Ibrahim Gambari: Olórí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì Ààrẹ ní oun tí ààrẹ Buhari nílò ni ìjólóòtọ́, ìfọkànsìn pẹ̀lú àtìlẹ́yìn òun

Ibrahim Gambari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olori tuntun fun awọn oṣiṣẹ lọfiisi aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari ti sọ ọ laifọtape pe oun ati ọmọ Naijiria kii ṣe ọlọrọ o, oun ati aarẹ Buhari lọlọrọ ninu iṣejọba yii.

Ọjọgbọn Gambari ṣalaye eyi lasiko to fi n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ti wọn kede rẹ lọjsbọ ni ileeṣẹ aarẹ, nilu Abuja.

Gambari ni oun ko tii lee sọ ibi ti oun yoo ti bẹrẹ si nii mu iṣẹṣe ṣugbọn ohun mọ daju pe, "oun ko ni abọ kankan n jẹ fun ọmọ Naijiria bi ko ṣe Aarẹ Buhari".

Ọjọgbọn Ibrahim Agboola Gambari sọ pe oun yoo fi gbogbo agbara oun sin aarẹ Muhammadu Buhari.

Gambari sọrọ yii fawọn akọroyin lẹyin to bẹrẹ iṣẹ nileeṣẹ ijọba l'Ọjọru niluu Abuja.

Gambari ni ifọkansin ati igbarukuti oun ni Aarẹ Buhari nilo lati ṣe ijọba gidi fawọn ọmọ Naijiria.

Olori awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ tun dupẹ lọwọ Eleduwa fun anfaani lati sin orilẹede Naijiria.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ Buhari fun anfaani lati sin in pẹlu ipo tp yan si i.

Ààrẹ Buhari yan Ibrahim Gambari gẹ́gẹ́ bíi olórí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì Ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Other

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé Aarẹ Muhammadu Buhari ti yan Ọjọgbọn Agboọla Ibrahim Gambari gẹgẹbii olori tuntun fawọn oṣiṣẹ lọfiisi aarẹ.

Akọwe ijọba apapọ Boss Mustapha lo kede orukọ Ọjọgbọn Gambari lasiko ti ipade igbimọ iṣejọba apapọ lorilẹede Naijiria fẹ bẹrẹ lọjọru niluu Abuja.

Ọjọgbọn Gambari ni yoo maa gba ipo naa eleyi ti Abba Kyari dimu lati ọdun 2015 ti saa akọkọ iṣejọba aarẹ Buhari bẹrẹ titi di oṣu kẹrin ọdun 2020 ti wọn kede iku rẹ lẹyin to lugbadi arun COVID-19.

Ni ọsan ọjọ Iṣẹgun ni iroyin ti kọkọ lu si igboro pe Ọjọgbọn Ibrahim Gambari ni aarẹ pada fontẹ lu fun ipo naa bi o tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ aarẹ kọkọ sẹ jalẹ pe awọn ko mọ nipa ikede orukọ naa nigba naa.

Ẹkunrẹrẹ iroyin yii n bọ lọna.

Chief of staff Ibrahim Gambari: Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibrahim Gambari tó ṣeéṣe kó rọ́pò olóògbé Abba Kyari gẹ́gẹ́ bíi olórí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì Ààrẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibrahim Gambari gẹ́gẹ́ bíi olórí àwọn òṣìṣẹ́ tuntun nílé iṣẹ́ ààrẹ.

Laipẹ yii ni Abba Kyari to jẹ olori awọn oṣiṣẹ nile iṣẹ aarẹ tẹlẹ di oloogbe lẹyin to lugbadi aarun coronavirus.

Ilu Eko ni Kyari ku sii lẹyin ti wọn gbe e wa si ipinlẹ naa fun itọju nigba to lugbadi aarun covid-19 l'Abuja.

Ta ni Ọjọgbọn Ibrahim Gambari gan an?

A bi Ọjọgbọn Ibrahim Agbaoola Gambari niluu Ilorin ipinlẹ Kwara lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla, ọdun 1944.

Ọjọgbọn Gambari lọ si gbajugbaja ileewe King's College nipinlẹ Eko.

O tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ nigba to gboye akọkọ ni fasiti ninu ẹkọ nipa ọrọ aje nileewe London School of Economics lọdun 1968.

Lẹyin naa lo tun gboye keji ni ati ikẹta ni fasiti Columbia niluu New York l'Amẹrika lọdun 1970 ati 1974 ninu ẹkọ nipa sayẹnsi osẹlu ati ibara-ẹni-ṣepọ laarin awọn orilẹede agbaye.

Awọn ipo ti Ọjọgbọn Ibrahim Gambari ti di mu ri

Olori orilẹede Ọgagun Muhammadu Bahuri nigba naa lọhun yan Ọjọgbọn Ibrahim Gambari gẹgẹ minisita fun ọrọ okeere laarin ọdun 1984 si 1985.

Oun ni aṣoju orilẹede Naijiria ni ajọ iṣọkan agbaaye laarin ọdun 1990 si ọdun 1999.

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ọjọgbọn Gambari jẹ alaga igbimọ ajọ iṣọkan agbaye to n pẹtu sija laarin ọdun 1990 si ọdun 1999.

Oun ni aarẹ igbimọ alaṣẹ ajọ UNICEF to n ri si ọrọ awọn ọmọde lọdun 1999.

Ọjọgbọn Gambari jẹ oludamọran pataki lori ọrọ ilẹ Afirika labẹ akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye, Ban Ki-Moon lọdun 2000 si ọdun 2005.

Bakan naa ni Ọjọgbọn Gambari ṣiṣẹ labẹ akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye ninu ọrọ oṣelu laarin ọdun 2005 si ọdun 2007.