Wole Soyinka: Buhari kọ́ ló ń darí wa ni ipo òṣèlú ṣe fì sí apá kan

Ọjọgbọn Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Instagram/wolesoyinka

Gbajugbaja onkọwe nni, ọjọgbọn Wole Soyinka ti koro oju si bi wọn ṣe pin ipo oselu ni Naijiria, to fi fi si apa kan ju ọkan lọ.Soyinka wa n beere pe ki wọn fi iya to pọ jẹ awọn eeyan to wa nidii ṣíṣe iyansipo oselu naa ninu ijọba Buhari nitori iwa ọdaran ni wọn hu.Ọjọgbọn Soyinka fajuro bẹẹ, nigba to n fesi lori lẹta kan ti gomina ologun tẹlẹ nipinlẹ Kaduna, Umar Dangiwa fisita, to si n daba pe ki wọn pin orilẹ-ede Naijiria si ẹlẹkunjẹkun.

"Okodoro ọrọ ni Umar sọ kalẹ yii lai si iwa imọtaraẹni nìkan nibẹ, ti ẹnu si ya mi pe iru iwa bayii n sẹlẹ.""Iru asiri to tu sita yii mi ilu titi, to si le pin orile-ede si yẹlẹ yẹlẹ, amọ ohun ti ijọba lee ṣe ni ko ṣẹ pe irọ ni ọrọ naa pẹlu ẹri to daju, tabi ko ṣe eto atunto."Ọjọgbọn naa wa woye pe kii ṣe aarẹ Buhari lo n dari Naijiria, to si n rọ ọ lati mase fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ lẹta naa." N ko ro pe ẹnikẹni wa ni ile ijọba Aso Rock to n dari Naijiria, mo ti n woye bi nnkan ṣe n lọ lati ọdun kan aabọ, mo si gbagbọ pe aarẹ yii kọ lo n ṣe akoso Naijiria ni gbogbo ọna."Soyinka fikun pe, bi ijọba ṣe dakẹ lai fọhun lori ọrọ naa bi oun ninu, amọ ọpọ awọn ti inu n bi bii ti oun, ni ko fẹ sọrọ to le da nnkan ru.