Coronavirus in Lagos: 'Bí Covid19 bá peléke síi l'Eko, ilé la ó ti máa tọ́jú àwọn kan'

Abayomi

Oríṣun àwòrán, @Rasheethe

Ijọba ipinlẹ ti jẹ ko hande pe bi wọn ba n ni iye awọn to lugbadi arun Covid19 to n le ni igba si ọọdunrun lojoojumọ gẹgẹ bo ṣe n sunmọ ọ lẹnu ọjọ mẹta yii, awọn ibudo iyaraẹnisọtọ wọn ko ni to fun itọju mọ.

Wọn fi kun un wi pe bi o ṣe tun n peleke si i bayii nipinlẹ naa, awọn alaisan ti ipo wọn le atawọn to sunmọ ọ nikan ni wọn yoo maa tọju nibudo iyaraẹni sọtọ nigba ti wọn yoo ma tọju awọn ti ko safihan ami Covid19 tabi ti tiwọn ko fibẹẹ pọ nile wọn.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nilu Eko lọjọ ẹti, kọmisọna eto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi tẹnu mọ ọ pe alaye kikun yoo wa lori itọju alaisan nile ki awọn eeyan le mọ ẹni to tọ si gan lati gba itọju nile tabi nibudo iyaraẹnisọtọ.

Kọmisọna tọka si wi pe tori ọda ibudo iyaraẹnisọtọ yii wọn nilo lati bẹrẹ itọju alaisan nile laarin ọsẹ kan si meji ti wọn yoo si yọnda ibudo iyaraẹnisọtọ fun awọn ti ailera wọn lagbara gan.Lara ohun ti wọn le fi wa tọju alaisan nile ni pe ṣe ile naa wa ni ipo to dara fun itọju?

Ṣe ẹni ti ara rẹ ko ya yii ni iṣoro èémí?Idahun si eyi atawọn nkan mii ni yoo sọ ibi ti wọn yoo ti tọju ẹni bẹẹ fun aisan Covid19.

Kọmisọna sọ pe bi o tilẹ jẹ pe wọn gbero lati tunbọ gba oṣiṣẹ si i, awọn kan wa to ti yọnda ti wọn si ti ṣe idanilẹkọ fun wọn lati lọ maa ṣe itọju awọn alaisan nile laarin ọsẹ kan si meji.

Ilana itọju alaisan nile"Fun awọn ti ailera wọn ko le ti wọn yoo maa tọju nile, a maa pe wọn lori ẹrọ ibanisọrọ, oṣiṣẹ wa yoo lọ bẹ wọn wo, a o ri i daju pe wọn gba ilana itọju ara ẹni lori ẹrọ ibanisọrọ wa, a o si ma mojuto ayipada wọn.

Bakan naa, wọn yoo gba ẹru itọju ati ogun eyi ti ogun apa irora ati aṣaraloore wa nibẹ.Lafikun, a o ṣe ilanilọyẹ fun awọn araalu lori didaabo bo ara wọn ati ẹbi ati aladugbo wọn lasiko itọju alaisan nile yii.

O fi kun un wipe wọn tun ti ṣeto lati jawo ayẹwo ojoojumọ soke sii lati ẹgbẹrun kan si ẹgbẹrun mẹta loojọ.

O ni ipinlẹ Eko ti ṣe ayẹwo to le ni ẹgbẹrun mejilelogun bẹẹ si ni wọn n tẹsiwaju tori eyi ni wọn ṣe gbudọ mura silẹ de afikun iye awọn to lugbadi arun yii.