Coronavirus in Nigeria: Èèyàn mẹjọ míràn tún ti ní àrùn Coronavirus ní Naijira

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nibayii, o ti di eeyan mẹtadinlọgọrun un (97) to ti ni aarun naa lorilẹede Naijiria.

Eniyan mẹjọ miran tun ti ni aarun coronavirus ni orilẹ-ede Naijiria.

Ajọ to n risi idena ati amojuto ajakalẹ aarun ni, NCDC lo fi ikede naa sita lalẹ ọjọ Abamẹta loju opo Twitter rẹ.

Meji ninu awọn eeyan ọhun wa ni Abuja, mẹrin ni ipinlẹ Oyo, ẹnikan lati Kaduna ati ẹnikan mii lati ipinlẹ Osun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus in Nigeria: Ẹ wo bí ẹ ṣe lè ṣe "hand sanitizer" nínú ilé yín

Nibayii, o ti di eeyan mẹtadinlọgọrun un (97) to ti ni aarun naa lorilẹede Naijiria.

Coronavirus in Nigeria: Àfẹ́sọ́nà Davido, Chioma ti ní ààrùn coronavirus

Image copyright davido/instagram

Gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Davido ti sọ pe afẹsọna oun, Chioma ti ni aarun Coronavirus.

Davido lo fi ọrọ naa sita loju opo Instagram rẹ, nibi to ti ṣalaye pe bi oun ṣe de lati America laip yii, naa ni afẹsọba oun, Chioma de lati ilẹ Gẹẹsi pada si Naijiria.

O ni awọn mejeji ko ṣafihan apẹẹrẹ aarun naa, ṣugbọn wọn lọ fun ayẹwo gẹgẹ bi agbekalẹ ajọ to n dena ajakalẹ arun, NCDC, ti esi ayẹwo naa si fi han pe Chioma ti ni arun naa.

Davido ni ayẹwo ọmọ oun ati Chioma fi han pe ọmọ naa ko ni arun naa lara, ati pe Chioma ko ti ma ṣafihan apẹrẹ aarun ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun ti ya ara oun sọtọ fun ọjọ merinla bayii.

Lẹyin naa lo dupe lọwọawọn ololufẹ rẹ, to si parọwa fun wọn ki wọn duro sile wọn lasiko yii.

Ènìyàn méjì míràn ti ní coronavirus ní ìpínlẹ̀ Oyo, mẹ́ta l'Abuja

Image copyright Google

Eniyan maarun miran tun ti ni aarun coronavirus ni orilẹ-ede Naijiria.

Eniyan meji lo wa ni ipinlẹ Ọyọ lara wọn, mẹta si wa lati ilu Abuja.

Ajọ to n risi idena ati amojuto ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC lo fi ikede naa sita lalẹ ọjọ Ẹti loju opo Twitter rẹ.

Nibayii, o ti pe aadọrin eniyan (70) to ti ni aarun naa ni Naijiria.

Afikun nipa aarun Coronavirus

Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ṣetán láti tilẹ́kùn ibodè rẹ̀ nítorí Coronavirus

Gboyega Oyetole Image copyright @GboyegaOyetola

Ijọba ipinlẹ Osun ti kede igbeṣẹ lati tilẹkun ibode rẹ lọna ati dena itankalẹ arun Coronavirus nipinlẹ ọhun.

Akọwe ijọba, Wole Oyebamiji lo fi ọrọ naa lede nilu Osogbo pe igbeṣẹ naa yoo bẹrẹ lati ọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta ọdun 2020.

O ni gbogbo awọn ọja nla ati ọja igbalode ni yoo di titi pa, yatọ si awọn ibi ti wọn ti n ta ogun ati ounjẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNjẹ Chloroquine nipa kankan lati le koju Coronavirus

Oyebamiji tẹsiwaju pe ijọba ipinlẹ ọhun yoo ṣe adinku si iye awọn eeyan ti ọkọ akero le gbe nigbakan ṣoṣo lọna ati dẹkun itankalẹ arun ọhun.

O ni awọn ọlọkada ko ni lanfani ati ma gbe eeyan meji papọ mọ, bẹẹ ni awọn ọkọ korope ko ni ma gbe ju eeyan mẹrin lọ; ẹnikan niwaju, ẹnikan laarin ati meji pere lẹyin.

Oyebamiji wa rọ awọn to ṣẹṣẹ de lati Amẹrika, ilẹ Gẹẹsi atawọn orilẹede mii ti arun ọhunn ti ṣọṣẹ julọ si ipinlẹ Osun lati pe nọmba 293 fun alaye kikun lori bi wọn ṣe le dabo bo ara wọn ati awọn to sun mọ wọn.

Coronavirus updates : Covid-19 tún ti pọ̀ si l'Eko àti Abuja, ó di èèyàn 65 tó níi ní Nàìjíríà

Image copyright Getty Images

Ajọ to n gbogun ti itankalẹ aarun ni Naijiria, NCDC ti kede pe eniyan mẹrinla miran tun ti ni coronavirus ni Naijiria.

Eniyan mejila lara awọn ẹni tuntun yii lo wa ni ipinlẹ Eko, ti meji si wa ni ilu Abuja.

Ninu mẹrinla naa, wọn ri awọn mẹfa to ko ẹru wọle lati ori omi, mẹta miran jẹ arinrinajo. Ẹnikan to ku jẹ ẹni to ko o lati ara ẹnikan to ti kọkọ ni i.

Nibayii, eniyan marundinlaadọrin lo ti ni aarun naa ni Naijiria.

Coronavirus wọ ìpínlẹ̀ Rivers, èèyàn méjì míì tún ni l'Eko, ó di èèyàn 51 tó níi ní Nàìjíríà

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC ti kede pe iye eeyan to ti ni aarun Coronavirus nilẹ yi ti di mọkanlelaadọta bayii.

To n tumọ si pe aarun naa ti rapala wọ ipinlẹ mẹsan an lorilẹ-ede Naijiria.

Awọn eeyan to ni aarun naa nipinlẹ Eko ti di mejilelọgbọn, FCT jẹ mẹwaa, Ogun ni mẹta, eeyan kọọkan lo ni aarun ọhun ni ipinlẹ Ekiti, Oyo, Edo, Bauchi, Osun ati Rivers.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Fífi nkan bó ìmu nìkan kò le dènà kíkó coronavirus

Ni bayii, eeyan mọkanlelaadọta lo ti lugbadi arun covid-19 ni Naijiria ninu eyi ti ẹnikan ti di oloogbe, ti awọn meji si ti kuro nile iwosan lẹyin ti wọn ri iwosan.

Coronavirus in Nigeria: Covid-19 wọ ìpínlẹ̀ Osun, èèyàn míì tún tí ni l'Eko, ó di èèyàn 46 tó níi ní Nàìjíríà

Image copyright Pius Utomi Ekpei
Àkọlé àwòrán Ajọ NCDC ṣalaye pe awọn mejeeji ṣẹṣẹ rinrin ajo de lati ilẹ okeere si Naijiria ni bi ọjọ meje sẹyin ni.

Eeyan meji mii tun ti ni aarun coronavirus lorilẹ-ede Naijiria, ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC to kede ọrọ naa loju opo Twitter rẹ.

Ẹnikan ninu awọn to ṣẹṣẹ larun naa wa lati ipinlẹ Osun, nigba ti ẹnikeji wa lati ipinlẹ Eko.

Ajọ NCDC ṣalaye pe awọn mejeeji ṣẹṣẹ rinrin ajo de lati ilẹ okeere si Naijiria ni bi ọjọ meje sẹyin ni.

Nibayii, eeyan mẹrindinlaadọta lo ti lugbadi arun covid-19 ni Naijiria ninu eyi ti ẹnikan ti di oloogbe ti awọn meji si ti kuro nile iwosan lẹyin ti wọn gbadun tan.

Ọgbọn eeyan ninu awọn mẹrindinlaadọta to ni arun covid-19 ni Naijiria lo wa lati ipinlẹ Eko, nigba ti meji wa lati Abuja.

Ipinlẹ Ogun lo ṣe ipo kẹta pẹlu eeyan mẹta to ni arun naa, eeyan kọọkan lo ni arun ọhun lati ipinlẹ Ekiti ati Oyo.

Ipinlẹ Edo, Bauchi ati Osun naa ni eeyan kọọkan to ni arun coronavirus bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Gbogbo igbá ti ṣófo láwọn ilé ìtajà káàkiri London