Coronavirus: Njẹ́ jíjẹ́ aláwọ̀ dúdú le gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ààrùn Coronavirus?

Coronavirus: Njẹ́ jíjẹ́ aláwọ̀ dúdú le gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ààrùn Coronavirus?

O ṣeeṣe ki iwọ naa ti ri tabi gbọ nipa iroyin kan pe jijẹ alawọ dudu le daabo bo ọ lọwọ coronavirus.

Awọn to gbe iroyin tiẹ sọ pe ọmọ orilẹ-ede Cameroon kan to n gbe ni China ri iwosan nitori pe o jẹ alawọ dudu.

Irọ nla leyi, nitori pe ko ti i si ẹri ijinlẹ pe awọn alawọ dudu ni anfaani lati bori coronavirus ju awọn ẹya miran lọ.

Bakan naa lo ṣe pataki lati mọ pe aarun naa yara pa awọn to ba ti dagba diẹ tabi ni aarun kan ti wọn n tọju lara tẹlẹ.

O si tun ṣe pataki fun ọ lati maa nu foonu rẹ pẹlu lati dena aarun naa.