Àwọn ọníṣẹ́ ọwọ́ wọ̀nyí ti gbowó iṣẹ́ àmọ́ Coronavirus ò jẹ́ kí n ṣisé owó tí wọ́n gbà

Àwọn ọníṣẹ́ ọwọ́ wọ̀nyí ti gbowó iṣẹ́ àmọ́ Coronavirus ò jẹ́ kí n ṣisé owó tí wọ́n gbà

Lati igba ti ajakalẹ arun COVID-19 ti rapala wọ orilẹede Naijiria, oniruuru ipa lo ti ni.

Lara awọn ipa to ni ni bi awọn eeyan to n ṣe awọn iṣẹ kan ko ṣe lee ṣe iṣẹ mọ nitori ipa ti o ni lori iṣẹ wọn.

Ko si idi meji ju wi pe, arun yii ti jẹ ko di mimọ fun gbogbo mutumuwa pe oun ko ni faramọ aṣepọ awọn eeyan ni fifarakanra, eyi to si jẹ pe akoba ni fun awọn iṣẹ kan nitori aṣepọ bẹẹ lo n mu ọrọ aje ya fun wọn.