Coronavirus: Ọjoọ́ mélòó ni Coronavirus ń lò lára kí ènìyàn tó gba ìwòsàn?

Osiṣẹ eto ilero duro ti alaisan kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arun Coronavirus bẹrẹ ni ipari ọdun 2019, amọ o le e ṣe diẹ ki awọn eniyan to ba ni arun naa to ri iwosan gba.

Gbigba iwosan niiṣe pẹlu bi eniyan ba ṣe ṣe aisan si nitori arun Coronavirus le ma lagbara lori awọn eniyan kan, amọ ko si ṣọṣẹ lara awọn eniyan miran.

Awọn ohun to niiṣe pẹlu bi eniyan ba tete ri iwosan gba si ni ọjọ ori, ọkunrin tabi obinrin ati boya ẹni naa ni aisan abẹnu tẹlẹ.

Ti eniyan ba tete lọ si ile iwosan, ki o bẹrẹ iwosan naa niiṣe pẹlu bi eniyan yoo ṣe gba iwosan si.

Ti apẹẹrẹ arun Coronavirus ko ba buru ju nkọ?

Ọpọlọpọ awọn eniyan to ba ni arun Coronavirus ko ni awọn apẹẹrẹ to koja agbara ju. Wọn le e wukọ tabi ni iba, ara riro, ọfun dundun ati ori fifọ.

Ikọ wiwu naa le ma le lakọkọ, amọ to baya, wọn yoo ba wukọ ti yoo ma tu nkan jade.

Ọna ati gbogun ti arun naa ni ki eniyan sun daadaa, ki eniyan mu omi daadaa ati lilo oogun ara riro tabi ori fifọ bii paracetamol.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ti apẹẹrẹ wọn ko ba le ju yoo tete ri iwosan gba laarin ọsẹ meji.

Ti apẹẹrẹ ami arun Coronavirus ba le ju nkọ?

Arun yoo le peleke si fun awọn miran, eleyii to le jẹ bi ọjọ mẹwa lẹyin ti wọn ba ti ni arun naa lara.

Ayipada naa le tete ṣẹlẹ, eemi le di iṣoro, ki ọna ọfun sibẹrẹ si ni dun eniyan.

Ohun to ṣẹlẹ ni wi pe awọn eroja ara n tiraka lati gbogun ti arun Coronavirus naa, eleyii le fa ki awọn eroja ara bẹrẹ si ni ṣiṣẹ aṣeju, eleyii to ba ago ara jẹ.

Awọn miran le nilo itọju ni ileewosan pajawiri ti wọn ko ba le mi dada.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwosan fun awọn ti wọn ba ti bẹrẹ si ni lo ẹrọ ventilator lati mi le lo to osu mejila si osu mejidinlogun ni ileewosan, ki ara to bẹrẹ si ni pada si ipo notori ọpọlọpọ eroja ara lo ti sọnu lasiko ti ara n ba arun Coronavirus naa ja.

Ajọ Isokan Agbaye ni ẹnikan ninu ogun eniyan to ba ni arun Coronavirus lo ma n nilo itọju pajawiri, eleyii le jẹ ki wọn kun ẹni naa loorun ni ileewosan tabi ki wọn bẹrẹ si ni lo ẹrọ ventilator lati mi fun ara wọn.