lọ! Ko si ayẹyẹ igbeyawo, isinku tabi apejọ kankan mọ lasiko konile o gbele.

Ṣọọṣi, mọṣalaaṣi ati gbogbo ile ijọsin ni yoo wa ni titi pa kaakiri orilẹede.

Gbogbo ẹ, gbogbo ẹ lati dẹkun itankalẹ arun naa ni.

Image copyright Getty Images

Adinku igboke-gbodo ọkọ

Ijọba maa n din igboke-gbodo ọkọ ku lasiko ti fin konile o gbele ba wa nita.

Amọ ijọba maa n faye gba kiko ọunjẹ kaakiri lasiko naa ki awọn eeyan le ri ohun ti wọn maa jẹ nigba ti wọn ba ninu ile.

Ṣugbọn wọn maa saa ba gbawọn eeyan naa ni imọran lati jina si ara wọn ti wọn ba n kẹru si ọkọ.

Ti nnkan meje yii ba n ṣẹlẹ lagbegbe rẹ, ki o tete mọ pe ijọba ti kede ofin konile o gbele niyẹn.