BuhariAddressNigerians:Ààrẹ f'òfin de irina ni Eko,Ogun ati Abuja fọjọ́ mẹ́rìnlá gbako

Aworan aarẹ Buhari Image copyright NTA

Aarẹ orileede Naijiria,Muhammadu Buhari ti kede pe ko ni si wiwọle tabi jijade ọkọ laarin ipinlẹ Eko,Ogun ati Abuja fun ọjọ mẹrinla gbako.

Iṣede yi to paṣẹ rẹ yoo bẹrẹ laago mọkanla lọjọ Aje ti ṣe ọgbọn ọjọ oṣu Kẹta.

Ninu ọrọ to ba awọn ọmọ Naijiria sọ lori ajakalẹ arun Corona Virus lo ti fi aṣẹ yi lelẹ gẹgẹ bi ọna ati dẹkun itankalẹ Coronavirus ni Naijiria

Awọn igbesẹ mi to kede

Aarẹ ni gbogbo awọn eeyan agbegbe ti iṣele yi kan ni ki wọn ma se jade rara.

Gbogbo karakata ati ileeṣẹ pata ni yoo wa ni titi pa.

O fi kun pe ọrọ yi ko ni kan awọn oniṣẹ ilera ati awọn ti o n pese irinṣẹ ilera.

Amọ akọroyin kankan ti yoo ba jade sita ni lati fi ẹri han pe oun ko le ṣe iṣẹ lati ile afi ni ọfisi rẹ.

Image copyright BashirAhmaad

Ohun to ti ṣẹlẹ ṣaaju

Femi Adeshina to jẹ oluranlọwọ agba aarẹ Buhari ni o fi ọrọ yi sita loju opo Facebook rẹ pe aarẹ yoo ba awọn eeyan Naijiria sọrọ lalẹ ọjọ Aiku.

Ni ọsan ọjọ Abamẹta ni Minisista feto ilera ati ọga agba ajọ ileesẹ to n gbogun ti arun NCDC ṣabẹwo si aarẹ nile ijọba.Lẹyin ipade naa,

Minisita ilera Osagie Ehanire ni awọn wa fi to aarẹ leti iru ipenija to wa niwaju pẹlu arun Coronavirus ati ọna lati le fi koju rẹ.

O ti to ọjọ mẹta ti awọn ọmọ Naijiria ti n reti ki aarẹ Muhammadu Buhari ba wọn sọrọ paapa julọ lori ajakalẹ Coronavirus.

Lori ẹrọ amounmworan orileede Naijiria ni Adeshina ni aarẹ yoo ti ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ laago meje alẹ.

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ tó ń rísí wọléwọ̀de Naijiria, Muhammed Babandede ti lùgbàdì àrùn Coronavirus

Ninu iroyin miran,Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ijọba to n risi wọlewọde lorilẹde yii, NIS, Muhammed Babandede ti fara kaasa arun Coronavirus.

Ṣaaju ni Babandede ti kọ ya ara rẹ sọtọ fun ayẹwo lẹyin to tirin ajo de lati ilẹ Gẹẹsi lọjọ kejilellogun oṣu yii.

Image copyright @chimbiko_jerome

O ni oun ti wa ni apapmọ bayii fun itọju to peye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus in Nigeria: Ẹ wo bí ẹ ṣe lè ṣe "hand sanitizer" nínú ilé yín

Lẹyin naa lo wa rọ awọn ọmọ Naijria ati awọn alabaṣiṣẹ rẹ ati ranti oun ati awọn ọmọ Naijiria mii to ni arun ọhun ninu adura wọn.

Coronavirus Update: Mínísítà ìlera tí jẹ́ abọ fún Ààrẹ Buhari lórí àrùn Coronavirus

Image copyright NGRPresident

Aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari ti foju han ni igba akọkọ lati igba ti awuyewuye lori ibi to sa pamọ si ti bẹrẹ loju opo ayelujara ni Naijiria pẹlu hashtag #BuhariResign.

Aarẹ Buhari gbalejo Minisita feto ilera ati ọga agba ajọ to n koju aisan ni Naijiria,NCDC nile ijọba lọsan ọjọ Abamẹta.

Ninu awọn fọnran fidio ati aworan ti ileeṣẹ aarẹ Naijiria fi sita, a ri ti aarẹ Buhari joko jina si Minisita Osagie Ehanire ati Dokita Chikwe Ihekweazu.

Image copyright NGRPresident

Gẹgẹ bi akọle awọn aworan naa ti ṣe ṣalaye, ileeṣẹ aarẹ ni awọn mejeeji wa jabọ fun aarẹ bi nnkan ti ṣe n lọ pẹlu kikoju ajakalẹ Coronavirus.

Lẹnu ọjọ mẹta yi ti iroyin ti lu sita pe olori awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari naa ti ni arun Coronavirus ni awọn eeyan ti ni awọn ko ko firi aarẹ Muhammadu Buhari mọ.

Loju opo Twitter, awọn eeyan n beere pe nibo ni aarẹ wa tawọn kan si ni o ti lọ gba itọju lẹyin odi.

Kete ti fọnran fidio ati aworan aarẹ jade loju opo Twitter lawọn ọmọ Naijiria ti n sọ ero ọkan wọn.

Awọ ọmọ Naijiria kan ko tilẹ gbagbọ pe aarẹ gangan lo wa ninu fọnran fidio naa ti wọn si ni afi dandan nki o ba awọn eeyan Naijiria sọrọ loju koroju

Àwọn mínísítà 43 fi ìdá 50% owó osù wọn fún ìdẹ́kun Coronavirus ní Náíjíríà

Awọn minisita lorilẹede Naijria ti sẹlẹri lati fi ida aadọta lara owo osu kẹta wọn ṣe iranwọ fun ijọba Naijria lati koju arun Coronavirus.

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Bashir Ahmad lo fi lede loju opo Twitter rẹ ni Ọjọ Satide pe inu atẹjade ti minisita fun ọrọ iroyin, Alhaji Lai Muhammed fi lede ni iroyin naa wa.

Ahmad ni awọn minisita mẹtalelọgọrin lorilẹede Naijria lo ṣetan lati gbe igbeṣẹ ti yio mu atunse ba gbigboju ti ajakalẹ arun naa to n ja nilẹ rain.

Iroyin sọ wi pe awọn minista naa gbe igbesẹ naa lati ṣe moriya fun igbesẹ ijọba lati koju arun naa.

Bakan naa ni awọn minisita naa gboriyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati gbogun ti arun naa.

Ẹ wo àwọn olówó tí wọ́n ti ṣe ìrànwọ́ fún Naijiria láti kojú àrùn Coronavirus

Ọjọbo, ọsẹ yii ni orilẹede Naijiria gba awọn ohun elo ayẹwo ti gbajugbaja oniṣowo ọmọ China, Jack Ma, to jẹ oludasilẹ ile itaja ayelujara ti a mọ si Alibaba fi ṣe iranwọ fun awọn orilẹede ni ilẹ Afrika lati fi gbogun ti itankalẹ arun Coronavirus ni agbaye.

Ọga agba kan lori ọrọ eto ilera ni Naijiria, Abdulaziz Abdullahi sọ wi pe Jack ma fun Naijiria ni ẹgberun lọna ọgọrun ibomu, ibọwọ ati awọn asọ to le dena arun Coronavirus to to ẹgbẹrun kan, ati ẹrọ ayẹwo to le ni ẹgbẹrun lọna ọgun.

Awọn olowo miran lorilẹede Naijiria naa ti n fi owo ati ohun elo se iranwo fun orilẹede Naijiria lati fi koju arun yii.

Ẹ wo àwọn olówó tí wọ́n ti ṣe ìrànwọ́ fún Naijiria láti kojú àrùn Coronavirus:

Atiku Abubakar

Image copyright Google

Igbakeji aarẹ lorilẹede Naijiria tẹlẹri, Atiku Abubaka fi aadọta miliọnu Naira, N50million, se iranwọ fun orilẹede Naijiria lati kapa arun Coronavirus lorilẹede Naijiria.

Atiku ni oun gbagbọ pe owo iranwọ naa yoo fun awọn oṣiṣẹ eto ilera laaye lati dẹkun itankalẹ arun naa ni Naijiria.

Aliko Dangote

Image copyright Google

Gbajugbaja onisowo lorilẹede Naijiria ati ni ilẹ Afrika, Aliko Dangote ti fi igba miliọnu naira, N200million ṣe iranwọ fun ijọba orilẹede Naijiria lọna ati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus ni Naijiria.

Dangote ni ẹni to lowo julọ nilẹ adulawọ.

Tony Elumelu

Image copyright Google

Alaga ile ifowopamọ United Bank of Africa, UBA ti fi owo to le ni biliọnu marun un naira, N5billion, ṣe iranwọ fun ijọba Naijiria ati orilẹede mẹtadinlogun ni ilẹ Afrika ki wọn le fi gbogun ti itankalẹ arun naa.

Elumelu ni owo naa yoo ṣe iranwọ fun ilẹ Afrika lati pese ohun elo iranwọ, eto iwosan pajawiri ati owo iranwo fun ijọba.

Bakan naa, o ni wọn yoo pese ileewosan ti yoo ma a se ayẹwo fun awọn eniyan ni ipinlẹ ti arun naa ti de si niNaijiria.

GT Bank

Image copyright Google

Adari ile ifowopamọ GT, Segun Agbaje ti fi ile iwosan to ni ọgba ibusun ọgọrun un fun ipinlẹ Eko, gẹgẹ bii iranwọ fun ijọba nipa igbogun ti arun Coronavirus.

Agbaje sọ wi pe awọn yoo ri wi pe ile iwosan naa ni ohun elo iwosan ti wọn nilo to fi mọ ẹrọ ti n ṣe iranwọ fun ati mi ‘respirators’ fun awọn to n gba itọju fun arun Coronavirus.

Abdul-Samad Rabiu

Image copyright Google

Abdul-Samad Rabiu to jẹ adari ileesẹ BUA Group ti ṣe iranwọ fun orilẹede Naijiria pẹlu biliọnu kan naira, N1billion, lati gbogun ti arun Coronavirus.

O fikun wi pe oniṣowo naa ti bere fun iranwọ awọn ohun elo miran ati ohun elo ilera fun awọn oṣiṣẹ eleto ilera lati le ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ lasiko igbogunti arun Coronavirus yii.

Nàìjíríà kò mọ̀ pé ààrùn Coronavirus lè rí báyìí - Mínísítà ètò ìlèra

Minisita fun eto ilera, Osagie Ehanire ti ni Naijiria ko mọ pe Coronavirus yoo ri bi o ṣe ri yii nitori wọn ko ṣe igbaradi to peye fun un.

Ehanire ni arun naa ṣe ajoji si gbogbo eniyan to fi mọ awọn orilẹede to ni eto iwosan to peye naa, nitori naa lo ṣe n ja rainrain ni gbogbo agbaye.

Image copyright TWITTER/@FMOHNIGERIA

O ni orilẹede Naijiria ati gbogbo agbaye to ku ti kọ ẹkọ to peye lati ara arun Coronavirus, ti wọn n pe ni Covid-19.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKi lo fa Ija lọbalọba ni ilu Iwo

Minisita naa ni to ba ṣe pe wọn gbaradi fun un, wọn ko ni ni iye awọn eniyan to ti ku latari aisan naa.

Bakan naa lo fikun wi pe lootọ ni ọkan gboogi ni ijọba aarẹ Buhari wa n gba itọju lẹyin ti ayẹwo fihan pe o ni arun Coronavirus.

Minisita fun eto ilera, Osagie Ehanire naa wa ni awọn ṣi n wa awọn ti wọn ti ṣe ipade pẹlu awọn ti o ti ni arun naa.