Chloroquine for coronavirus: Njẹ Chloroquine nipa kankan láti kojú Coronavirus?

Chloroquine for coronavirus: Njẹ Chloroquine nipa kankan láti kojú Coronavirus?

Lori alaye awn nkan to yẹ ki o mọ nipa aarun coronavirus fun tonii, a ṣe agbeyẹwo lilo oogun Chloroquine fun itọju aarun naa.

Lati ọjọ pipẹ, oogun to n gbogun ti aisan iba ni Chloroquine jẹ, botilẹjẹ pe awọn orilẹ-ede kan ti fi ofin de lilo rẹ.

Ṣugbọn lati igba ti Aarẹ ilẹ America, Donald Trump ti sọ pe Chloroquine le gbogun ti aarun tuntun yii, ni ọpọ eniyan ti n lo oogun naa lọna aitọ.

Awọn onimọ iṣegun oyinbo si ti sọ pe wọn ko ti i fidirẹmulẹ pe Chloroquine le dena tabi wo aarun coronavirus.

Nitori naa, ilokulo oogun Chloroquine le ṣakoba fun ọ, koda, o le ṣeku pa ọ.