Lagos Tanker Accident: Ìjàmbá ọkọ̀ agbépo mú ẹ̀mí èèyàn kàn lọ ní Èkó, awakọ̀ tírélà f'ẹsẹ fẹ́ẹ

Aworan ọkọ agbepo to ṣubu danu

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ijamba ọkọ tirela agbepo kan to ṣubu lulẹ nilu Eko ti mu ẹmi eeyan kan lọ ti dirẹba ọkọ naa si ti na papa bora.

Ni iwaju bareke awọn ologun ni adugbo Mile 2 ni iṣẹlẹ yi ti waye lọjọ Ẹti.

Ninu atẹjade ti ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nilu Eko fi sita lorukọ ọga agba Femi Osanyintolu, wọn ni epo bẹntiro ni ọkọ naa gbe lasiko to dẹgbẹ lulẹ.

Osanyintolu ṣalaye pe epo naa ti da silẹ lasiko tawọn de ibi iṣẹlẹ naa ati pe awọn ṣi dawọ duro lati da epo naa si ọkọ mi.

Oríṣun àwòrán, LASEMA

O ni idi ni pe awọn fẹ kan si ẹni to ni ọkọ agbepo naa ki awọn to bẹrẹ si ni da epo inu rẹ kuro.

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àwọn tó wà nínú ìjàmbá ọkọ̀ órí afára Otedola ń lọ ìpínlẹ̀ míì láti Eko ni - LASTMA

Ileeṣẹ to n risi irinkerinko ọkọ oju popo ni ipinlẹ Eko, LASTMA ti sọ pe arinrin ajo ni awọn eeyan to wa ninu ijamba ọkọ to waye lori afara Otedola ni owurọ Ọjọbọ.

Ọga agba ileeṣẹ naa, Olajide Oduyoye lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC.

O ni awọn eeyan to wa ninu ọkọ akero funfun naa n rin irin ajo lati ipinlẹ Eko lọ ipinlẹ mii ni.

O fi kun pe "Awọn eeyan na n kuro ni ilu Eko ni, a ko mọ ibi gan ti wọn lọ, boya ipinlẹ Ogun ni wọn lọ tabi Oyo, a ko lee sọ, ṣugbọn ohun ti a mọ ni pe wọn n rinrin ajo kuro ni Eko ni."

Ni ti pe awọn eeyan naa tapa sofin to tako irinajo lati ipinlẹ kan si omiran lasiko Coronavirus yii, Oduyoye ni ofin naa yoo ṣoro lati tẹle.

"Nitori ọpọ awọn eeyan lo n ṣiṣẹ ni Eko ti wọn si n fi ipinlẹ Ogun ṣebugbe, papa lawọn agbegbe kan bi Berger, Mowe ati Ibafo.

O ni ọpọ ninu awọn eeeyan to n yọlẹ rin irinajo lati Eko lọ ipinlẹ mii lo ma n parọ pe ile wọn ni wọn n lọ jẹ ko ṣoro lati mọ awọn to n lọ ipinlẹ mii.

Oduyoye pari ọrọ rẹ pe iṣẹ LASTMA ni lati dari ọkọ ni igboro ilu Eko, ti ala iṣẹ iṣẹ wọn si pin si agbegbe Berger, nitori naa o ṣoro lati mu awọn eeyan to ba n lọ ipinlẹ miran.

Ènìyàn kan kú, méje farapa nínú ìjàmbá afárá Otedola ní Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter

Eniyan kan ti gbe ẹmi mi, ti eniyan meje si faragba ninu ijamba ọkọ to waye lori afara Otedola ni ipinlẹ Eko laarin ọkọ agbepo ati ọkọ igbooro ti eniyan mẹwa.

Ileeṣẹ to n risi irinna ọkọ ni ipinlẹ Eko, LASTMA to fi iroyin naa lede, sọ pe aago mẹjọ aabo ni ijamba ọkọ naa waye laarọ Ọjọọbọ.

Ọkọ Golf naa wa lara awọn ọkọ to lugbadi ijamba ọkọ naa, amọ ajọ LASTMA ni ko si ẹni to farapa ninu ọkọ naa.

LASTMA ni gbogbo awọn oṣiṣẹ ajọ pajawiri lo ti wa nibẹ lati tete bojuto awọn eniyan naa.

Bakan naa ni wọn ti gbe awọn ọkọ to ni ijamba kuro ni oju ọna, ki awọn ọkọ to n lọ, to n bọ ba a le ri ọna kọja.

Ni bayii, wọn ti ṣi ọna silẹ fun awọn eniyan lati kọja, amọ sunkẹrẹ fakẹrẹ wa diẹ ni opopona naa.

Bẹẹ ni Ajọ LASTMA wa kesi awọn eniyan lati ṣe jẹjẹ ni oju popo.