NFF fi #30,000 kún #10,000 owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini àti Samuel Okwaraji

Yekini

Oríṣun àwòrán, Others

Ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF ti fi ẹgbẹrun un lọna ọgbọn naira kun ẹgbẹrun mẹwaa ti ẹka ijọba to n ri si ere idaraya ṣeto gẹgẹ bi owo iranwọ oṣooṣu fawọn iya oloogbe agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Rashidi Yekini ati Samuel Okwaraji.

L'Ọjọru ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ kede eto naa lati maa fun awọn mama oloogbe agbabọọlu Naijiria mejeeji tẹlẹ ni ẹgbẹrun mẹwaa naira loṣooṣu gẹgẹ bi owo iranwọ.

Olaitan Shittu to jẹ aṣoju minisita ere idaraya lo fọrọ naa lede l'Ọjọru nigba to ṣabẹwo si Alhaja Yekini niluu Ijagbo nipinlẹ Kwara.

Yekini

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Rashidi Yekini ṣi ni aṣiwaju atamatase agbabọọlu fun ilẹ Naijiria ninu itan.

Bakan naa ni ijọba tun fun mọmọ Yekini ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ ẹbun fun awẹ Ramadan to n lọ lọwọ.

O ti pe ọdun mẹjọ ti ẹlẹsẹ ayo, Rashidi to gba goolu sawọn julọ fun Naijiria di oloogbe.

Okwaraji ṣubu lori papa, o si gba ibẹ ku nigba to n kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ati yege fun idije ife ẹyẹ Italian '90 to waye laarin Naijiria ati Angola niluu Eko lọjọ kejila oṣu kẹjọ ọdun 1989.

Ìjọba buwọ́lu ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini

Rashidi Yekini: Ìjọba buwọ́lu ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini

Ileeṣẹ ijọba to n ri si ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ ti ṣeto lati maa fun mama oloogbe agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Rashidi Yekini ni ẹgbẹrun mẹwaa naira loṣooṣu gẹgẹ bi owo iranwọ.

Aworan Yekini ati Iya rẹ

Oríṣun àwòrán, others