Ibadan Masquerades festival: Olóòlù ní bí eégún bá fi aṣọ wọ́lẹ̀ láàrin ìlú ni Coronavirus yóò kúrò

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Ibadan Masquerades festival: Olóòlù ní bí eégún bá fi aṣọ wọ́lẹ̀ láàrin ìlú ni C

Wọn ni ẹ jẹ ka ṣe bi wọn tii ṣe, ko lee ri bo ti yẹ ko ri, ko maa ba lẹyin bii oku iya jọjọ.

Eyi ni esi ti ọkan lara awọn eegun ilẹ Ibadan, tii tun ṣe Oloolu baba eegun, Ifasuyi Omotoso Kazeem fi fesi si aṣẹ ti Olubadan pa.

Bẹẹ ba gbagbe, a ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe, Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji ti paṣẹ pe egungun kankan ko gbọdọ jade fun ọdun eegun, nitori arun Coronavirus.

Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ naa, Oloolu ni oun ko gbọ ri rara pe ni ọdun kan, eegun ko ni fi aṣọ wọlẹ nilu Ibadan.

Oloolu ni "awọn nnkan to maa n sẹlẹ lẹyin rẹ maa n lagbara, Ọlọrun ma jẹ ka ri ogun igbona, Coronavirus si ree, igbona lo bii,aṣọ eegun si lo maa n ko arun kuro nilu.

Agba eegun naa ni idakureku ojo to n waye laarin ìlú, isoro nla ni, orisirisi arun ni yoo si maa bẹ silẹ, to fi mọ arun ti a ko gbọ ri.

Àkọlé fídíò,

Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn

"Aṣẹ ti ijọba pa fun Olubadan lo sọ sita, oun ti ko si ye ijọba ni pe egungun la fi tẹ Ibadan do, bi eegun ko ba si jade, isoro yoo sẹlẹ, Ọlọrun ma jẹ ki aburu ṣe wa."

"Ọrọ bii wahala ni yoo maa sẹlẹ n'Ibadan, ọrọ bii ogun, bii ọtẹ, awọn etutu kan wa ta maa n ṣe fun ọba, bawo wa ni yoo ṣe wa di ọdun yii, ti wọn yoo ni ka ma ṣe etutu ọhun amọ ka jokoo sile."

Oloolu tẹ siwaju pe awọn egungun kan wa to jẹ pe ti wọn ko ba jade, nnkan yoo ṣe awọn to n gbe eegun naa, to si fi eegun kan ti wọn ni ko ma jade ni ọdun kan ṣe apẹẹrẹ, o ni ọmọ ẹni to n gbe eegun naa meji lo ku.

"Eyi to ṣẹlẹ yii, bii igba ta kan da wahala sira wa lọrun ni. Ki Ọlọrun ma jẹ ka ri wahala."

Oloolu, ẹni to ni oun ko tii le sọ boya ijọba yoo fun oun lasẹ lati jade ṣe ọdun ni ọdun yii abi bẹẹ kọ wa fi ọwọ gbaya pe bi ijọba ko ba fun oun lasẹ lati jade, oun yoo ṣe iwọnba ohun ti oun ba le ṣe niha toun, amọ ohun ti yoo ti ẹyin rẹ yọ, ni oun ko le sọ,tori mẹwa yoo sẹlẹ.

Ibadan Masquerades festival: Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus, Olubadan pàṣẹ fáwọn Egúngún láti fi ìdí mọ́lé ṣe ọdún

Oríṣun àwòrán, others

O dabi ẹni pe ko sibi ti ọwọja ajakalẹ arun Coronavirus ko ni de ni orilẹ ede Naijiria, tori o ti de ọdọ awọn ara ọrun pẹlu.

Idi ni pe ọdun egungun ko ni ṣee ṣe fun awọn ara ọrun lọdun yii nitori arun Coronavirus to n ran bii ọwara ojo.

Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso kinni ti paṣẹ fun awọn egungun nilẹ Ibadan lati ṣe etutu ọdun egungun ninu ile wọn, ki wọn si maa ṣe adura fun opin arun Covid-19.

Atẹjade kan to wa lati aafin Olubadan lo sísọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe ko ni si ijade lọpọ yanturu lati ṣe ọdun eegun, titi tawọn alaṣẹ yoo fi si gbogbo eeyan silẹ.

Ọba Adetunji ni oun fi ìpinnu naa síta lẹyin ifikunlukun pẹlu awọn eeyan ti ọrọ ọdun naa gberu, eyi to nii ṣe pẹlu ofin itakete sira ẹni to wa nita, to si tun rọ awọn araalu lati maa fọ ọwọ wọn deede.