Yoruba Films: Mr Latin ní òṣèré tó bá ya sinimá lásìkò Coronavirus yìí, òun ò lọ́wọ́ ń bẹ

Awọn oṣere tiata

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mr Latin

Ere Sinima jẹ ara ẹka iṣẹ aayan laayo lawujọ to ṣe pataki, to si tun ma a mu owo wọle fun awọn osere tiata ati ijọba pẹlu.Amọ ajakalẹ arun Coronavirus to gbode kan yii, n pa iṣẹ tiata lara gẹgẹ bo ṣe n waye ni awọn ẹka iṣẹ aayan laayo miran.Ni osu kẹta ọdun ti arun Covid-19 burẹkẹ ni Naijiria, agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni ede Yoruba, taa mọ si TANPAN, labẹ akoso aarẹ ẹgbẹ Bolaji Amusan, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Latin, pasẹ pe ọmọ ẹgbẹ naa kankan ko gbọdọ ya sinima.

Aṣẹ ẹgbẹ TANPAN naa, to wa lati dena itankalẹ arun Coronavirus, ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa tẹle, ti koowa wọn si joko sile lai gbe sinima kankan jade.Ṣugbọn lati igba ti aarẹ Muhammadu Buhari ti dẹ okun lọrun ofin konile o gbele, ni awọn oṣere tiata kan ti n gbero lati pada si idi isẹ wọn, ti wọn si n reti igbimọ alakoso ẹgbẹ lati gbe ẹsẹ kuro lori ofin 'ẹ jokoo sile yin' to pa.Amọ aarẹ ẹgbẹ, Mr Latin, ninu alaye to ṣe si oju opo Instagram rẹ ti ni, eyi ko lee ṣee ṣe nitori awọn idi kan to mẹnuba.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mr Latin

Mr Latin ni loootọ ni oun mọ pe ajakalẹ arun Coronavirus ti ṣe akoba nla fun ọrọ aje awọn osere tiata, sugbọn o san ki eeyan wa laye ninu ilera pipe, ju ko maa jẹ irora aisan lọ.Latin fikun pe "ifọwọsowọpọ ọpọ eeyan ni sinima ṣiṣe gba, eyi to si le tako awọn ofin to rọ mọ idena arun Covid-19 nitori ogun eeyan tabi ju bẹẹ lọ lo n kopa ninu sinima kan."

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mr Latin

O wa n rọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati ro gbogbo nkan wọn yii, ki wọn si fara da akoko yii bo ṣe gba.Mr Latin tun woye ninu ọrọ rẹ pe, ni wọn igba ti ijọba ti paṣẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ rin irin ajo lati ipinlẹ kan si omiran yika Naijiria, bawo wa ni yoo ṣe rọrun fun awọn oṣere ori tiata lati rinrin ajo lati ipinlẹ kan si omiran lọ kopa ninu yiya sinima?"Koda, bi oṣere tiata kan ba gba owo lati kopa ninu ere lasiko yii, ti ko si si ọna lati rinrin ajo lọ kopa ninu ere ọhun nipinlẹ ti wọn ti fẹ ya iṣẹ, iru iṣẹlẹ bẹẹ tun le da ede aiyede silẹ, eyi to le da ẹgbẹ ru.Aarẹ ẹgbẹ TANPAN wa sọ oju abẹ niko pe igbimọ amusẹya ẹgbẹ naa ti paṣẹ pe ki awọn oṣere tiata si jokoo sile wọn titi ti ijọba apapọ yoo fi gbe ẹsẹ kuro lori ofin konile o gbele patapata.Amọ ko sai yan pe "bi Olootu ère kan ba wa le tẹle awọn ofin tijọba la kalẹ lori idena itankalẹ arun Covid-19 ti mo mẹnuba saaju, o le tẹsiwaju lati lọ ya ere amọ ẹgbẹ TANPAN ko lọwọ ninu irufẹ igbesẹ Bẹẹ."