MC Oluomo: Agbálẹ̀ títì ni ìyá mi, ọmọ ọdún 13 ni mo sì ti sá nílé lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kọ̀ǹdọ́

MCOLUOMO

Oríṣun àwòrán, InSTAGRAM/MCOLUOMO

Alaga ẹgbẹ onimọto NURTW nipinlẹ Eko, Alhaji Musiliu Ayinde Akinsanya, ti ọpọ eeyan mọ si MC Oluomo, ti salaye bo ṣe bẹrẹ igbe aye rẹ ati bo ṣe di gbajumọ lọjọ oni.

MC Oluomo, lasiko to n kopa lori eto kan ni ikanni BBC Yoruba salaye pe, ọmọ ọdun meje ni baba oun jade laye, atijẹ atimu di ọran, iṣẹ agbalẹ oju popo ni iya oun si n ṣe.

Oluomo fikun pe "ọdọ ẹni to ku ni iya fun mama mi nilu Abeokuta la n gbe lọdọ rẹ, Mama mi n gbalẹ titi ni Eko, n ko ri itọju to, ni mo ṣe sa kuro nile lọmọ ọdun mẹtala, ti mo si n ṣe kọndọ lati Abeokuta wa si Eko."

Oluomo tun sisọ loju rẹ pe, ko si ẹnikẹni to kọ oun ni ọkọ wiwa, oun kan n sun ọkọ siwaju diẹ-diẹ ni ori tọọnu ni gareeji bii kọndọ, ni oun fi mọ ọkọ wa.

Oríṣun àwòrán, InSTAGRAM/MCOLUOMO

Alaga ẹgbẹ ọlọkọ ero ni Eko tun fikun pe, inu iya oun ko dun pe oun n ṣe kọndọ, ti wọn si fẹ mu oun lọ sile ọmọ alaigbọran, ti wọn n pe ni welfare, amọ oun sa mọ wọn lọwọ, ti oun si n sun ita.

O wa yan pe, lootọ ni oun n sun ita tabi inu ọkọ mọju, sugbọn oun ko huwa ọmọ buruku ri, oun kii jale, mu igbo, mu siga tabi ọti, ti oun kii si ṣe ipanle.

Nigba to n sọ idi ti wọn ṣe n pe ni Oluomo, MC ni "Oju popo ni mo gbe dagba, a ko ara wa jọ lati dẹkun iwa ole jija ni Oshodi, ni ọba mẹrinla ṣe fi mi jẹ oye Oluomo ni Isọlọ, orúkọ yii si lo ro mi, ti mo fi de ibi giga."

Oríṣun àwòrán, InSTAGRAM/MCOLUOMO

Oluomo wa leri leka pe bi Ọlọrun ba bo oun ni asiri, awọn ọmọ ita ni oun yoo ran lọwọ julọ nitori ọmọ ita ni oun naa, idile ti ko si toro lo mu ki ọpọ awọn ọmọ yii di ọmọ ita."

Nigba to n sọrọ lori ibasepọ rẹ pẹlu awọn oṣere tiata, Oluomo ni "iyọ̀ aye ati amuludun ni awọn oṣere tiata, iwọnba ti mo le ṣe, ni mo fi n ran wọn lọwọ, ohunkohun to ba sì wu awọn eeyan ni ki wọn sọ nipa ibasepọ wa."

MC Oluomo, ẹni to ni ẹgbẹ awakọ ero kii lọwọ ninu eto iselu, wa rọ awọn ọmọ ita lati mase ro ara wọn pin, kí wọn mase jale amọ ki wọn lo ọpọlọ wọn lati ṣíṣẹ, ki wọn si fi igbe aye toun ṣe arikọgbọn."