Yoruba Films: Ọmọba Femi Oyewunmi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Laditi ti jáde láyé

Oloogbe Femi Oyewunmi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Prince Kehinde Oyewunmi

Iku n pa ni, ilẹ n jẹ eniyan. Iku tun ti mu gbajugbaja oṣere tiata, Ọmọba Femi Oyewunmi ti ọpọ mọ si Laditi lọ.

Ọrẹ oloogbe naa, Ọgbẹni Sayo Alagbe lo fidi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba.

Ọmọba Oyewunmi ni a gbọ pe o ti n ṣaisan fun ọjọ pipẹ, koda Ọgbẹni Alagbe fidi rẹ mulẹ pe o ṣiṣẹ abẹ lori ẹyin rẹ.

O pada jẹ Ọlọrun ni pe lẹni ọdun mẹrinlelọgọta lọjọ Jimọ, ọjọ kejilelogun oṣu karun un ọdun 2020.

Oloogbe Oyewunmi kopa ninu awọn ere tiata bii Aye Toto, Koto Ọrun, Ija Eleye atawọn ere tiata.

O tun kopa ninu ere Ogun O Jalu Ogbomoṣo ki o to dagbere faye.

Ọmọba Femi Oyewumi fi iyawo ati ọmọ meje si aye lọ.