Coronavirus Updates: UCH ní èròjà Covid-19 tíjọba fún òun kò tó ₦1m

owo Naira

Oríṣun àwòrán, Others

O ti to ọjọ mẹta bayii ti awuyewuye ti n lọ laarin ijọba ipinlẹ Oyo ati ile iwosan UCH lori ibi ti miliọnu mejidinlọgọfa naira wa.

Ijọba ipinlẹ Oyo lo kede pe biliọnu meji ati miliọnu lsna ẹẹdẹgbẹẹta naira ni oun na fun itọju arun Coronavirus.

Bakan naa lo fikun pe miliọnu lọna mejidinlọgọfa naira ni oun na fun ile iwosan UCH ninu owo yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ile iwosan naa ti figbe bọnu pe irọ to jinna sootọ ni ikede ijọba yii nitori oun ko gba owo naa lọwọ ijọba.

Idi ree ti BBC Yoruba fi n tanna wadi ibi ti owo yii wọlẹ si, abi ejo miran tun ti mi owo ijọba ipinlẹ Oyo ni?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, osisẹ alarina fun ile iwosan UCH, Toye Akinrinola salaye pe eroja ti ko ju miliọnu kan naira ni UCH gba lọwọ ijsba ipinlẹ Oyo.

Oríṣun àwòrán, Facebook/UCH

UCH si wa lori ẹsẹ rẹ pe, ohun ko gba iranwọ owo kankan lati ọdọ ipinlẹ Oyo fun itọju awọn to ni aarun Coronavirus.

Amọ akọwe iroyin fun Gomina Seyi Makinde, Ọgbẹni Taiwo Adisa lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe, ijọba ṣeranwọ fun UCH pẹlu awọn irinṣẹ atawọn eroja itọju awọn alaarun Covid-19.

Ọgbẹni Adisa ni ijọba ipinlẹ Oyo ti ṣi owo to fi ra gbogbo eroja atawọn irinṣẹ naa, o si jẹ miliọnu mejilelọgbọn

Adisa ni ijọba tun ra eroja ati irinṣẹ to to miliọnu mẹrindinlaadọrun un(N86m) fun ẹka ẹkọṣẹ nipa awọn kokoro aifojuri (Department of Virologyy).

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde Facebook

Ṣugbọn agbẹnusọ fun ile iwosan UCH, Toye Akinrinola sọ fun BBC Yoruba pe, iranwọ aṣọ idaabobo lọwọ arun, (PPE) bii ọtalerugba o din mẹwaa(250) nikan UCH gba lọwọ ijọba.

Amọ Akinrinola ṣalaye pe, gbogbo aṣọ PPE naa ko to miliọnu kan naira lọja.

Agbẹnusọ ile iwosan UCH wa ke pe ijọba lati ṣalaye ohun ti o fi miliọnu mejilelọgbọn ra gan an fun UCH.

Àkọlé fídíò,

Kid boxer: Ọmọọba 'The Buzz' Larbie rèé, ọmọ ọdún méje tó ń fi ẹ̀ṣẹ́ dá bírà

Ọgbẹni Akinrinola fikun ọrọ rẹ pe, gbogbo awọn ileeṣẹ ati eeyan ti wọn ṣeranwọ kan ta bi omiiran fun ile iwosan UCH, ni ile iwosan naa maa n fi lede lori ayelujara.

Kò sí ibùdó ayẹwo àrùn Coronavirus ní UCH, ẹ má wá fún ayẹwo lọ́dọ̀ wa - Ọga àgbà UCH

Ọ̀ga àgbà fún ilé iwosan UCH, Ọjọgbọn Jesse Abiodun Otegbayo lọ sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń gbalejo kọmisana feto ìlera nipinlẹ Ọ̀yọ́, Dókítà Bashir Bello nílé ìwòsàn náà.

Atẹjade kan tí ilé ìwòsàn UCH wá fi síta lẹ́yìn abẹwo naa ni lóòótọ́ nile ìwòsàn náà ń tọju afurasi alárùn Covid-19 kan lọ́wọ́ àmọ́ wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ayẹwo rẹ ransẹ sì ikọ ìjọba tó ń ṣe ayẹwo àrùn Coronavirus ni.

Atẹjade náà fikùn pé, ilé ìwòsàn UCH sì ń dúró de èsì ayẹwo náà láti ibùdó ayẹwo níta, táwọn yóò si maa fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó aráyé létí bo ba ṣe ń lọ.

Coronavirus ti mú kí Rábí elépo pupa ó lówó ju Rábí elépo rọ̀bì lọ́

Ni bi a ṣe n to iroyin yii jọ, agbẹ olowo epo pupa labule kabule lorilẹede Naijiria ma ti di olowo ju baba olowo oniṣowo epo rọbi nibikibi lagbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ara awọn ohun manigbagbe ti ajakalẹ arun Coronavirus lagbaye mu ba aye ree.

Ni ilẹ to mọ loni yii ẹya epo rọbi Brent ti di dọla mọkanlelogun, iyẹn ẹgbẹrun mẹjọ o le bi igba naira lori agba epo rọbi kan nigba ti ẹda epo rọbi WTI ti di dọla mẹrindinlogun iyẹn ẹgbẹrun mẹfa o le ojilelugba ati naira marun lori agba kan.

Amọṣa lori epo pupa, ọtalelẹgbẹta o din mẹta dọla, iyẹn ẹgbẹrun lọna igba o le mẹtadinlogun naira. Eyi tumọ si pe, ẹni to n ṣowo epo pupa lọwọ yii n pawo wọle.

O ti to igba diẹ bayii ti owo epo lagbaye ti n kuta nitori ajakalẹ arun coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Owo epo ilẹ Amẹrika ti dẹnukọlẹ fun igba akọkọ ninu itan.

Eyi tumọ si peawọn to n ta epo gan lo n sanwo fawo orilẹede to n ra epo lati wa ko epo rọbi naa kuro lori igba wọn.

Idi eyi ko ju ibẹrubojo pe oṣeeṣe ko maa si aye lati ko epo rọbi pams si mọ nigba to oṣu karun ọdun yii ba fi wọle.

Ko si awọn to n beere lati ra epo rọbi lagbaye bayii nitori aṣẹ konileogbele kaakiri agbaye eleyi to ti ti ọpọlọpọ awọn eeyan mọle jakejado agbaye.

Nitori eyi, nṣe lawọn ileeṣẹ apọnpo gbogbo bẹrẹ si ni ya agba ikeposi kaakiri lati ko awọn apọju epo naa si, eyi lo si fa bi owo epo rọbi ilẹ Gẹẹsi ṣe dẹnukọlẹ.

Owo ori ẹya epo rọbi West Texas Intermediate (WTI) to jẹ odinwọn owo epo lorilẹede Amẹrika ti ja lọlẹ si dọla mẹtadinlogoji lori jala kan.