Ajikanle ní òun ti ta ọ̀pọ̀ dúkìá lórí apá àti ẹsẹ̀ tó rọ láti ọdún kẹta náà

Mufutau Ajikanle,

Oríṣun àwòrán, Instagram/murphyafolabi20

Yoruba ni ẹni ti ija ko ba, nii pe ara rẹ ni ọkunrin, bi ere ba si ba ẹdun nilẹ, yoo di ọlẹ ni.Bẹẹ ni ọrọ ri fun gbajumọ oṣere tiata kan, Mufutau Ajikanle, ẹni ti apa ati ẹsẹ rẹ ti rọ lati ọdun mẹta sẹyin.Nigba to n salaye ohun ti oṣere tiata naa n la kọja faraye, gbajugbaja oṣere tiata miran, Murphy Afolabi sọ loju opo Instagram rẹ pe, ọkunrin naa nilo iranwọ araalu kiakia.

Ninu fidio to gbe jade ọhun ni Ajikanle, ẹni to ko ipa ribiribi ninu sinima Mufu Olosha Oko ati Olosha Molete, ti n bẹbẹ si araalu pe ki wọn saanu oun pẹlu iranwọ owo.

Mufutai, to jokoo lori ibusun pẹlu ọpa lọwọ ni "ibi ti wọn ti n tọju mi ni mo wa, n ko ni alaafia rara, awọn ẹgbẹ ti mo n ṣe ati awọn ọrẹ ti gbinyanju, ti mo si ti ta dukia mi tan."O wa bẹbẹ pe "ẹ saanu mi, Ọlọrun ko ni fi aarẹ ṣe yin, a ti nawo sẹyin lai ri iwosan, amọ mo sẹṣẹ wa ri ibi ti wọn yoo ti tọju mi daadaa bayii ni, sugbọn ko si owo mọ."