Nigeria At 61: Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?

Ikọlu nile ijọba

Oríṣun àwòrán, other

Ninu eto isejọba alagbada ni orilẹ ede Naijiria, ọpọ ojo lo ti rọ, ti ilẹ ti fi mu nitori awọn hila-hilo to ti la kọja, bẹrẹ lati ṣaa isejọba alagbada akọkọ, eyi to mu ko dojude.

Awọn ami to fa isubu ijọba alagbada akọkọ, naa la si tun ti n kofiri wọn ninu isejọba alagbada kẹrin taa wa yii, adura wa si ni pe ko ma dojude bii ti akọkọ.

Ni bayii ti orilẹ ede Naijiria wa n sami ọdun kọkanlelọgọta to ti gba ominira, BBC Yoruba ri pe akoko to da ree lati gba ara wa niyanju.

Itan Manigbagbe ti ẹ le nifẹ si:

Idi ree ta fi ṣe akojọpọ awọn iṣẹlẹ to bi isejọba alagbada akọkọ wo ati ẹkọ ti awọn oloselu aye ode oni lee ri kọ ninu rẹ, nitori ina eesi ko gbọdọ jo ni lẹẹmeji.

Gẹgẹ ba ṣe kaa loju opo itakun agbaye ati ninu awọn iwe itan miran, ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria ni ipilẹsẹ ohun to bi ijọba alagbada akọkọ wo ti wa, ẹkunrẹrẹ ohun to si sẹlẹ ree:

Ki lo fa ogun Wẹtiẹ ati isubu ijọba alagbada kinni?

Wẹtiẹ ni orukọ ti wọn n pe idarudapọ to waye ni ẹkun ìwọ oorun ijọun, tii ṣe ẹkun ẹya Yoruba, ninu eyi ti awọn oloselu ati araalu ti doju ija kọ ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Other

Itumọ Wetiẹ ni 'da epo pẹtiroolu si lara, ko dana sun', eyi ti araalu ati oloselu n ṣe.

Wọn n sun ile ati dukia ara wọn ni ina, ti wọn si n gbe oku si agbala ile ara wọn, lati fi ṣe akoba fun ara wọn.

Ọdun 1962 si ni awọn ohun to fa rogbodiyan naa bẹrẹ, nigba ti aawọ bẹ silẹ laarin Oloye Obafemi Awolowo ati Samuel Ladoke Akintola.

Awọn mejeeji yii si ni wọn jẹ asaaju ẹgbẹ oselu Action Group, AG, ti wọn tun n pe ni ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ.

Ede aiyede ati iwa itajẹsilẹ naa si lo bẹrẹ nigba ti Awolowo, tii ṣe asaaju patapata fun ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ kọwe fi ipo silẹ gẹgẹ bii Olootu ijọba ẹkun ìwọ oorun Naijiria, lati lọ du ipo Minisita labẹ ijọba apapọ.

Awolowo fidi rẹmi lati gba ipo Minisita náà, amọ o gba ipo olori ẹgbẹ oselu alatako nile asofin apapọ, ti igbakeji rẹ, Ladoke Akintola si gba ipo Olootu ijọba ẹkun ìwọ oorun.

Amọ Awolowo si ni asaaju ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, ti Akintola ko si faramọ igbesẹ naa, eyi to fa aawọ laarin awọn asaaju mejeeji.

Bẹẹ ni ọpọ awọn iyansipo ti Awolowo ṣe, ni Akintola fagile, ti ko si dun mọ Awolowo ninu.

Ni ọjọ kinni osu Kejì ọdun 1962, wọn wọgile ipo igbakeji asaaju ẹgbẹ nibi ipade apapọ ẹgbẹ Ọlọpẹ to waye nilu Jos, eyi to yẹ aga mọ Akintola ati awọn oloye ẹgbẹ miran nidii.

Lara wọn si ni Oloye Ayo Rosiji to jẹ akọwe ẹgbẹ ati Minisita mẹrin miran.

Wọn dibo a nigbẹkẹle ninu rẹ mọ lati yọ Akintola:Nigba to wa di ọjọ kẹrinlelogun oṣu Karun ọdun 1962, ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ yan Dauda Adegbenro bii Olootu ijọba tuntun.

Adegbenro si lọ sile asofin pe, ki wọn dibo 'a ko ni igbẹkẹle ninu rẹ mọ' lati yọ Akintola bii Olootu ijọba lẹkun naa, ti wọn si kede pe, awọn ko ni igbẹkẹle ninu Akintola mọ lootọ.

Oríṣun àwòrán, Other

Awọn alatilẹyin Akintola gbọ nipa igbesẹ yii, wọn ya bo ile asofin naa, eyi lo fa wahala nla níbi ijoko ile asofin lọjọ naa lọhun, tawọn asofin si n yọ ọwọ ẹṣẹ sira wọn niwaju ile.

Nigba to ya, gomina ẹkun iwọ oorun Naijiria nigba naa, tii tun ṣe Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Ọlọla Adesoji Aderemi yẹ aga ipo Olootu ẹkun ìwọ oorun mọ Akintola nidii.

O wa fi ontẹ lu iyansipo Alhaji Dauda Adegbenro, lati rọpo Akintola bíi Olootu ìjọba tuntun.

Iṣẹlẹ yii lo da idarudapọ silẹ laarin awọn ọmọlẹyin Awolowo ati Akintola ni ẹkun ìwọ oorun guusu Naijiria, tabi ilẹ Yoruba lapapọ, ti eku ko si ke bii eku mọ, bẹẹ ni ẹyẹ ko ke bii ẹyẹ mọ.

Awọn oloselu n sun ile, mọto ati eeyan:

Wọn n da epo pẹtiroolu si ara eeyan, ile, mọto ati dukia miran lorisirisi, lati dana sun wọn, ibi ti ọrọ Wẹtiẹ ti jade ree.

Bakan naa ni wọn si tun n gbe oku si ẹyinkule ile ara wọn lati fi ṣe akoba fun ẹni bẹẹ lọdọ ọlọpaa.

Ẹmi ọpọlọpọ eeyan lo bọ lọjọ aipe sinu rogbodiyan itajẹsilẹ naa, ti ọkẹ aimọye dukia si sofo pẹlu, sinu laasigbo naa laarin ọjọ perete.

Idi si ree tijọba apapọ fi kede pe nkan ko fararọ ni ẹkun ìwọ oorun guusu Naijiria, ni ọjọ kọkandinlọgbọn osu Karun ọdun 1962.

Wọn le ọba Adesoji Aderemi nipo bii gomina ẹkun iwọ oorun:

Isẹlẹ naa ti pe ọdun Mọkandinlọgọta bayii, boya ọna lati maa ṣe iranti ọjọ nla yii, ọjọ Manigbagbe naa, ni wọn ṣe n bura fun awọn aarẹ ati gomina ni ayajọ ọjọ naa.Ikede nkan ko fararọ ọhun lo mu ki wọn le ọba Adesoji Aderemi gẹgẹ bii gomina ẹkun ìwọ oorun guusu Naijiria.

Wọn si fi Minisita feto ilera labẹ ijọba apapọ, Dokita Moses Majekodunmi rọpo rẹ bii alakoso fidihẹ tabi Alakoso ijọba afunsọ, fun ẹkun ìwọ oorun guusu Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Other

Igba akọkọ si ree ninu itan orilẹ ede Naijiria ti wọn yoo ṣe amulo ikede nkan ko fararọ lati yanju rogbodiyan kan tabi omiran, eyi si jẹ ara ọna lati bomi pana wahala kan nigba to ba suyọ.

Amọ nigba to di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kejila ọdun 1962 ọhun, Ahmadu Bello, tii ṣe Olootu ijọba ẹkun ariwa Naijiria, ti ọwọ bọ iwe adehun ajọsepọ pẹlu Akintola.

Akintola pada si ipo Olootu ijọba ẹkun ìwọ oorun guusu Naijiria, nigbati Remi Fani-Kayode si jẹ igbakeji rẹ.

Ajọsepọ to wa laarin ẹkun ariwa ati ìwọ oorun guusu yii ko bímọ re fun Awolowo, lẹyin o rẹyìn ni wọn ran Awolowo lọ si ọgba ẹwọn fun ọdun mẹwa lori ẹsun idaluru.

Akintola ati Remi Fani-Kayode lọ se ẹgbẹ oselu ti ẹkun Ariwa:

Eyi si lo fun Akintola ati Igbakeji rẹ, Remi Fani-Kayode lanfaani lati fi ọwọ siwe ajọsepọ pẹlu ẹgbẹ oselu awọn eeyan ẹkun ariwa, Northern People's Congress, NPC .

Eyi tun kan awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oselu kan yika Naijiria, ti gbogbo wọn si yi orukọ wọn pada di ẹgbẹ oselu Nigerian National Alliance, NNA.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnira lojú àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Áfíríkà t''o ń wá ìgbé ayé rere lọ sí Yúróòpù ń rí

Amọ ẹgbẹ oselu NCNC to jẹ ti Nnamdi Azikiwe darapọ mọ ẹgbẹ Ọlọpẹ ti Awolowo n dari tẹlẹ ati awọn ẹgbẹ oselu miran yika Naijiria.

Wọn pa orukọ da di ẹgbẹ United Progressive Grand Alliance, UPGA.

Nigba ti idibo sile asofin apapọ de lọdun 1964, ẹgbẹ oselu NNA, ti Akintola jẹ ara wọn, ko ijokoo mejidinlọgọrun ninu ijokoo okoolelọọdunrun o din mẹjọ to wa nile asofin apapọ naa.

Amọ ọpọ akọsilẹ lo fihan pe, magomago rẹpẹtẹ ati eru ibo waye ninu esi ibo naa.

Nigba ti ẹkun ìwọ oorun guusu si tun seto idibo sile asofin tiẹ ni ọjọ kọkanla oṣu kẹwaa ọdun 1965, ti magomago tun waye, ni gbẹgẹdẹ ba gbina, wahala mii tun suyọ.

Rogbodiyan bẹrẹ tori esi ibo, ọpọ oku sun:

Ni kete ti wọn si kede esi ibo ọhun ni gọngọ tun sọ, eruku wahala miran tun sọ lala, rogbodiyan akọtun miran tun gbode ni ẹkun ìwọ oorun guusu Naijiria.

Ọpọ eeyan ni wọn n pa lojoojumọ, ti aimọye dukia si n sofo danu, ogun Wẹtiẹ miran tun de.

Laasigbo ọtun yii si lo mu ki ologun gba ìjọba lọwọ awọn oloselu alagbada ni ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kinni ọdun 1966, eyi to fopin si eto iselu ijọba alagbada akọkọ.

Ologun gba ijọba Naijiria tori ogun Wẹtiẹ:

Lasiko ti awọn ologun naa, eyiti ọgagun Chukwuma Kaduna Nzeogwu ati Emmanuel Ifeajuna lewaju wọn, gba ijọba lọwọ awọn oloselu, wọn sekupa Samuel Ladoke Akintola, tii ṣe Olootu ijọba ẹkun ìwọ oorun guusu Naijiria.

Bakanna ni wọn pa akẹẹgbẹ rẹ ni ẹkun ariwa, Ahmad Bello pẹlu Olootu ijọba Naijiria nigba naa, Ọlọla Tafawa Balewa.

Ọpẹlọpẹ pe Awolowo wa lọgba ẹwọn nigba naa ni ori fi ko yọ, bi bẹẹ kọ, o ṣee ṣe ki ẹmi oun gan bọ sinu iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Other

Ẹkọ to yẹ ki ijọba alagbada kẹrin kọ ninu isubu ijọba alagbada kinni:

Ni bayii ti ilẹ Naijiria n sami ayajọ ọdun Kẹkanlelọgọta ta gba ominira, ọpọ ẹkọ lo yẹ ka kọ lati ara awọn gbongbo to bi isejọba alagbada kinni wo, eyi ti yoo mu ki ijọba alagbada kẹrin taa wa yii ṣe aseye.

Ohun akọkọ to bi ijọba agbada akọkọ wo ni magomago ati ṣiṣe eru ibo, eyi to tun n fi oju han rẹpẹtẹ lasiko isejọba alagbada kẹrin yii.

Osi yẹ ka takete si nitori itakun kan ṣoṣo ko gbọdọ da wa ni epo nu lẹẹkan si.

Iwa afemi-afemi, ẹmi imọ tara ẹni nikan ati ijagudu fun ipo agbara wa lara ohun to bi isejọba alagbada kinni wo, eyi naa si n fi oju han bayii ninu ijọba alagbada kẹrin.

Osi yẹ ka yago fun, ta ba fẹ ṣe aṣeyọri ninu rẹ.

Bakan naa, iwa ipaniyan, dida ina sun ile ati dukia to fa ìjọba ologun wa, eyi to fopin si isejọba alagbada akọkọ, ko tii kasẹ nilẹ ninu ijọba alagbada kẹrin yii, nitori rogbodiyan, itajẹsilẹ ati isekupani to si n waye.

BBC Yoruba wa n gbadura pe ọba oke yoo fi idi ijọba alagbada kẹrin yii mulẹ, ti yoo si tu wa lara.