Coronavirus: Odaran tíì kí bá ṣé ọmọ orílẹ̀èdè Ethiopia yóò padà sí ìlú abinibi rẹ

Image copyright Getty Images

Ẹgbẹrun mẹrin awọn to wa lọgba ẹwọn lorileede Ethiopia ni ijọba ilẹ naa ti ni oun yoo tusilẹ nitori ajakalẹ aarun Coronavirus.

Gẹgẹ bi wọn ti ṣe sọ, wn ni igbesẹ yi yoo jẹ ọna kan gbogi lati dẹkun ajakalẹ aarun naa.

Agbẹjọro agba orileede naa ṣalaye pe awọn ọdaran ti wọn n ṣẹwọn lori ẹsun pẹẹpẹẹpẹ ati awọn obinrin wọn ni ọmọ lọwọ yoo wa lara awọn ti yoo gba itusilẹ.

Awọn ọmọ orileede mìíràn tí wọn mú fún ẹsun ṣiṣe owó ẹrú àti àwọn tí wọn ń ṣe fayawo náà wá lára àwọn tí wọn yóò gbà itusile ti wọn yóò sì dá olúkúlùkù padà sí ìlú abinibi wọn.

Lára àwọn tí yóò tún gba itusile ni àkòroyín kan Fakadu Mahtemework.

Oga agba oniroyin náà padà sí Ethiopia leyin ti asoju ijoba Ahmed Abiy gorí alefa lodun 2018 lásìkò tí wọn tú òpó àwọn tí wọn mu nítorí oselu silẹ.

Aworan awọn ẹlẹwọn lọgba ẹwọn Image copyright Getty Images

Ṣùgbọ́n wọn ní pe o jẹ owo ori, ejò yìí ni wón ṣe leyin rẹ tí wọn sì ju sì ẹwọn ọdún méje ni inu osu Kẹ̀wá ọdún tó kọjá.

Ilana miran ti ijoba Ethiopia tún gunle ni lati ṣètò àwọn ilé ìtura kan fún àwọn arìnrìn-àjò tí wọn sì ti kan ń pá fún àwọn osise láti maa ṣiṣẹ láti ilé wọn àti pé gbogbo ẹnu ibodè tó wọ orileede náà ni kò wá ní titi pa.

Àwọn ọmọ orileede Ethiopia tí kò bá lè san owó náà, ijoba ni àwọn yóò sanwó wọn.

Ó lè ní irínwó àwọn arìnrìn-àjò lọ sí Ethiopia to tí bẹ̀rẹ̀ igbele túláàsì gẹ́gẹ́ bi atejade tí minisita fún ìlera Ethiopia fi síta.

Ènìyàn méjìlá lọ tí ni aarun Coronavirus ni Ethiopia

Afikun nipa aarun Coronavirus
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Gbogbo igbá ti ṣófo láwọn ilé ìtajà káàkiri London

Uganda fofin de ọkada wiwọ laarin ọjọ mẹrinla

Aarẹ orileede Uganda,Yoweri Museveni tí fi ofin de ìgbòkègbodò ọkọ jákèjádò orile náà fún òjò mẹ́rìnlá láti dekun ìtànkalẹ aarun Coronavirus.

Amohunmaworan orileede náà ni Aare tí soro ni Ọjoru, èyí tó sì ni yóò bẹ̀rẹ̀ loni waransesa.

Ni Uganda, Boda-boda ni orukọ ti wọn n pe alupupu akero ọkada.

Aworan awọn eeyan to joko si ori alupupu ni Uganda Image copyright Getty Images

Kò tán síbẹ̀, ọkọ aladani ni orileede Uganda kò gbogbo kò ju èrò mẹta lọ tó fi mọ awako.

Ènìyàn merinla péré ni àwọn aláṣẹ Uganda ṣẹṣẹ fi idi rẹ mulẹ pé wọn ní aarun náà tó fi mọ ọmọdébìnrin oṣù mejo kan.

Iroyin tún sọ pé àwọn ọmọ orileede Uganda miran ti ko tilè rìn ìrìn-àjò kúrò ní Uganda farakasa aisan naa.

Ẹwẹ àwọn ọja tó máa ń kún fòfò náà yóò kogbasile afi àwọn èyí tí wọn tí ń tà oúnjẹ jíjẹ

Ní ose tó kọjá ní aare ni kí wọn tí gbogbo ilé ìwé, ilé ọtí, àti àwọn ibi igbafe, gbogbo ilé ìworán àti pé ipejopo kò gbọ́dọ̀ ju ènìyàn méjìlélọ́gbọ̀n lọ.

Afikun nipa aarun Coronavirus

Èèèyàn márùn ún péré ló leè lọ ayẹyẹ ìgbéyàwó ní Australia báyìí nítorí Coronavirus

Ijọba orilẹ-ede Australia ti sọ pe oun ko faaye gba ju eeyan marun un pere ti yoo wa nibi ayẹyẹ igbeyawo ati mẹwaa nibi isinku lọna ati dẹkun itankalẹ aarun Coronavirus.

Adari ijọba Scott Morrison lo kede igbeṣẹ yi lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn minisita orilẹ-ede ọhun.

Australia Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Èèèyàn mẹ́wàá péré ló leè lọ ayẹyẹ ìsinìkú ní Australia báyìí nítorí àrùn Coronavirus

O ni ijọba ilẹ naa yoo wọgile ọpọ lara irin ajo okeere ati pe awọn ibi igbafẹ ita gbangba ni yoo di titi pa.

Ofin tuntun yi ni ijọba Australia sọ pe yoo bẹrẹ lati ago kan ọsan, ọjọ karundinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2020 lẹyin ti iye awọn eeyan to ni aarun Coronavirus n peleke sii.

O kere tan, eeyan to fara kaasa aarun naa le ni irinwo laarin wakati mẹrinlelogun, leyi to ti mu ki iye awọn to n ba arun ọhun finra naa le ni ẹgbẹrun meji bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Gbogbo igbá ti ṣófo láwọn ilé ìtajà káàkiri London

Ni bayii, ijọba ilẹ naa ti gbe agadagodo sẹnu ọna awọn ile ijọsin ati ile ọti, ṣugbọn ko tii gbeṣẹle ile iwe gẹgẹ binawọn orilẹ-ede miran.

Afurasí Boko Haram pa ogójì ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà ní Borno:

boko haram Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Afurasí Boko Haram pa ogójì ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà ní Borno

Awọn alakatakiti ẹsin Islam, boko Haram ni wọn fura si pe wọn ti ṣeku pa ọmọ ogun ilẹ̀ Naijiria to le ni ogoji nipinlẹ Borno.

Awọn agbesunmọmi yii kọlu ọkọ ọmọ ogun ilẹ̀ Naijiria lasiko ti wọn n wọ aarin igbo Sambisa ni ariwa iwọ oorun Naijiria.

Iroyin ti a kọkọ gbọ sọ pe o le ni aadọrin eniyan lo ku si iṣẹlẹ naa tẹlẹ.

Ogagun Abdulssalam Sani tó jẹ́ alukoro fun ileeṣẹ ọmọ ogun lori iṣẹ akanṣe ṣalaye pe awọn naa pada kọlu awọn oniṣẹ ibi naa.

Iroyin ni awọn miran ninu awọn ọmọ ogun ṣi wa ni ile iwosan fun itọju bayii.

Titi di asiko yii, ko sẹni to tii le sọ nipato boya awọn oniṣẹibi alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram lo ṣiṣẹ naa tabi bẹẹkọ, ṣugbọn awọn ni wọn fura si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Ogagun Abdulssalam Sani ṣalaye fun BBC pe awọn ọmọ ogun ofurufu tete dide iranwọ lasiko ikọlu yii ni kete ti wọn ri ipe pajawiri awọn ọmọ ogun ilẹ̀ Naijria gba.

Bakan naa ni Ogagun Sani sọ fun BBC pe awọn ọmọ ogun ofurufu lo pada gbẹsan lara awọn oniṣẹ ibi naa ninu igbo Sambisa nipinlẹ Borno.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn fíìmì òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú

'Ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìnmí, àmọ́ èmi nìkan kọ́ ló ṣẹ̀,' Ajimobi bẹ ọmọ ẹgbẹ́ APC l'Oyo

Oyo APC Crisis: Gómìnà Oyo tẹ́lẹ̀, Ajimobi tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC l'Oyo

Abiola Ajimobi ni ''a kii mọọ rin, k'ori o ma mi,'' o ni oun gba pe oun ṣe awọn aṣiṣe kan ṣugbọn oun tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ.

Abiola Ajimobi Image copyright Instagram/abiolaajimobi

Ẹ dari aṣiṣe mi ji mi, amọ emi nikan kọ ni mo ṣe aṣisẹ, awọn miiran naa ṣe aṣiṣe bi temi, gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Sẹnẹtọ Abiola Ajimobi lo sọrọ yii nibi ipade igbimọ to n pẹtu si aawọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Ajimobi to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ APC lapa gusu orilẹede Naijiria lo ṣe agbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹrindinlogun naa ti gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Adebayo Alao Akala jẹ alaga rẹ.

Nigba to n sọrọ nibi ipade naa, Ajimobi ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo kopa ribiribi ninu aṣeyọri ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo lọdun 2011 ati 2015.

Ṣugbọn Ajimobi ni bakan naa ni gbogbo ọmọ tun kopa ninu ijakulẹ ẹgbẹ APC ninu idibo gbogbogbo ọdun 2019 lọna kan, tabi omiiran.

Ajimobi ni ''a kii mọọ rin, k'ori ma mi,'' o ni oun gba pe oun ṣe awọn aṣiṣe kan ṣugbọn oun tọtọ aforiji lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ.

Amọ, o ni loun ti gba ẹbẹ awọn ọmọ mii tawọn naa ti ṣe aṣiṣe kan tabi omiiran.

Image copyright Instagram/abiolaajimobi

Ajimọbi rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo lati dariji ara wọn nitori akoko niyii lati ṣe atunṣe ẹgbẹ naa ṣaaju ipenija to le wa lọjọ iwaju.

O ni asiko ti to fun gbogbo ọmọm ẹgbẹ APC lati fi iwa imọtara ẹni nikan silẹ, ki wọn si maa lepa ilọsiwaju ẹgbẹ naa.

Awọn inu ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo bi Ọjọgbọn Prof Dibu Ojerinde, Sẹnẹtọ Teslim Folarin, Họnọrebu Segun Odebunmi, Pa Akin Ojebode, Alhaji Laide Abass, Pa Adeleke atawọn mii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus in Nigeria: Ẹ wo àǹfààní tó wà nínú àrùn Coronavirus