Coronavirus Lockdown: Iléèwé Chrisland ṣetán láti fún ìgbẹ̀kọ́ orí ayélujára lọ́jọ́ Ajé tó ń bọ̀

Ileewe Chrisland

Oríṣun àwòrán, Other

Ko si ṣiṣe, ko si aisẹ, ile iwe Chrisland niluu Eko yoo wọle saa eto ẹkọ tuntun lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ti a wa yii, bo tilẹ jẹ wi pe ofin konile-o-gbele si wa lode.

Ohun ti awọn alaṣẹ ileewe naa n gbereo lati ṣe ni pe lori ayelujara ni awọn akẹkọọ ile iwe naa yoo ti maa gbẹkọọ.

Amọ ọpọ ninu awọn obin awọn ọmọ ile iwe naa lo tako igbesẹ awọn alaṣẹ ileewe naa.

Ohun to ya ọpọ eeyan lẹnu ni wi pe awọn obi ni lati sanwo ile iwe awọn ọmọ wọn fun saa eto ẹkọ tuntun to maa bẹrẹ lọjọ Aje to n bọ.

Bakan naa ni iroyin sọ pe awọn akẹkọọ tawọn obi wọn ko tii sanwo ileewe wọn ko ni lanfaani lati kopa ninu igbẹkọ naa lori ayeluajra.

Ṣugbọn nigba ti o ba BBC Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Jide Onigbogi to jẹ oludari idasoke okowo ileewe Chrisland ṣalaye pe ọpọ ninu awọn obi awọn akẹkọọ ileewe naa lo fọwọ sii pe ki saa igbẹkọọ tuntun bẹrẹ lori ayelujara.

Ọgbẹni Onigbogi sọ pe diẹ lara awọn obi awọn akẹkọọ ileewe naa lo tako ki ileewe Chrisland wọle saa eto ẹkọ tuntun bayii.

O ni awọn alaṣẹ ileewe naa ti pinnu lati ṣe adinku owo ileewe lasiko yii nitori ai lanfaani lati maa kẹkọọ ninu yara ikawe nitori konile-o-gbele to wa nita nitori coronavirus.

Ọgbẹni Onigbogi fikun ọrọ rẹ pe awọn ti ko tii sanwo ileewe fun saa keji igbẹkọ to lọ nikan ni ko ni lanfaani lati kopa ninu igbẹkọ ori ayelujara.

Bakan naa lo sọ pe ofin konile-o-gbele ko mu igbẹkọ lori ayelujara lasiko yii.