₦22.5M ti pọ̀ jù fún owó fọ́ọ̀mù ìdìbò abẹ́lẹ́ sípò gómìnà APC - SERAP

APC

Oríṣun àwòrán, @Pristinenetwor1

Adari agba ajọ SERAP, Adetokunbo Mumuni ti sọ fun BBC pe oṣẹlu ko ni rọrun ti awọn ẹgbẹ oṣẹlu ba n gba owo gọbọi lọwọ awọn to fẹ gbe apoti ibo.

Mummu ni lo sọ ọrọ naa lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn to ba nifẹ lati kopa ninu idibo abẹle gomina ipinlẹ Ondo ati Edo ni lati san miliọnu mejilelogun atabọ naira gẹgẹ bi owo fọọmu.

O ni owo ti ẹgbẹ APC n bere lọwọ to fẹ gbe apotyi idibo naa ti pọ ju.

Mumuni tẹsiwaju pe ajọ SERAP ko faramọ igbesẹ APC lati sọ fun awọn oludije sipo gomina lati lọ wa owo gọbi fun fọọmu, nitori iru awọn igbeṣẹ bẹẹ lo n fa iwa ajẹbanu ti awọn oloṣelu n wu.

Lẹyin naa lo sọ pe iru igbesẹ bẹẹ yoo mu ko ṣoro fun awọn ọdọ, papa awọn ti ko lowo lati kopa ninu idibo ni Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Restructuring: Àgbékalẹ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí kò lè fàyè

O ni eto oṣelu ni Naijiria ko yẹ ko wa fun awọn to lowo atawọn to ni baba isalẹ nikan.

Ọgbẹni Mumuni wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ke gbajari si ijọba pe ko ṣe atunṣe si ofin to jẹ mọ bi idibo ṣe n waye, ko ma ba di pe olowo nikan ni yoo ma kopa ninu eto oṣẹlu.

Ondo 2020: Mú N22.5m péré wá, ko kópa nínú ìbò abẹ́nú fún ipò gómìnà ní Ondo àti Edo - APC kéde

Oríṣun àwòrán, @newsacrosscom

Ẹgbẹ oṣelu APC ni Ipinlẹ Edo ti kede pe Ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun oṣu kẹfa ọdun 2020 gẹgẹ bii ọjọ ti eto idibo abẹnu fun awọn oludije gomina ninu ẹgbẹ oselu naa ni Ipinlẹ Edo yoo waye.

Bakan naa ni ẹgbẹ APC tun ni idije abẹnu fawọn oludije gomina rẹ ni ipinlẹ Ondo yoo waye ni ọjọ Aje, ogunjọ oṣu Keje ọdun 2020 yii kan náà.

Ẹgbẹ oṣelu APC, lati ipasẹ akọwe Alakoso ẹgbẹ, Emma Ibediro, wa tun kede pe, oludije to ba nifẹ lati kopa ninu idije abẹnu fun ipo gomina naa ni Ipinlẹ mejeeji, yoo san miliọnu mejilelogun ati abọ naira, owo fifi ifẹ lati dije han ati owo fọọmu idije.

Amọ sa, ẹgbẹ APC ni awọn oludije fun igbakeji gomina ko ni san owo kankan fun wọn, ti wọn si tun faaye gba awọn eeyan to ni ipenija ara lati san idaji owo ọhun.